Ilé aṣòfin àgbà ṣe ìbúrawọlé fún Natasha Akpoti tí PDP láti ṣojú Kogi

Ilé aṣòfin àgbà ṣe ìbúrawọlé fún Natasha Akpoti
Aworan Natasha nile igbimọ aṣofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Natasha Update

Ile aṣofin agba lorilẹ-ede Naijiria lo ti bura fun oludije fun ipo sẹnetọ ni ẹkun aarin-gbungbun Kogi lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Natasha Akpoti-Uduaghan, lati darapọ mọ ile igbimọ naa.

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ilẹ yii, Godswill Akpabio, lo dari akọwe ile ọun lati ṣeto iburawọle naa fun un.

Aago mejila ku iṣẹju mọkandinlogun ni Natasha jẹjẹ wọṣẹ gẹgẹ bii sẹnetọ.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ meji ti ile-ẹjo kotemilọrun kede pe arabirin naa lo jawe olubori nibi eto idipo dipo sẹnetọ ẹkun aarin-gbungbun Kogi to waye lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun yii.

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun naa lo gbe lẹyin idajọ igbimọ to gbọ ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo ọun leyi to wi pe Natasha lo ni ojulowo ibo tyo pọ julọ ninu idije naa.

Natasha ni obirin akọkọ ti yoo jẹ sẹnetọ ni ipinlẹ Kogi.

Ilé-ẹjọ̀ kòtẹ́milọ́rùn ní Natasha PDP ló borí ìbò Sẹ́nétọ̀ ní Kogi kìí ṣe Ohere APC
Aworan Natasha Akpoti

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti/Instagram

Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ti gbe idajọ kalẹ lori Senato ipinle Kogi.

Ile ẹjọ ni wi pe Natasha Akpoti-Uduagan ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) lo jawe olubori ninu eto idibo sile igbimọ aṣofin agba orileede yii ni ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kogi.

Wọn ni Natasha lo bori ninu eto idibo apapọ orileede yii to waye ninu oṣu keji, ọdun yii.

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, Independent National Elctoral Commission, INEC ti kọkọ kede Abubakar Ohere lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori niu eto idibo naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ti INEC kede Ohere ni Natasha gba ile-ẹjọ Tribunal lọ lati tako igbesẹ ti INEC gbe naa, to si ni oṣelu ni ẹgbẹ oṣelu alatako fẹẹ lo lati gba ẹtọ oun kuro lọwọ oun.

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun gba ẹbẹ Natasha, o si gbe idajọ kalẹ wi pe oun gan-an ni ojulowo oludije to jawe olubori ninu eto idibo ọhun.

Alaga igbimọ ẹlẹni mẹta tile-ẹjọ Tribunal naa, Onidajọ K. A. Orjiako nigba to n gbe idajọ kalẹ sọ pe niṣe ni wọn fi kun ti wọn fi kede Ohere ni awọn ibudo idibo meṣan to wa nijọba ibilẹ Ajaokuta.

O ni ajọ INEC din ibo Natasha ku ni awọn ibudo idibo ọhun, bẹẹ ni wọn ko ṣe akọsile ibo l’awọn ibudo idibo mẹta ti wọn ti dibo fun Natasha ni ijọba ibilẹ naa.

Ile-ẹjọ naa wa kede Natasha gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹrinleadọta le ni ẹrinlelaadọrin (54,074) to fi bori Ohere toun ni ibo to le ni ẹgbẹrun mọkanlelaadọta (51,291).

Ohere tako idajọ naa, to si gba ile-ẹjọ kotẹmilọrun lọ, ṣugbọn ti ileẹjọ naa sọ pe ko si ẹri kan ninu ẹjọ to pe.

Bẹẹ ni wọn sọ pe ko lọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira gẹgẹ bi owo itanran.