Ìpínlẹ Ékò tọwọ̀ bọ̀wé adehun oníbílíọ́nù $1.35b dọ́la nítorí Afárá ẹlẹẹkẹrin ati ọkọ̀ oju irin Blue Rail

Sawno Olu

Oríṣun àwòrán, @Sanwo Olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti tọwọ bọwe adehun onibiliọnu kan ati marundinlogoji dọla ($1.35b )pẹlu awọn ileefowopamọ meji kan,Export-Import ati Access Bank, ni ireti ati lo owo naa fun afara ẹlẹẹkẹrin ti i ṣe 4th Mainland Bridge ati ọkọ oju irin Blue Rail nipinlẹ Eko.

Ilu Guyana, lorilẹ-ede Amẹrika ni Sanwo-Olu ti tọwọ bọwe adehun naa nibi ayẹyẹ ‘Africaribbean Trade and Investment Forum’ ti ọdun yii, to si kede loju opo X rẹ pe agbegbe ibudo omi Omu paapaa yoo jẹ anfaani lara awọn iṣẹ ọlọdun gbọọrọ ti ijọba oun yoo fowo naa ṣe.

Gomina Sanwo-Olu ṣalaye, pe igbesi aye irọrun fawọn olugbe ipinlẹ Eko lo jẹ iṣakoso oun logun. O ni ajọsẹpọ yii yoo so eso rere fun ipinlẹ Eko pupọ, nitori awọn nnkan amayedẹrun ọlọdun gbọọrọ nijọba fẹẹ kowo le lori.

O fi kun un pe eyi tun ṣafihan igbagbọ kikun tawọn olokoowo ilẹ okeere ati tawọn ilẹ yii ni ninu ọrọ aje ipinlẹ Eko to n gunke ni.

Gomina Sanwo-Olu so pe, “Afojusun wa fun ipinlẹ Eko ti n wa si imuṣẹ pẹlu papakọ ofurufu Lekki-Epe ati aaye ipese ounjẹ to wa niluu Ẹpẹ. Awọn eto yii yoo tubọ ran ọrọ aje Eko lọwọ, yoo si wulo fun awọn irandiran wa. ọjọ iwaju Eko daa pupọ ju ba a ṣe lero lọ’’