NLC dúnkokò láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì tí ìjọba kò bá yọ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Imo nípò

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, Nigeria Labour Congress àti akẹgbẹ́ rẹ̀, Trade Union Congress, TUC ti kéde pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́rú ọjọ́ kẹjọ oṣù Kọkànlá ọdún 2023.
Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún ni pé kí ìjọba yọ ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo kúrò ní ipò tó wà àti abẹ́ṣinkáwọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe fìyà jẹ ààrẹ NLC, Joe Ajaero ní ìpínlẹ̀ náà.
Ìpè yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn kan ṣe ìkọlù sí ààrẹ NLC, Joe Ajaero ní ìpínlẹ̀ Imo lásìkò tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba ìpínlẹ̀ látàrí gbèsè owó oṣù tí wọ́n jẹ àwọn òṣìṣẹ́..
Igbákejì ààrẹ NLC, Adewale Adeyanju sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja ohun tó le yẹ ìyanṣẹ́lódì náà kò sí àyàfi tí ìjọba bá dáhùn gbogbo ìbéèrè àwọn lórí ìyà tí wọ́n fi jẹ Ajaero.
NLC ní ọjọ́ márùn-ún ni àwọn fún ìjọba láti dáhùn ìbéèrè àwọn bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹta oṣù Kọkànlá.
Wọ́n ní ìjọba kò bá dáhùn ìbéèrè àwọn dandan ní kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọ́jọ́rú.
Ọlọ́pàá lu Ajaero ní àlùbami, tó sì dèrò ilé ìwòsàn- Agbẹnusọ NLC

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ti fẹsun kan ileeṣẹ Ọlọpaa pe wọn lu Aare ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ni alubami lẹyin ti wọn mu nipinlẹ Imo lọsan Ọjọru.
Agbẹnusọ ẹgbẹ NLC, Benson Upah lọ sọ eyi ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin, to fi di rẹ mulẹ pe Ajaero tí kuro ni ahamọ.
O ni, "A ti ba Aarẹ ẹgbẹ sọrọ ni nnkan bi ago mẹta abọ ni ile iwosan ti ileeṣẹ Ọlọpaa ni Owerri, nibi wọn ti gbe lọ Ile iwosan ìjọba apapọ níbi to ti n gba itọju bayii."
Ileeṣẹ Ọlọpaa ni awọn mu Ajaero lọ agọ wọn lati le da bobo ẹmi rẹ sugbọn ẹgbẹ NLC ni wọn ṣekọlu sì Aarẹ ẹgbẹ naa lẹyin wọn mu.
"Alubami ní wọn na, oju ọtun rẹ ti pade," Upah salaye.
"Ajaero ninu ọrọ diẹ to salaye ni lẹyin ti wọn mu oun, wọn na oun, ti wọn si fi nnkan de loju gbe lọ ibi ẹnikẹni ko mọ, ti wọn si fìyajẹ."
Upah ni ẹrọ ibanisọrọ, owo ati awọn dukia mii ni wọn gba lọwọ Ajaero tí wọn kò si ti dapada fun.
Ileeṣẹ Ọlọpaa nawọ gani Ajaero ni ọfisi NLC to wa ni Owerri.
NLC Joe Ajaero abduction: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fárígá lẹ́yìn tí àwọn agbófinró fipa gbé ààrẹ wọn lọ ní ìpínlẹ̀ Imo

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ Naijiria ti sọ pe ki awọn oṣiṣẹ maa gbaradi fun igbesẹ ti yoo lamilaka jakejado Naijiria ti awọn to gbe aarẹ ẹgbẹ naa ko ba tu silẹ nigba ti ilẹ oni yoo ba fi ṣu.
Igbe gbajare yi ko ṣẹyin gbigbe ti awọn agbofinro ṣe gbe aarẹ ẹgbẹ naa Comrade Joe Ajaero lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ nipinlẹ Imo.
Wọn ni iru iṣẹlẹ yi jẹ ohun to kan ni lominu to si ṣafihan iru iwa aibikita to n waye ni ipinlẹ Imo ni paapa si awọn oṣiṣẹ rẹ.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita lỌjọ Aje ni wọn ti sọ pe awọn agbofinro lu aarẹ ẹgbẹ naa bi bara ti wọn si wọ nilẹ ki wọn to sọ sinu ọkọ ti wọn si gbe lọ sibi ti ẹnikankan ko mọ.
Emmanuel Ugboaja ati Comrade Nuhu ni wọn jijọ buwọlu atẹjade yi ti wọn si sọ pe ki aarẹ Naijiria kesi Gomina ipinlẹ Imo Hope Uzodiinma ko tọwọ ọmọrẹ bọ aṣọ ki o ma ba sọ ipinlẹ Imo di ibuba awọn janduku.
Ki lo fa wahala ti wọn fi n ji aarẹ oṣiṣẹ gbe?

Oríṣun àwòrán, NLCHeadquarters
Lẹnu lọọlọ yi ni ẹgbẹoṣiṣẹ ni ipinlẹ Imo ati Gomina ipinlẹ naa Hope Uzodinma ti n gbena woju ara wọn.
Gbogbo aigbọraẹniye yi ko si ṣẹyin kikọ ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe Gomina naa kọ lati ṣika adehun lori awọn ọrọ ti awọn jijọ fẹnuko si.
Loju opo Twitter ẹgbẹ oṣiṣẹ, a ri ti wọn fi ọrọ sibẹ pe GominaUzodinma jẹ awọn oṣiṣẹ ni owo oṣu ogun lai san fun wọn.
Wọn ni Gomina dẹyẹ si awọn oṣiṣẹ yi nipa apejuwe wọn gẹgẹ bi ayederu oṣiṣẹ.
Yatọ si eyi, wọn ni awọn janduku Gomina ṣe ikọlu si ileeṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti eyi si wa lara awọn nkan to mu ki awọn fẹ naa tan bi owo pẹlu rẹ.
Lọjọ Iṣẹgun ni aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ balẹ si ilu Owerri lati lọ darapọ mọ awọn oṣiṣẹ ki wọn si jijọ koju idẹyẹsi ati awọn iwa mii ti wọn ni Gomina n hu si awọn oṣiṣẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe ri ka ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi kede pe wọn ji aarẹ gbe, wọn sọ pe awọn ọlọpaa gbiyanju lati tu awọn oṣiṣẹ to peju si olu ileeṣẹ ẹgbẹ ṣugbọn wn o ri bi le wọn lọ.
Wọn sọ pe wọn ko awọn janduku lọwọ ti awọn wọnyii si da ọgbẹ sawọn oṣiṣẹ lara.
Ibẹ naa ni atẹjade ọhun sọ pe wọn ti tun da bantẹ iya fun aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ nigba to wa yọju si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.
''Wọn ko ẹsẹ bo lori ati ara rẹ ki wọn to wọ sinu ọkọ ti awọn ọlọpaa si wa nibẹ bi awọn janduku ṣe n da ra to wu wọn pẹlu aṣẹ oluranlọwọ Gomina Chinasa Nwaneri ati awọn mii''
''Wọn pada gbe aarẹ sinu ọkọ wọn ti wọn si gbe lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ tiu a o si gburo rẹ titi di asiko taa wa yii''
Ọlọpaa ti fesi lori iṣẹlẹ yi, a ko fi ofin mu Ajaero
Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Imo Okoye Henry ti sọrọ si iṣẹlẹ yi.
Ninu atẹjade to fi sita, o ni awọn ko fi ofin mu aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ bi kii ṣe pe awọn gbe kuro nibi tawọn janduku ti n da bantẹ iya fun un.
O ni Kọmiṣana ọlọpaa lopaṣẹ pe ki wọn gbe lọ sibi ti yoo ti gba itọju nitori ikọlu tawọn janduku ṣe si eleyi ti ko ba mu ẹmi rẹ lọ bi awọn ko ba tete gbe kuro nibẹ.
O ni bẹẹ naa lawọn tun ti pese aabo to peye fun ki obaa le tẹsiwaju pẹlu awọn iṣẹ rẹ mii to ba ṣe eyi to wa ni ibamu pẹluofin.
Atẹjade yi ko sọ patoboya o ti kuro nibi to ti n gba itọjutabi ibi ti o wa bayii.
Wọn kan sọ pe ẹka ti wọn ti n pese itọju ileeṣẹ ọlọpaa lawọn gbe lọ niilu Owerri.












