Dókítà kàn, Téélọ̀ àti ọmọ kekere: Èyí ni ìtàn nípa àwọn tó kú ní Gaza

- Author, Ethar Shalaby
- Role, BBC Arabic
Iye awọn to n ba ikọlu Israel si Gaza lọ n pọ si lojojumọ lẹyin ti Hamas ṣe ikọlu to mu ẹmi awọn to sunmọ 1,400 lọ lọjọ Keje oṣu kẹwaa.
Ileeṣẹ ilera ni Gaza ti Hamas n dari rẹ sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹsan eeyan to ti ku lati igba ti ogun yi bẹrẹ.
Nitori ipenija aabo, iye awọn akọroyin ti yoo le fidi ọrọ yi mulẹ ni Gaza ko to nkan.
Amọ BBC lanfaani lati ba awọn mọlẹbi ati oju mi to to ṣalaye itan nipa awọn eeyan ti wọn padanu ẹmi wọn lẹnu lọọlọ yi.

Yusof Abu Mousa
Aisi ina ni ilu Gaza jẹ ipenija fun ọpọ amọ lọdọ Yusof ati awọn ẹgbọn rẹ meji-Jury, ọmọ ọdun mẹtala ati Hamed ọmọ ọdun mẹsan-nkan tun fararọ diẹ
Idi ni pe baba wọn to jẹ oṣiṣẹ ilera nileewosan Nasser nilu Khan Younis ribi pese ẹrọ amunawa solar ti awọn ọmọ rẹ si lanfaani lati wo iran lori ẹrọ amounmaworan wọn.
Iwaju ẹrọ amohunmaworan ni wọn wa lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹwaa ti baba wọn sọ pe wọn ṣadede kagbako ado oloro ti Israel yin lu wọn.
Jury ati Hamed moribọ ṣugbọn Yusof ba iṣẹlẹ yi lọ nigba ti orule ile wọn re lu lori.
Ọmọ ọdun meje nii ṣe.
Ibiṣẹ ni Mohammed wa to n ṣe iṣẹ aṣeyipo nigba ti iyawo rẹ wọle tọ ọ to n lọgun pe oun n wa ọmọ wọn.
O ri Hamed nigba tawọn adoola si wọ Jury jade labẹ ile top wo lu wọn.
Jury ṣeṣe lori ṣugbọn wọn lo n gba itọju ti ara rẹ si n ya bọ,
Kaakiri ayelujara ni fọnran fidio ibi ti Rawan ti n ke gbajare fun ọmọ rẹ ti gbode.
Mohammed pada ri oku ọmọ rẹ ni ile agbokupamọ si.
Mohammed sọ pe ''igba ti mo ri Yosuf kẹyin ni igba to sare wa dimọ mi lẹnu ọna ile wa ki n tọ maa lọ si ibiṣẹ''
O ki mi pe o daabọ lẹyin ti mo fun ni bisikiiti ati ọgẹdẹ.
O loun fẹ di dokita to ba dagba nitori bo ṣe n ri ti mo n lọ si ibiṣẹ nileewosan.
Dr Midhat Saidam

Nirọlẹ ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹwaa Dr Saidam loun fẹ sinmi diẹ.
Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta oniṣẹabẹ yi ko ti ribi kuro nileewosan al-Shifa ni Gaza lati nkan bi ọsẹ kan to ti wa nibẹ.
O sọ fun awọn akẹgbẹ rẹ pe oun fẹ fẹsẹ kan dele.
Amọ lẹyin wakati diẹ to dele tan ni ado oloro ti Israel ju lu ile rẹ ṣekupa.
''Ọlọyaya ati alaanu yi pada wa si ileewosan to ti kuro laarọ ọjọ keji amọ oku rẹ ni wọn gbẹ wa''
Bẹẹ ni ọkan ninu awọn alabaṣiṣẹ rẹ Dokita Adnan Albursh ti ṣe ṣalaye.
Dokita Albursh, ti wọn jijọ mọra lati nkan bi ogun ọdun sẹyin fi kun pe inagijẹ tawọn alabaṣiṣẹ rẹ n pe Dr Saidom ni ''oniṣẹẹabẹ ti kii sinmi''
Ko si sẹyin ifarajin to ni fun iṣẹ rẹ.
O tun jẹ ẹni tawọn dokita kekeeke a maa wo lawokọṣe.
Olori ẹka awọn to n ṣiṣẹ abẹ nileewosan al-Shifa Dr Ahmed El Mokhalla sọ pe''Bi ẹnikankan ninu awọn dokita ba koju ipenija kankan wọn mọ pe Dr Saidam lo le bawọn wa ojutu si.''
''Kii ṣe awa nikan nileewosan yi la padanu ẹni nla yi bi kii ṣe ẹka iwosan lapapọ''
Nour Yousef Al Kharma

Lọjọ kọkanla oṣu Kẹwaa Nour akẹkọọ ẹni ọdun mẹtadinlogun kagbako iku nigba ti ado oloro ṣe ikọlu si ile awọ́n obi rẹ to wa ni Deir al-Balah gẹgẹ bi aburo baba rẹ ṣe sọ.
Mohammed al-Kharma sọ pe Nour fẹ ko lọ sọdọ awọn mọlẹbi wọn nibo mii tori ado oloro ti wọn n ju sawọn ile ni Gaza.
''Baba rẹ lo sọ pe ko duro si ile wọn lai mọ pe wọn yoo ju ado oloro lu u nibẹ. Owurọ ọjọ keji ni ado oloro kọlu.Kadara rẹ ni.''
Nour ati ibatan rẹ kan Yazan ni wọn jijọ padanu ẹmi wọn.
Wọn jijọ n ṣere ninu ile ni.
Awọn ẹgbọn rẹ obinrin Ola ati Huda ti wọn n dana pẹlu iya wọn Jamalat moribọ ni tiwọn.
Kilasi ipari ni Nour wa ni ileẹkọ giram to si lero lati di dokita lọjọ iwaju.
Ẹgbọn baba rẹ sọ pe wọn ri apati rẹ fayọ labẹ ile to wo wọn si ba iwe rẹ to maa n kọ nkan si ninu rẹ.
Loju ewe kan nibẹ lo kọ ọrọ si pe ''Mo fẹ mu ori awọn mọlẹbimi wu maa si yege nidi ẹkọ mii pẹlu ogo Ọlọrun''
Lurin Azzam Abuhalima

Ninu ọrọ rẹ to kọ kẹyin si ọkọ afẹsọna rẹ Khaled al-Masry, Lurin sọ pe sisaka lati ibi kan omiran yi tori ogun ti ṣu oun.
Ẹni ọgbọn ọdun yi ṣẹṣẹ de si ibudo awọn ogunlende to wa Nusairat to wa laarin Gaza nibi to ti wa ba aburo ababrẹ lobinrin.
O ti ṣaaju moribọ ninu ikọlu ado oloro meji to fi mọ ọkanto waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa to pa ile toun ati awọn obi rẹ́
O ti ṣaaju moribọ ninu ikọlu ado oloro meji to fi mọ ọkan to waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa to pa ile to n gbe pẹlu awọn obi rẹ mọlẹ.
Khaled loun ranti pe '' O sọ fun mi pe oun fẹ ṣanra ki oun si kirun koun wa sinmi to ba ṣetan''
Gẹgẹ bi afẹsọna rẹ to n gbe ni Cyprus ti ṣe wi, irun lo n ki lọwọ ninu ile nigba ti ado oloro ja lu ile to wa.
''Ori irun to n ki lọwọ lo ti padanu ẹmi rẹ''
Lurin ati Khalid ti sun ọjọ igbeyawo wọn siwaju lẹẹmeelo kan tori binkan ko ṣe fini lọkan balẹ ni Gaza.
Oṣu Kejila ọdun yi ni wọn gbero pe awọn yoo ṣe igbeyawo ti wọn yo si ko lọ si Cyprus.
Pẹlu ibanujẹ ọkan Khaled sọ pe ''O ti n sinmi isinmi ayeraye bayi. Aṣọ funfun lo maa n wọ amọ o ti tẹri gba aṣọ funfun bayii.''
Lurin and Khaled had postponed their wedding a couple of times due to the unstable situation in Gaza.
They were planning finally to get married in December and move to Cyprus.
A devastated Khaled said: "She is now resting forever. She used to wear a white dress, but now is wearing a white shroud."
Fekriya Hassan Abdul A'al

Awọn to ba fẹ ra aṣọ obinrin ni agbegbe Radwan ni Gaza a maa saba lọ sọdọ Fekriya Hassan Abdul A'al.
Ọmọ rẹ obinrin Nevine sọ pe ''Mo ranti igba tawọn to ba fẹ ṣe igbeyawo ati ọrẹ iya maa n kun ṣọọbu iya mi lati wa ra aṣọ.O mọṣẹ pupọ''
Arabinrin ẹni ọdun marundinlaadọrin yi ati awọn ọmọ iya rẹ meji, ọmọ bibi rẹ meji ati awọn ọmọọmọ meji ni wọn jijọ kagbako iku nigba ti Israel ju ado oloro si ile ti wọn sa asala si lọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹwaa.
Nevine to sa asala ni ile ọrẹ rẹ kan sọ pe Mama rẹ nifẹ mọlẹbi pupọ ati pe a maa ko ẹbi jọ lọsọọsẹ fun apejẹ.
Nevine sọ pe ogun to n waye yi ti ko irẹwẹsi ọkan ba mama rẹ.
O ni ''nigba taa sọrọ kẹyin lori ago mama mi sọ pe: Iporuru ọkan ti ba o siti rẹ ẹmi mi pẹlu ogun alailopin to n waye yi''
Mazen and Ahmed Abu Assi

Ọmọ iya mejilọkunrin Mazen, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Ahmed ọmọ ọdun mẹtala wa lara awọn ti ibugbamu towaye ni ileewosan al-Ahli ṣekupa lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa.
Awọn alaṣẹ Palestine sọ pe ado oloro lati ọwọ Israel loṣokunfa rẹ.
Amọ ileeṣẹ ologun Israel tako ọrọ yi ti wọn si ni ado oloro ti Hamas yin ṣugbọn ti ko lọ ibi ti wọn ran lo fa ibugbamuyi lati ọwọ ikọ Islamic Jihad.
Awọn ikọ yi sọ pe awọn ko lọwọ ninu ibugbamu naa.
Abu Massi,baba awọn ọmọ mejeeji yi sọ pe wọn nifẹ ara wọn ṣugbọn iwa wọn yatọ sira.
Arafat ati iyawo rẹ pori ileewosan fọdun mẹjọ gbako ti wọn fi n wa oyun Mazen ki wọn to pada fi ilana IVF loyun rẹ.
Mazen loun fẹ di dokita to n tọju ilera eyin.
''Oun lo mọwe julọ ninu awọn ọmọ mi''
Baba awọn ọmọ yi juwe Ahmed gẹgẹ bi ''eyi to jẹ akin julọ ninu awọn ọmọ ninu idile wa-oun naa lo si tun lọrọ aje julọ''

''O maa n ta nkan isere ọmọde ati awọn nkan eelo ile ẹkọ ni ṣọọbu kekere kan lẹgbẹ ile wa''
Ọmọ rẹ kan ṣoṣo to ṣẹku bayii ni Faraj ọmọ ọdun mẹta ti Arafat sọ pe kii ye sunkun ti a si maa beere pe nibo lawọn ẹgbọn rẹ wa.
''Mo sọ fun pe Ọlọrun ti kesi wọn lati duro sọdọ rẹ. Aaye to dara julọ ree fawọn ọmọ mii meji ti wọn jẹ ọmọluabi''
Salam Mema

Salam Mema jẹ akọroyin ẹni ọdun mẹejilelọgbọn ọmọ Palestine ti wọn pa lọjọ Kẹwaa oṣu Kẹwaa nigba ti ado oloro ba ile rẹ to wa lagbegbe Jabaliya ni ariwa Gaza.
Ọkọ rẹ,ọmọ wọn ọmọ ọdun meji Sham,ọmọ wọn ọmọ ọdun meje Hadi ati awọn mọlẹbi wọn mii naa padanu ẹmi wọn.
Ọmọ wọn ọmọ ọdun marun unAli nikan lo ṣẹku bayii.
Ninu awọn akọroyin mọkanlelọgbọn ti akọsilẹ wa ni ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa pe wọn padanu ẹmi wọn lati igba ti ogun Hamas ati Israel bẹrẹ ni Salam wa.
Safaa Nezar Hassouna

Ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to jẹ apoogun yi padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu ado oloro to waye ni guusu Rafah.
Iku deba nibi to ti sun lẹgbẹ ọmọ rẹ ọmọ oṣu mẹta Elyana ati ọkọ rẹ.
Aburo baba rẹ to jẹ dokita nilẹ Gẹẹsi, Omar Hassouna sọ pe awọn obi rẹ moribọ ninu ikọlu yi ṣugbọn wọn ko ribi sọrọ nitori bi iku rẹ ṣe ka wọn lara to.
Omar sọ pe igba toun baa sọrọ kẹyin ni oṣu kini lasiko toun lọ fun isinmi ọlide ni Gaza.
''Ọmọ to lojuti ni Safaa ti a si maa fi apọnle ba awọn eeyan sọrọ. Gbogbo eeyan lo nifẹ rẹ.''
Iku rẹ yi ka eeyan lara gẹgẹ bi awọn iku awọn to ku ni Gaza.
''Ki ba wu mi ki n wa ni Gaza bayii pẹlu wọn.O ka mi lara bi mi o ṣe ri nkankan ṣe fun wọn lati ibi''














