Arming Israel: 120,000 Ọmọ Israẹli ló tí kọ̀wé láti gbà ìyọ̀nda kí wọn lè rà ìbọn ìléwọ́

Oríṣun àwòrán, getty
- Author, Muhannad Tutunji & Claire Press
- Role, BBC Arabic, Israel
Lati igba ti ikọlu Hamas ti waye lọjọ Keje oṣu Kẹwaa nibi ti ọmọ Israel to le ni 1,400 padanu ẹmi wọn, o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa iwe ibeere aṣẹ ibọn lilo tawọn araalu ti fi ranṣẹ sawọn alaṣẹ.
Jakejadi orileede naa lawọn eeyan n ṣe kirakita lati ri ibọn gba.
Se lawọn eeyan n kun awọn aaye oju ọta nibi ti wọn ti n kọ ibọn yiyin.
Ni ita awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta ibọn awọn eeyan pọ to to nibẹ ti wọn fẹ ra ibọn.
Lẹyin ti ijọba kede pe awọn yoo dẹwọ ilana to de ibọn rira,awọn to kaju oṣunwọn ti wọn ko ni akọsilẹ iwa ọdaran tabi ipenija ilera kankan ti bẹrẹ si ni ri ibọn ra laarin ọsẹ kan.
Anfaani situn wa fawọn eeyan lati le ra to ọta ibọn ọgọrun dipo aadọta ti wọn le ra tẹlẹ.
Omri Shnaider to jẹ agbẹjọro ẹni ọdun mọkanlelogoji to wa lati ibugbe kan to wa lẹba Jerusalem sọ pe ''Ni bayii tori ti wọn yọ gbogbo idiwọ kuro, o ti wa rọrun lati ri ibọn ra bayii''
Amọ inu arakunrin Shnaider ko dun si igbesẹ yi to si ni yoo ni ipa ti yoo ko ti wọn ba bẹrẹ si ni gbe ibọn fawọn ẹgbẹgbẹrun araalu.
''Daada wa nibẹ, bẹẹ naa lo si ni kudiẹ kudi.A ri iru nkan to ṣẹlẹ lorileede America.Kii ṣe ipinnu to rọrun lati gbe.Amọ nkan ti mo ro wi pe o yẹ ka gbe ni igbesẹ ree ki aabo to peye baa le wa fun awọn eeyan Israel.''
Minisita aabo labẹle Itamar Ben-Gvir to jẹ ọkan lara awọn to faramọ ki araalu ni ibọn ti wọn ti n kaakiri orileede naa to si n pin ẹgbẹgbẹrun ibọn fawọn eeyan.
O ni ibọn yi wa fun awọn to n gbe agbegbe to sunmọ ibode pẹlu Gaza tabi ti wọn n gbe agbegbe ti awọn Jew ati Larubawa jijọ n gbe.
Bẹẹ lo gba awọn Jew lagbegbe naa pe ki wọn ṣeto igbimọ aabo arawọn.

Oríṣun àwòrán, getty
Ọgbẹni Schnaider n gbe adugbo to tobi ti awọn igba ẹbi si n gbe nibẹ.
O faramọ igbesẹ kawọn araalu naa dira pẹlu ibọn.
''Nitori ohun to n ṣẹlẹ, a pinnu lati wa ibọn fun aabo arawa ni adugbo wa.Awọn fijilante wa ni yoo gbe igbesẹ ti o ba ṣeeṣe pe awọn agbesunmọmi fẹ wọle siwa lara''
Ṣugbọn bo ṣe jẹ wi pe wọn gbiyanju ọna ati daabo bo arawọn lawọn ọpọ ibi ti awọn Jew n gbe awọn larubawa to jẹ ọmọ Israeli sọ pe kan awọn kobalẹ.
Ida ogun ninu ida ọgọrun lawọn eyi jẹ ninu awọn ọmọ ilẹ Israeli.
Awọn ọmọ Israeli to jẹlarubawa yi ti fi to BBC leti pe iṣẹlẹ idẹyẹsi ati eebu loju aye ati loju opo ayelujara a maa ṣẹlẹ sawọn jakejado ilẹ Israeli.
Ni paapa ilu kan torukọ rẹ n jẹ Lod ni aarin gbungbun Israel jẹ ibi kan ti iru idẹyẹsi tori ẹya bayii ti n waye.

Lati igba ti wọn ti bi ni Suhair Hamdouni to jẹ akọṣẹmọṣẹ olukọ awọn mọ to ni ipenija ti n gbe ni Lod.
Ile awọn Jew wa lapa kan ilu ti tawọn Palestine naa si wa lapa keji.
O sọ pe lati igba ti ikọlu Hamas ti waye, oun ko le lọ ra nkan eelo lagbegbe tawọn Jew n gbe
O ni kaka bẹẹ, oun a maa yipo gba ọdọ awọn larubawa nitori ẹru pe ki wọn maa ṣe ikọlu si oun.
''Wọn ti ṣe ikọlu si wa tẹlẹ rininu ile wa.Ojojumọ lẹru n ba wa bi a ba ranti iṣẹlẹ yi''
Awọn larubawa ilẹ Israeli ti ọpọ ninu wọn a maa pe ara wọn ni eeyan ilẹ Palestine ni wọn ko faaye gba lati darapọ mọ ileeṣẹ ologun.
Lai si ni igbaradi ologun yi, yoo ṣoro ki wọn to le ri iwe aṣẹ lati le ra ibọn.
O ni ''ẹru n ba mi pẹlu bi awọn Israeli ṣe n ribi ṣamulo ẹtọ wọn lati daabo bo ẹmi ara wọn.O le ja si iku fun mi.Emi ati awọn ọmọ mii ọkunrin.''
''Eru o ba mi tori pe mo ṣaburu bi kii ṣe pe tori mo jẹ larubawa.Bi wọn ba fun awọn Jew to wa lagbegbe mi lẹtọ ati ra ibọn, ko yẹ ki wọn di emi naa lọwọ lati ri ibọn ra. Abi ki wọn si kuku ma gba ẹnikankan ninu wa laaye lati ra ibọn''
Lati igba ti ikọlu yi bẹrẹ,awọn ilu ti larubawa ati Jew jijọ n gbe ni Israel ko ti ribi gbalejo awọn to wa fun igbafẹ mọ.
Titi pa ni ọpọ awọn ṣọọbu ati ile ounjẹ wa ti wọn si da paroparo.
''O le ni ida ọgọta awọn alabara mi to jẹ Jew.''
Bẹẹ ni arakunrin kan to ni ile ounjẹ ni Lod, Abu Amir ṣe sọ.
''Amọ bayii, wọn ko wa mọ. Ko si eeyan kankan to n wa sọdọ mi.Awn larubawa n bẹru lati lọ si agbegbe awn Jew. Awọn Jew naa n bẹru lati lọ si agbegbe awọn larubawa.''












