Àwọn kókó ohun tó mú kí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì wọn ní Nàìjíríà

Aworan awọn oṣiṣẹ to n wọde

Oríṣun àwòrán, nlc/x

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti ṣẹwe le iyanṣẹlodi wọn eyi to yẹ ko bẹrẹ ljọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta oṣu kẹwaa ọdun 2023.

Igbesẹ naa waye lẹyin ipade laarin awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ.

Bi o tiẹ jẹ pe ọpọ lo ti fi ọkan si pe iyanṣẹlodi naa yoo waye gẹgẹ bi wọn ṣe kede, awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe ọrọ naa ko ṣai ni idi to fi pada ja si bẹẹ.

Lara awọn koko ohun ti wọn ṣalaye pe o fa eyi niwọnyii:

  • Ijọba apapọ bu ọwọ lu owo oṣu tuntun, ẹgbẹrun marundinlogoji naira fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, bẹrẹ lati oṣu kẹsan-an, ọdun yii, titi di igba ti wọn yoo fi bu ọwọ lu owo oṣu tuntun ti gbogbo oṣiṣẹ yoo maa gba.
  • Ijọba apapọ yoo yọ ọwọ kuro lori owo ori epo disu (diesel) fun oṣu mẹfa gbako, bẹrẹ lati oṣu kẹwaa, ọdun 2023.
  • Ijọba apapọ ti gba lati gbe ọgọrun-un biliọnu naira kalẹ fun ipese bọọsi ti yoo maa lo afẹfẹ gaasi kaakiri Naijiria. Eto tun ti wa nilẹ fun yiyi ẹgbẹrun marundinlọgọta ọkọ pada si eyi to n lo afẹfẹ gaasi kaakiri ileẹkọ giga lorileede Naijiria.
  • Ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati bẹrẹ sii gba owo ori tuntun lọwọ awọn ileeṣẹ aladani ati araalu.
  • Ileeṣẹ to n sọrọ awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ igbesẹ lori awọn owo ajẹẹlẹ ti awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ l’awọn ileẹkọ giga to jẹ ti ijọba apapọ.
Aworan atẹjade NLC

Oríṣun àwòrán, NLC/x

Aworan atẹjade NLC

Oríṣun àwòrán, NLC/x

  • Ijọba apapọ yoo ba awọn ijọba ipinlẹ sọrọ nipasẹ ipade awọn alẹnulọrọ lori eto ọrọ aje (National Economic Council) ati ẹgbẹ awọn gomina lati ṣagbeyẹwo owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ ijọba wọn. Eyi si gbọdọ kan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aladani.
  • Gẹgẹ bi Aarẹ ṣe ti kede lọjọ kini, oṣu kẹjọ wi pe ijọba apapọ yoo gbe owo jade fun awọn ileeṣẹ ati olokoowo keekeeke (Micro and Small Scale Enterprises), lati rii daju pe wọn ṣe iṣẹ gidi ti yoo jọju.
  • Abẹwo apapọ yoo waye s’awọn ile ifọpo to wa kaakiri Naijiria, lati ṣe agbeyẹwo bi atunṣe yoo ṣe waye.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC àti TUC ní Nàìjíríà dá ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n fẹ́ gùnlé dúró fún oṣù kan
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress/X

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ti kede pe awọn ti da iyanṣẹlodi ọlọjọ pipẹ tawọn fẹ gunle lonii ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa ọdun 2023 duro fun oṣu kan.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣiṣẹ kede erongba rẹ lati gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ pipẹ lẹyin ti ijọba ko fẹnu ko pẹlu wọn lori nkan meje ti wọn n beere fun.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe ikede naa latari owo iranwọ ori epo ti ijọba apapọ yọ kuro eleyii ti o si jẹ ki gbogbo nkan gboow lori ni Naijiria.

Amọ, lẹyin ọpọ ipade pẹlu ijọba, ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC kepe gbogbo ọmọ ẹgbẹ lalẹ ọjọ Aje ki onikaluku wọn si lọ sibi iṣẹ lonii ọjọ Iṣẹgun wi pe awọn ti da iyanṣẹlodi ọhun duro na.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lalẹ ọjọ Aje eleyii ti aarẹ ẹgbẹ NLC, , Joe Ajaero, akọwe agba ẹgbẹ naa, Emmanuel Ugboaja, aarẹ TUC, Festus Osifo ati akọwe agba ẹgbẹ naa, Nuhu Toro buwọlu ni wọn ti ṣe ikede naa.

Awọn aṣoju ijọba to wa lara awọn to buwọlu atẹjade naa ni minisita ọrọ awọn oṣiṣẹ ati ipese iṣẹ, Simon Lalong ati igbakeji rẹ, Ọmọwe Nkeiruka Onyejeocha ati minisita eto iroyin pẹlu ilanilọyẹ, Mohammed Idris.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post