Àwọn ajínigbé tó jí àwọn akọrin gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo ti ń kàn sí wa lórí ohun tí wọ́n fẹ́ - Àlùfáà Ìjọ
Ni aipẹ yii lawọn ajinigbe ji awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin ijọ CAC Odubanjo Regional headquarters to wa lagbegbe Oke Igan, Ẹringboni ilu Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo gbe.
Ninu ọrọ ti Alufaa ijọ naa, ba BBC News Yoruba sọ, o ni aluduru ijọ wọn lo n ṣe oku obi rẹ kan ti wọn fi lọ.
Igba ti wọn n pada bọ lawọn ajinigbe naa dabu wọn lọna ti wọn si ko wọn wọ inu igbo lọ.
Alufaa naa ni ọkan lara awọn eeyan to sunmọ ijọ naa lo kọja lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ to si ri ọkọ bọọsi ijọ naa lo wa ta alufaa wọn kan lolobo.
O ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Ẹlẹgbẹka ni opopona Ọwọ-idoani si Ifọn ni wọn ti ji wọn gbe.
Awọn ajinigbe naa ti kan si ijọ, wọn si ti sọ ohun ti wọn n fẹ

Alufaa ijọ naa ni ọkan lara awọn ti wọn ji gbe naa, to si tun jẹ pasitọ ni ijọ naa lo pe to si ni awọn ajinigbe ọhun n beere owo.
“Ajinigbe yẹn gba foonu lọwọ rẹ, o sọ fun emi gan pe aadọta miliọnu lawọn fẹ gba bayi bayii. Mo wa ni pe ko mu suuru pe a maa de ọdọ wọn.”
Awọn mẹjọ sa asala bọ mọ awọn ajinigbe naa lọwọ
Bakan naa la gbọ pe ninu awọn eeyan ogun ti awọn ajinigbe yii ji gbe, mẹjọ ninu wọn ti moribọ mọ awọn ajinigbe naa lọwọ.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, mejila ninu awọn akọrin naa lo wa ni ahamọ awọn ajinigbe ọhun.
Alufaa ijọ naa ni awọn mẹjọ naa wa ni agọ ọlọpaa to wa ni ilu Ipele nipinlẹ Ondo kan naa.

Ileeṣẹ Ọlọpaa, Alufaa ijọ CAC ṣalaye igbesẹ to n waye lati ṣeto itusilẹ awọn akọrin naa
Nigba to n ṣalaye lori igbesẹ ti ijọ n gbe lori iṣẹlẹ naa bayii, alufaa ijọ CAC Oke Igan, Ẹringboni ilu Akurẹ naa ṣalaye pe awọn ọmọ ijọ ti wolẹ adura lati igba to ti bẹrẹ.
O ni awọn ṣọja, ọlọpaa atawọn amọtẹkun lo ti gbọ si iṣẹlẹ naa ti wọn si ti n gbe igbesẹ.
Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, DSP Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ kaakiri inu igbo ti wọn ko wọn wọ.
O ni awọn fijilante atawọn araalu wa lara awọn to n ṣeto ati ṣe awari awọn ti wọn ji gbe naa.
Bakan naa lo fi idaniloju han pe gbogbo awọn to ku ni ahamọ awọn ajinigbe naa ni wọn yoo tu silẹ laipẹ.



