Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn kan ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan

Oríṣun àwòrán, TRACE/FRSC
Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn ara agbegbe Magboro to wa lopopona marosẹ Eko si Ibadan, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun lọjọ ayajọ ominira bi ijamba ọkọ ṣe gbẹmi eeyan kan ti awọn miiran si farapa yannayanna.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ ṣe sọ, nnkan bi aago mẹsan-an kọja iṣẹju mejila aarọ ni ijamba naa waye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri sọrọ eto aabo oju poponipinlẹ Ogun, Traffic Compliance and Enforcement Corps (TRACE) nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi ṣalaye pe awakọ Benz kan lo padanu ijanu ọkọ rẹ lori ere, to si lọ kọlu bọọsi Mazda akero kan.
Akinbiyi ni eeyan mẹsan-an lo fara kaṣa ninu ijamba naa, leyi ti awọn marun-un jẹ ọkunrin, ti awọn mẹrin si jẹ obinrin.
Bakan naa lo ṣapejuwe ọkọ Benz naa pẹlu nọmba dainmọ AKD 424HH, ati bọọsi ọhun to ni nọmba idanimọ KSF 93 YA.
O ṣalaye pe ni loju ẹsẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye l’awọn oṣiṣẹ wọn ti sare debẹ lati doola ẹmi awọn eeyan, to si ni ẹpa ko boro mọ fun ọkunrin kan toun ku loju ẹsẹ, ṣugbọn to sọ pe awọn yooku to farapa ti wa nile iwosan fun itọju.
Agbẹnusọ naa ni nipasẹ iranlọwọ awọn ati ajọ ẹṣọ oju popo t’ijọiba apapọ, iyẹn Federal Road Safety Corps (FRSC) ati awọn ọlọpaa l’awọn fi gbe awọn to farapa lọ si ile iwosan kan to wa nitosi fun itọju, ati pe ọkunrin to padanu ẹmi rẹ l’awọn gbe oku rẹ lọ si mọṣuari.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti wọ awọn mọto mejeeji naa lọ sinu ọgba wọn to wa ni Arepo.















