Wo àwọn kókó tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà ní àyájọ́ òmìnira

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti tun kede ifarajin si idagbasoke ati igbayegbadun awọn ọmọ Naijiria.

Tinubu fi awọn ọrọ aridaju yii han nigba to n ba awọn araalu sọrọ ni ayajọ ọjọ ominira Naijiria to waye lọjọ kiini oṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Igba akọkọ niyi ti Tunubu yoo maa ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ayajọ ominira lẹyin to di aarẹ Naijiria, to si tun ṣe awọn ileri tuntun lori awọn afojusun rẹ fawọn eniyan orilẹ ede yii.

Ni nnkan bii aago meje aarọ ni Aarẹ Tinubu sọrọ lori amohunmaworan lati tun f’ọkan awọn araalu balẹ lori awọn ipenija ti Naijiria n dojukọ lasiko yii.

Nigba to n sọrọ, Tinubu ipa ti awọn Baba-nla Naijiria, ti wọn ronu jinlẹ lati kuro l’oko ẹru, ti wọn si gba ominira ko kere rara ati pe ọkan akikanju ni wọn fi ṣe e.

Àwọn kókó tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìyí:

Ṣiṣe atunṣe ko rọrun, ṣugbọn ọna abayọ wa

Aarẹ Tinubu sọ pe bo tilẹ jẹ pe ṣiṣe atunṣe ko rọrun, nitori pe o maa n mu irora dani, ṣugbọn sibẹ, o sọ pe ohun ti idagbasoke n fẹ niyẹn.

O sọ pe Naijiria ti n gbe akaba aṣeyọri lọ sibi giga, nitori pe ko si lọwọ awọn alajẹbanu mọ kereje bayii.

O kọminu gidi, to si ni ko si ayọ ninu lati maa foju ri iṣoro t’awọn eeyan n koju, eyi to yẹ ki awọn adari to ti kọja lọ ti ṣabojuto rẹ.

"Ko wu mi ki ohun ti a n la kọja bayii ṣi maa ṣẹlẹ, ohun to yẹ ko ti kọja lọ tipẹ ni," ṣugbọn to ni Naijiria yoo too de ilẹ ileri.

Afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ

Ninu ọrọ rẹ siwaju sii lo ti sọ pe lori ọrọ t’awọn n ba awọn adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, awọn onileeṣẹ ati awọn alẹnulọrọ sọ, Tinubu ni iṣakoso oun ti n ṣiṣẹ lori ẹkunwo lori owo oṣu lai ni ipalara.

O sọ pe laarin oṣu mẹfaa si asiko yii, oṣiṣẹ to kere julọ lẹnu iṣẹ yoo tun gba ẹgbẹrun marundinlọgbọn le owo oṣu to n gba tẹlẹ.

Bẹẹ lo tun sọ pe oun yoo fi owo kun owo akanṣe iṣẹ idagbasoke.

Bakan naa lo kan saara si awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fun akitiyan wọn lori ilu, tó si ni bi o tilẹ jẹ pe awọn kii fẹnuko ni gbogbo igba, oun ko ko iyan wọn kere rara.

Irọrun yoo ba igbokegbodo ọkọ

Koko pataki ti Aarẹ Tinubu tun mẹnuba ni ti ọrọ igbokegbodo ọkọ.

O ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ri pe awọn ọkọ bẹrẹ sii lo afẹfẹ gaasi, eyi ti yoo jẹ ki owo t’awọn araalu n wọ ọkọ dinku.

Eto aabo

Tinubu sọ pe lara awọn ohun to ṣe pataki si oun ni eto aabo ẹmi ati dukia araalu,

O ni gbogbo ojuṣe to ba yẹ loun yoo ṣe lati rii pe awọn araalu n sun, wọn si n di oju wọn lai bẹru ohunkohun.

Yiyọ iranwọ ori epo bẹntiroolu

Tinubu tun tẹnumọ pe nitori awọn alajẹbanu ti wọn n jẹ nidii owo iranwọ ori epo lo fa a toun fi yọ subsidy naa danu lai woju ẹnikẹni.

O sọ pe nigba ti wọn n bura foun, ọrọ akọkọ toun sọ ni pe oun yọ iranwọ, pẹlu ileri wi pe oun yoo tukọ orileede yii daadaa. O ni lara awọn ileri naa ni lati mu atunṣe si ọrọ eto ọrọ aje, ati lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Ipese iṣẹ

Aarẹ ṣalaye pe oun ti n ba awọn ile iṣẹ to le dokoowo si Naijiria sọrọ lati wa da ileeṣẹ silẹ lojuna ati pese iṣẹ fun awọn ọmọ orilẹ ede yii.

O fi kun pe awọn ti n pese aaye fun awọn olokoowo keekeeke lati goke agba nipa pipese aaye tun dun ṣiṣẹ fun wọn.

O tun tẹsiwaju pe awọn n wa gbogbo ọna lati ri pe awọn obinrin atawọn ọdọ ri aaye atawọn ipo to dara mu ninu iṣejọba oun.

Bẹẹ naa lo wi pe awọn akanda eniyan naa ko ni gbẹyin ninu awọn ti awọn n pese aye lati ri ọwọ mu fun.

Ọrọ CBN

Tinubu ni ohun to foju han ni pe eto iṣẹ ṣiṣe ni ile ifowopamọ apapọ Naijiria iyẹn CBN nilo amojuto to peye ti awọn si ti bẹrẹ igbesẹ rẹ nipa yiyan awọn olori tuntun sibẹ.

O ni awọn oluwadii ti oun gbà lati ṣewadii awọn iṣẹ CBN yoo to gbe ijabọ wọn kalẹ laipẹ.

O fi kun pe o da ohun loju pe gbogbo awọn eto ti yoo maa jade lati ile ifowopamọ naa lati asiko yii lọ maa jẹ eyi to maa ṣe anfani fun gbogbo awọn ara ilu dipo awọn ọlọrọ kan lọ.

Tinubu kéde N25,000 gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ onípò kékèké lóṣooṣù

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook

Aarẹ Bola Tinubu ti kede ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn naira loṣooṣu gẹgẹ bi owo iranwọ fawọn oṣisẹ ijọba onipo kekeke.

Aarẹ Tinubu sọrọ yii ninu ọrọ to bawọn ọmọ Naijiria sọ lori ẹrọ amohunmaworan fun ayajọ ominira ọdun kẹtalelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira.

Tinubu sọ ninu ọrọ rẹ pe oun kede owo yii lati le ṣe iranwọ fawọn oṣiṣẹ ti owo oṣu wọn ko gbewọn to pẹlu bi gbogbo nkan ṣe gbowo lori lọja bayii.

Aarẹ Naijiria ni awọn oṣiṣẹ yii yoo jẹ anfaani owo naa fun oṣu mẹfa lati akoko yii lọ.

Bakan naa ni Tinubu sọ pe ijọba oun si n ṣiṣẹ lori afikun owo oṣu tuntun fawọn oṣisẹ ni Naijiria.

O tun sọ ninu ọrọ rẹ pe oun mọ ohun tawọn ọmọ Naijiria n la kọja latari bi ijọba ṣe yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro.

Tinubu ni gbogbo nkan ni yoo pada dẹrọ pẹlu bi awọn eeyan ti n fara da ọwọngogo nkan lọja bayii.

Aarẹ Tinubu tun ṣalaye pe ijọba oun ti pese awọn ọkọ ti yoo maa gbe awọn eeyan ni ẹdinwo kaakiri gbogbo ipinlẹ ni Naijiria pẹlu bi owo ọkọ ti di gọbọi bayii.

Tinubu wa rọ ọmọ Naijiria wi pe ki wọn tubọ ni ifarada sii wi pe didun ni ọsan yoo so laipẹ lai jina.