Ohun tó wáyé níbi ìjókòó ìgbìmọ̀ olùwádìí lórí ikú Mohbad rèé

Igbimọ oluwadi Korona ti jokoo lana ọjọ Ẹti nile ẹjọ Magisireti to wa nilu Ikorodu.
Eredi ijoko wọn naa ni lati sawari iru iku to pa Ilerioluwa Aloba, ti se akọrin takansufe ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad.
Lẹyin ijoko naa ni igbimọ onigbẹjọ Korona naa wa sun ijoko rẹ siwaju di ọjọ kẹtala osu Kẹwa ọdun 2023 nigba ti awọn ẹlẹri ti wọn pe lori iku akọrin naa yoo yọju sibẹ.
Ilé ẹjọ́ ti pinnu láti pe àwọn ẹlẹ́rìí wá lórí ikú Mohbad - Agbẹjọ́rò ẹbi olóògbé
Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹjọro fun ẹbi Mohbad, Funmi Falana salaye pe ijoko akọkọ igbimọ oluwadi naa lo wa lati pinnu boya wọn yoo pe ẹlẹri wa sile ẹjọ naa tabi bẹẹ kọ.
“Ohun ta se lonii ni lati kọkọ pinnu lori boya ka pe awọn ẹlẹri wa ati ilana ti igbẹjọ naa yoo gba eyi ti yoo mu ki idajọ ododo foju han.
A ti wa mu ọjọ Kẹtala osu Kẹwa ọdun yii fun ijoko miran, ti a si tun pinnu lati ko awọn ẹlẹri wa sile ẹjọ.
Ifẹ awọn eeyan ni awa duro fun, a si gbọdọ gba ki alaafia jọba, ti idajọ ododo yoo si wa, a si ri okodoro ọrọ nipa iru iku to pa Mohbad. ”
"Ko si ẹlẹri ti ile ẹjọ ba pe, ti yoo lori laya sọ pe oun ko ni yọju si wọn"
Bakan naa, agbẹjọro agbefọba to ba gbe ẹjọ kalẹ fun iwadii lori iku Mohbad, Festus Ogun naa fikun pe ko si ẹlẹri ti ile ẹjọ naa ba pe, ti yoo lori laya sọ pe oun ko ni yọju si wọn.
Ọrọ naa yoo di iwa arifin sile ẹjọ ni ti eyikeyi ẹlẹri ti wọn ba pe ko ba fi ara rẹ han nile ẹjọ, a jẹ pe o tun ti da ẹsẹ mii niyẹn.’’
Ogun fikun pe iye awọn ẹlẹri to ba yọju siwaju ile ẹjọ naa ni yoo sọ bi igbẹjọ iwadii naa yoo ti pẹ to.
Amọ o wa fi ọwọ idaniloju sọya pe igbẹjọ naa ko ni falẹ rara.
Ìgbìmọ̀ olùwádìí bẹ̀rẹ̀ ìjókòó láti ṣàwárí ikú tó pa Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad
Ìgbìmọ̀ oluwadi yóò jókòó n'ilu Eko láti ìtànná wádìí wọn sì ikú tó pá gbajúmọ̀ akọrin takasufe nnì, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ sì Mohbad.
Mohbad, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, lọ dagbere fàyè ni ojo Kejìlá oṣù Kẹ̀sán ọdún 2023, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń fapa janu pé ikú rẹ̀ kii se lati ọdọ Ọlọhun wá.
Atẹjade kan tí iléeṣẹ́ tó ń ṣèwádìí láti mọ irú ikú tó pá òkú kan nipinlẹ Eko, Lagos Coroner inquest kọ sawọn agbẹjọro to ni nnkan se pẹlu iku Mohbad, lo sísọ loju ọrọ yii.
Ileẹjọ Magistrate kẹta, to wa ninu ile ẹjọ Candide Johnson, Ita-Elewa ninu Ikorodu ni ijoko igbimọ oluwadi naa yoo ti maa waye.
Iwe ipe kan naa, ti wọn buwọlu lorukọ Adajọ oluwadi agba, Adajọ Dada salaye pe deedee aago mejila Ọsan Ọjọ Ẹti, ni ijoko igbimọ naa yoo maa waye.
Atẹjade naa ni “ọọfisi oluwadi agba, Adajọ Dada ti dari mi lati fi to yin leti pe igbimọ naa yoo joko lati wadi iru iku to pa Mohbad.”
Saaju ni gbajugbaja agbẹjọro kan, Agba Amofin Femi Falana ti kọwe si igbimọ naa pe awọn fẹ m iru iku to pa gbajumọ akọrin takansufe naa.
Bi ijokoo igbimọ oluwadi naa ba se n lọ, ni BBC Yoruba yoo maa mu iroyin naa wa fun yin.

Oríṣun àwòrán, Mohbad
Mohbad gba pósí ọ̀fẹ́, gbọ̀ngàn ìgbàlejò ọ̀fẹ́, ẹ̀dínwó ibojì àtàwọn nǹkan míì fún ìsìnkú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì - Iyabo Ojo
Alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Ebony Vaults niluu Eko ti ṣeleri posi ọfẹ, gbọgan igbalode ọfe, awọn agboku atawọn nnkan mii fun isinku Mohbad lẹẹkeji.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 yii ni Mohbad jade laye niluu Eko.
Lẹyin iku rẹ, oniruru họwuhọwu lo waye lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si bere fun idajọ ododo lori iku ọhun.
Ṣaaju ni awọn mọlẹbi Mohbad ti kọkọ sin oku rẹ lọjọ keji to dagbere faye amọ ọlọpaa pada wu oku ọhun fun iwadii.
Ni bayii ti wọn n mura isinku rẹ lẹẹkeji, awọn oṣere tiata meji, Iyabo Ojo ati Tonto Dikeh ti ṣabẹwo si ile itaja ti wọn ti n ta ohun elo isinku niluu Eko lati mọ awọn ohun ti wọn yoo nilo fun eto isinku naa.

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
"Ọga agba ileeṣẹ naa fun wa ni posi ọfẹ, gbọgan igbalejo ọfẹ, ẹdinwo fun iboji oku, awọn agboku, ẹlẹsin..."
Nigba to sọrọ loju opo Instagram rẹ, Iyabo Ojo ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ naa lo pese pupọ ninu awọn ohun ti wọn yoo nilo fun eto isinku ọhun.
O ni “A lọ si Ebony Vault to wa ni Ikoyi fun imurasilẹ eto isinku to yẹ Mohbad.”
“Ọga agba ileeṣẹ naa fun wa ni posi ọfẹ, gbọgan igbalejo ọfẹ, ẹdinwo fun iboji oku, awọn agboku, ẹlẹsin.... Mohbad gbọdọ gba idajọ ododo”
Ọpọ awọn araalu lo ti n kan sara si ọkunrin naa fun igbesẹ ọhun, ti awọn mii si n fi ẹmi imoore han si awon oṣere tiata naa.












