Ṣé ríró òkú tàbí 'Autopsy' ló dára jùlọ láti tú àṣírí òkú tí wọn bá pa?

Oku ti wọn di silẹ

Ni kete ti wọn tufọ iku akọrin takansufe nni, Ilerioluwa Aloba, ti awọn eeyan mọ si Mohbad, ọpọ ọmọ Naijiria ati nilẹ okeere lo n tara poro lori iku ọmọdekunrin naa.

Awọn eeyan naa lo n gbarata pe ki lo le da ẹmi ọdunrin naa, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn pere legbodo lọsan gangan aye rẹ.

Koda, wọn n naka aleebu si awọn eeyan kan pe awọn lo wa nidi iku akọrin naa, ti wọn si n gba awọn obi Mohbad nimọran lati gbẹsan iku ọmọ wọn.

Lara ọna tawọn eeyan si n [pariwo pe wọn fi le gbẹsan iku akọrin naa ni nipa riro oku rẹ nilana asa abalaye.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi tọ awọn agba lọ lati beere pe ki ni itumọ oku riro, bawo ni wọn ti n se e, awọn eroja wo ni wọn n lo ati ipa ti igbesẹ riro oku yii le ni lori mọlẹbi oku ati oku gan.

Bakan naa la tun fẹ mọ boya o seese lati ro oku Mohbad lẹyin ti wọn ti sin-in tẹlẹ, ki wọn to hu oku rẹ jade pada fun ayẹwo, taa mọ si Autopsy?

Tun wẹ, se oku ti wọn ti la ikun ati awọn ẹya ara rẹ kan fun ayẹwo, se o seese lati ro pada lasiko ti wọn ba fẹ sin?

Ọba Ogboni igba iwasẹ, Adeyinka Sangolade Arifanlajogun

Ki ni itumọ oku riro?

Nigba to n salaye ohun ti asa riro oku jẹ fun BBC Yoruba, Ọba Adeyinka Sangolade Arifanlajogun tii se Ọba Ogboni igba iwasẹ fun gbogbo agbaye, sọ pe itumọ oku riro ki ẹlẹda oku yẹn mase sun rara.

“Ohun ti eyi tumọ si ni pe ki Ẹlẹda oku naa lọ ja nitori wọn fuura pe kii se iku Ọlọrun lo pa a, to jẹ pe awn eeyan kan lo seku pa a.

Awọn ẹbi oku yii, ti wọn ba si fẹ mọ iru iku to pa a, yoo gbe igbesẹ lati ro oku rẹ, ki wọn to sin-in.

Ti awọn to ba pa oku, ko ba jẹwọ pe awọn lawọn pa a, wọn yoo ro oku naa nigba iwasẹ, ti ẹlẹda oku naa yoo si lọ ba awọn to pa a ja, titi ti wọn yoo fi jẹwọ lojutaye pe awọn ni awọn pa a.”

Ọba Ogboni wa yan pe ko si ayederu rara nidi riro oku nitori bi wọn se n ro oku nigba iwasẹ to fi n jẹ fun wọn, ilana naa si ni wọn n lo lati ro oku lode oni.

Ki ni iyatọ laarin Autopsy ati oku riro?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọba Ogboni igba iwasẹ tẹsiwaju pe nigba iwasẹ, ti ko si Autopsy tabi iwadi dokita, ilana riro oku ni awọn baba wa fi n mọ boya iku eeyan lọwọ awọn kan ninu tabi pe wọn pa a ni.

O fikun pe lati igba ti ilana ayẹwo oku, ti wn n pe ni Autopsy ti jade, ni ko jẹ ki iran Yoruba kọbi ara si oku riro mọ.

Sugbọn o salaye pe Autopsy ka maa sọ iru iku to pa oku lẹyin iwadi, ohun to jẹ, to fi ku tabi ọna to gba ku boya wọn yin ni ọrun pa ni tabi pe wọn lu u pa.

Ọba Ogboni ni ilana oku riro, funra oku ni yoo maa lọ le ẹni to pa a, lẹyin ti wọn ba ro iru oku bẹẹ tan.

O ni ẹni to sisẹ ibi naa ko si ni ri ojutu aye rẹ mọ titi ti yoo fi bẹrẹ si jẹwọ pe oun lo pa oku ọhun.

“Bi wọn ba ti ro oku tan, funra oku yẹn ni yoo maa le awọn to pa a kiri, ko ni jẹ ki wọn ni isinmi, bi wọn n sun, bi wọn n jẹun, bi wọn n wẹ, bi wọn n rin lọ.

Se ni oku naa yoo maa yọ si awọn to pa a pe ki wọn tete lọ jẹwọ fun araye pe awọn lo pa oun.

Awọn eeyan naa ko ni nisisnmi titi ti wọn yoo fi tu asiri ara wọn, ti wọn ba si ti kede pe awọn lo pa oku naa, ko si idarijin fun wọn.

Iku ni ere ẹsẹ tiwọn naa, wọn ko baa pe ogun tabi igba, ti wọn lọwọ ninu iku ẹni ti wọn ba ro .”

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

“To ba jẹ eeyan lo pa Mohbad, ti wọn si ro oku rẹ, funra ẹni to pa a ni yoo kà”

Ọba Arifanlajogun wa fi ọwọ gbaya pe to ba jẹ pe eeyan kan lo pa Mohbad, ti wọn si ro oku rẹ, funra onitọhun ni yoo maa kigbe kiri pe oun ni oun pa a.

“O seese ko jẹ pe ẹni ti ẹnu n kun pe o pa Mohbad, kọ lo pa a, o le jẹ awọn eeyan miran lo pa a.

Paapaa awọn oogun oloro ti wọn n ko jade fawọn ọmọ wa, to ba jẹ pe ohun lo pa a, ko si nnkan to fẹ sẹlẹ.

Nigba mii, ẹnu maa n ko ba eeyan, ti yoo sọ awọn nnkan ti ko yẹ ko sọ, eyi to le mu kawọn eeyan lero pe oun lo pa oku to ba ku.

Amọ to ba jẹ pe awọn eeyan lọwọ ninu iku rẹ, ohun ti wọn fi ro oku Mohbad yoo maa le wọn kaakiri ni ti wọn ba ti ro oku yẹn.”

Ọba Arifanlajogun ni ko si iru agbo ti wọn le fi wẹ awọn to ba pa oku ti wọn ro, tabi oogun isọra yoowu ti wọn ba se fun wọn, to le sediwọ fun oku naa lati ja.

O ni ẹmi oku naa ni yoo maa le wọn kiri titi ti wọn yoo fi jẹwọ, ẹmi oku yẹn funra rẹ si ni yoo pa wọn.

Ọba Ogboni ni oku riro maa n jẹ ka mọ boya lootọ ni wọn pa ẹni to ku naa tabi bẹẹ kọ.

Ipa wo ni igbesẹ riro oku maa n ni lori oku ati awọn to baa ro, ṣe o le lẹ́yìn tabi ki oku naa má ri ọrun wọ?

Nigba to n salaye lori ipa to seese ki igbesẹ riro oku ni lori oku ati awọn to ba ro o, Ọba Ogboni igba iwasẹ lagbaye ni ko si ohun to n lẹyin ninu riro oku rara.

“Ko si nnkan to jọ pe riro oku maa n lẹyin fun idile oku tabi oku gan funra rẹ.

Koda, igbesẹ riro oku ko sọ pe ki oku mase ri ọrun wọ amọ kikida awọn eeyan to ba pa a, nikan ni yoo kabamọ igbesẹ riro oku naa.

Se o si seese lati ro oku Mohbad lẹyin ti wọn ti sin-in, ti wọn si hu oku rẹ jade ninu saare, ti wọn si tun la ara rẹ lati se ayẹwo Autopsy?

Iboji ti wọn kọkọ sin Mohbad si, ki wọn to hu sita fun ayẹwo

Oríṣun àwòrán, Others

Se akoko ko ti lọ lori iku Mohbad bayii lati ro oku rẹ?

BBC Yoruba wa bi Ọba Ogboni igba iwasẹ pe se akoko ti lọ lati ro oku Mohbad bayii?

Idi ni pe wọn ti kọkọ sin oku naa, lẹyin eyi ni wọn hu u jade fun ayẹwo iwadi Autopsy, ti wọn yoo si la awọn ẹya ara rẹ kan fun ayẹwo naa.

A tun fẹ mọ pe se o si seese nilana asa ilẹ Yoruba lati ro oku Mohbad ti wọn ti sin tẹlẹ, tabi oku ti wọn ti la ara rẹ fun ilana igbalode lati mọ iru iku to pa oku kan?

Ninu alaye rẹ, Ọba Arifanlajogun ni eyi seese, koda, asiko to seese gan ree.

“Ti wọn ba ni ki n mu ọkan ninu riro oku ati Autopsy, riro oku ni maa mu.

Idi ni pe aye di aye ọlaju ni Autopsy de, laye atijọ, ilan a oku riro la n lo.

Agbara awọn baba wa si wa nbẹ, ko si dara ka ko awọn agbara awọn baba wa danu.

“Mo setan lati pese awọn eroja ti wọn yoo fi ro oku Mohbad, ti wọn ba gba wa laaye”

Ọba Arifanlajogun wa salaye fun BBC pe ti awọn ẹbi Mohbad ba setan lati ro oku ọmọ wọn, oun setan lati se atilẹyin fun wọn.

“Mo setan lati pese awọn eroja ti wọn nilo lati ro oku Mohbad ti wọn ba fẹ ro oku ọmọ naa.”

Nigba ti BBC Yoruba si beere pe ki ni awọn eroja ti wọn n lo nilẹ Yoruba lati ro oku, Ọba Ogboni ni oun ko ni sọ fun wa.

“A kii sọ awọn eroja ta n lo sita, ohun to n ba aye jẹ niyẹn.

A maa n ri awọn eeyan kan ti wọn yoo maa sa oogun lori ayelujara, paapaa Facebook, eyi ko dara to.”

Ọba Ogboni agbaye wa rọ awọn ọmọ Yoruba lati tọju asa adayeba wọn nitori ọmọ to ba sọ ile nu,m o so apo iya kọ ni.