Àwàdà la fi mọ̀ mí àmọ́ àwọn èèyàn ń pè mí fún àdúrà gbígbà ju àwàdà lọ - Wolii Arole
Ti a ba n sọrọ nipa awọn adẹrinposonu tabi alawada lori ayelujara, ọdu ni Bayegun Oluwatoyin, kii si se aimọ fun oloko.
Ojo si ti n pa igun rẹ bọ, ọjọ ti pẹ nidi awada sise lori ayelujara, bakan naa lo maa n kopa ninu ere sinima, to si tun maa n sisẹ adari eto nibi ayẹyẹ.
Ni ọpọ igba, alawada lasan to maa n se bii Wolii Ọọrun ni ọkunrin naa, to si maa n fi awada rẹ sin awọn Wolii, Pasitọ atawọn ojisẹ Ọlọrun miran jẹ.
Idi ree ti ọpọ eeyan se mọ si Wolii Arole lori ayelujara, ti orukọ rẹ naa si di gbajugbaja kaakiri agbaye.

"Ohun ti adura n se, Kọmẹdi ko lee se, mejeeji yatọ sira wọn"
Amọ iyalẹnu lo jẹ fun wa nigba ti Wolii Arole sọ fun BBC Yoruba, ninu ifọrọwanilẹnuwo ta se fun pe ọpọn isẹ awada ti oun n se ti sun siwaju.
Wolii Arole ni oun ti mu adura gbigba mọ isẹ naa, koda, o ti n fun oun ni okiki ju isẹ awada lọ.
“Awọn eeyan n pe mi fun adura gbigba ju kọmẹdi lọ, inu mi dun ohun ti adura n se, Kọmẹdi ko le se, isẹ mejeeji yatọ sira wọn.
Adura ni mo n gba fawọn eeyan laarọ, lọsan ati lalẹ, bi adura naa se n sisẹ fun wọn, naa lo n sisẹ fun emi naa.
Adura n gba, ẹri n tẹle, isẹ iyanu ko si gbẹyin, mo ri ogo lo, ọkan mi si balẹ.”
Wolii Arole sọ siwaju wipe isẹ kọmẹdi ati adura gbigba naa ti gbe oun lọ kaakiri agbaye.
“Ọlọrun ko jẹ ki n sisẹ lasan, Ọlọrun jẹ ki n ri ere lori rẹ.”
Arole wa fi idunnu rẹ han pe ọpọ eeyan lo n ni iwuri pẹlu ohun ti oun n se naa, ti wọn si maa n pe oun lati sọ fun oun.

Oríṣun àwòrán, Woli Arole
“Ti Ọlọrun ba ni ki n da ori oke adura tabi sọọsi silẹ, maa dá a sílẹ̀”
Nigba to n sọ igbesẹ to kan to fẹ se, Wolii Arole ni oun ko le da ohunkohun se lẹyin Ọlọrun to n lo oun fun isẹ rẹ.
O ni ohunkohun ti Ọlọrun ba fẹ ki oun se, tabi igbesẹ ti Ọlọrun ba fi ọwọ si, ni oun maa se.
“Ọlọrun n ti ara mi sisẹ ami ati isẹ iyanu, Mo ni imisiẹmi mimọ, ti Ọlọrun si n ba mi sọrọ.
Ohun ti Ọlọrun ba ni ki n se lọjọ iwaju, maa se e.






