Wo ẹ̀sùn mẹ́rìnlá tí ilé aṣòfin Ondo fẹ́ fi yọ igbákejì gómìnà, Aiyedatiwa nípò

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Àtẹ̀jáde kan láti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo ní ẹ̀sùn mẹ́rìnlá ló wà lọ́rùn Aiyedatiwa, èyí tó ṣokùnfà ìdí tí àwọn fẹ́ fi yọ nípò.
Ẹ ó rántí pé Aiyedatiwa ló ti wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà fún bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn láti ìgbà tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Rotimi Akeredolu ti gba ìsinmi láti lọ fún ìtọ́jú nílẹ̀ òkèrè.
Láti ìgbà tí Akeredolu ti padá sí Nàìjíríà ni nǹkan kò ti dánmọ́rán láàárín òun àti Aiyedatiwa.
Èyí náà ló sì ṣokùnfà bí ilé aṣòfin ṣe gbèrò láti yọ Aiyedatiwa nípò gẹ́gẹ́ bí igbákejì gómìnà tí ìgbésẹ̀ náà sì ti ń fa onírúurú awuyewuye.
Àtẹ̀jáde tí ilé aṣòfin náà fi síta ní àwọn ìwà àṣemáṣe mẹ́rìnlá ni àwọn fẹ́ torí rẹ̀ yọ Aiyedatiwa nípò.

Oríṣun àwòrán, Ondo House of Assembly
Àwọn ẹ̀sùn náà nìyí:
- Aiyedatiwa gbé àwọn àtẹ̀jáde kan jáde, tó sì tún ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níbi tó ti parọ́ nípa ipò ìlera gómìnà Akeredolu èyí tó lòdì sí ìwé òfin Nàìjíríà.
- Pé Aiyedatiwa gbìyànjú láti dá wàhálà òṣèlú sílẹ̀, tó sì ń ṣíṣe tako gómìnà Akeredolu nípa pípè fún yíyọ Akeredolu nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà nígbà tó wà ní ìsinmi láti lọ gba ìtọ́jú lórí ìlera rẹ̀.
- Pé Aiyedatiwa gẹ́gẹ́ bí igbákejì gómìnà pín ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba Ondo lójúnà àti yọ gómìnà Akeredolu nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
- Aiyedatiwa ń ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìlú tó gbé dání gẹ́gẹ́ bí igbákejì gómìnà ní èyí tó tàbùkù ọ́fíìsì rẹ̀.
- Gbígba owó tó lè ní mílíọ̀nù méje náírà lápò owó ìlú láti fi ṣe ìrìnàjò nínú oṣù Kẹfà àti oṣù Keje ọdún ṣùgbọ́n tí kò rin ìrìnàjò kankan.
- Lílo owó tó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún náírà láti fi táyà àti bátìrì sí àwọn ọkọ̀ ọ́fíìsì rẹ̀ lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù Kìíní ọdún 2023. Wọ́n ní owó náà pọ̀ púpọ̀ jù àti pé igbákejì náà gbèrò láti kó owó ìlú sí àpò ara rẹ̀.
- Aiyedatiwa gba owó tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà nínú oṣù Kẹfà àti oṣù Kẹjọ ọdún 2023 láti fi tún ọkọ̀ SUV ijoba ṣe àmọ́ tí kò sí àrídájú pé wọ́n ṣe ọkọ̀ náà.
- Aiyedatiwa gba owó tó lé ní mílíọ̀nù méjì náírà láti fi ṣe ìrìnàjò lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ Ilaje àti Ese-Odo láàárín ọjọ́ Kẹwàá sí ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún 2023.
- Pé Aiyedatiwa lu ìyàwó rẹ̀, Oluwaseun Aiyedatiwa ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Kẹfà ọdún 2023 èyí tó lòdì sí òfin títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ ìpínlẹ̀ Ondo tọdún 2020.
- Aiyedatiwa ṣe owó ₦500,000,000.00 tó jẹ́ owó tó wà fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kúmọkùmọ ní èyí tó lòdì sí òfin.
- Pé Aiyedatiwa lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú Kọmíṣọ́nà fún ìjọba ìbílẹ̀ àti ọ̀rọ̀ oyè ní ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí, Akin Sowore láti máa gba owó lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ jẹ oyè ní ìpínlẹ̀ náà èyí tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ₦250,000,000.00.
- Pé Aiyedatiwa ṣe owó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà tí gómìnà Rotimi Akeredolu buwọ́lù fún àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ náà kúmọkùmọ ní ọjọ́ Kejì oṣù Kẹta ọdún 2022.
- Ṣíṣe owó ₦150,000,000 tó wà fún àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ìpínlẹ̀ náà kúmọkùmọ lọ́jọ́ Kejì oṣù Kẹta ọdún 2022.
- Pé Aiyedatiwa lo owó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà tó buwọ́lù fún àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì fún ara rẹ̀ ní èyí tó lòdì sí òfin.
Gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí ni ilé aṣòfin ní àwọn ń ṣe ìwádìí Aiyedatiwa lé lórí tí àwọn fẹ́ fi yọ nípò.

Oríṣun àwòrán, Ondo state House of Assembly
'Àjọ̀dún ìwọ́de' lóníran àn ran wáyé l'Ondo lórí yíyọ igbákejì gómìnà, Lucky Aiyedatiwa nípò

Oríṣun àwòrán, Facebook
Oriṣiriṣi ẹgbẹ lo ti bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan ni ilu Akure tako igbesẹ yiyọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa.
Lọjọ Iṣẹgun ni awọn ero kan labẹ ẹgbẹ ọmọbibi agbegbe Ilajẹ labẹ aṣia, Ilaje World Congress yabo ile aṣofin ipinlẹ naa ti wọn si nkọ orin loriṣiriṣi lati sọ fun awọn aṣofin naa pe ki wọn jawọ ninu igbesẹ ati yọ igbakeji gomina naa.
Ẹniọwọ Ola Judah, to sọrọ lorukọ awọn olufẹhonuhan naa wi pe awọn wa lati jẹ ki gbogbo aye o mọ pe igbesẹ tawọn aṣofin naa n gbe ko boju mu to.
Judah ni lara awọn anfani ti Ilaje mu ba Ondo ni epo rọbi sibẹ ko si anfani ti eyi mu ba awọn olugbe agbegbe naa.
“O le logun ọdun taa ti ni ina mọnamọna kẹyin nilẹ Ilajẹ amọ awọn aṣofin yii ko ri nkan ṣe sii.
“Ọpọ ilu ni Ilaje bii Aiyetoro ati Awoye ni omi ti gbe lọ ti ile aṣofin yii ko ri ohunkohun ṣe sii.
“O jẹ ohun iyalẹnu ati ibanujẹ pe ọrọ akọkọ ti ile aṣofin yii ri sọ nipa Ilajẹ ni iyọnipo ọmọ wa to jẹ igbakeji gomina.
“Igba akọkọ niyii ti ọmọ Ilaje yoo de ipo giga kankan nipinlẹ Ondo, ki lo waa de to jẹ iyọnipo lo kan?
'Ibo ajumọ lo ọlọdun mẹrin la di fun Akeredolu ati Ayedatiwa'

“Ibo ọdun mẹrin lawọn araalu di fun gomina Akeredolu ati Aiyedatiwa, niwọn igba ti Akeredolu ba ṣi jẹ gomina, Aiyedatiwa gbọdọ jẹ igbakeji rẹ.”
Ọmọọba Temilade Ogbaro to sọrọ lorukọ awọn obirin to wa ninu iwọde naa wi pe “ọmọ Ilajẹ ni awọn olugbe ipinlẹ Ondo dibo fun bii igbakeji gomina, a ko si nii gba ki wọn yọọ nipo.
“Titi di baa ṣe n sọrọ yii, wọn ko tii sọ ohun kan pato ti Aiyedatiwa ṣe fun wa.
“To ba jẹ pe o ṣẹ wọn ni, ki wọn wi fun wa ka lee bẹ wọn ki wọn ṣe idariji fun-un.”
Bakan naa ni ẹgbẹ “Atunluse Initiative” naa ṣe iwọde tiwọn.
Ọtunba Akinsola Akinbobola to sọrọ lorukọ ẹgbẹ naa wi pe o jẹ ohun ti ko boju mu ki gomina Akeredolu tun fẹẹ gbe igbesẹ to gbe pẹlu igbakeji to lo ni saa akọkọ.
“Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Aiyedatiwa ni wọn ko lee fidi rẹ mulẹ ninu iwe ti wọn fi lede. Koda, awọn ẹsun kan ti wọn fi kan-an lori ẹrọ ayelujara ni wọn yọ kuro ninu iwe naa nitori pe ko lẹsẹ nlẹ.
“Awọn kan lo n lo aarẹ gomina lati fi dari rẹ leyi ti wọn fẹẹ fi da laasigbo silẹ nipinlẹ yi.
“Gomina Akeredolu ni lati tẹti si ohun tawọn araalu n sọ. Igbe aye irọrun lo jẹ wọn logun, kii ṣe idarudapọ tawọn kan n tii lati da silẹ yi.”
Awọn aṣofin tẹlẹ ri lẹgbẹ Apc naa wa nibẹ

Awọn aṣofin tẹlẹ ri nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC naa da si ọrọ ọun.
Abiodun Jerome to sọrọ lorukọ awọn aṣofin tẹlẹ ri naa wi pe awọn nigbagbọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nile aṣofin ipinlẹ naa lo ni ọwọ kan ika ninu ati pe ko dara to ki awọn aṣofin naa gba lati lọwọ ninu igbesẹ bẹẹ.
“O jọwa loju pe ohun ti o yẹ ki ile aṣofin o moju to ni bonkẹlẹ waa di ohun tawọn oniwe iroyin n ṣe atotonu le lori.
“Amọran taa ni fun ile aṣofin naa gẹgẹ bii aṣofin tẹlẹ ri ni ki wọn gbaju mọ ohun to jẹ iṣẹ wọn ti yoo ṣe awọn araalu lanfaani.
“Ida aadoje ninu wọn lo wa nile aṣofin fun igba akọkọ ti wọn ko si tii lo oṣu mẹrin gẹgẹ bii aṣofin leyi to fi yẹ ki wọ farabalẹ ki oju wọn o lee ri imu.”
Iwọde ọun ni awọn kan lara wọn ni yoo tẹsiwaju lọla.
Iléẹjọ́ dá ilé aṣòfin Ondo dúró lórí yíyọ igbákejì gómìnà, Lucky Aiyedatiwa nípò
Ninu idajọ rẹ, adajọ Emeka Nwite fontẹ lu awijare Kayode Adewusi to jẹ agbẹjọro igbakeji gomina ipinlẹ Ondo to bẹbẹ fún idaduro igbesẹ ile aṣofin ọhun.
Adajọ wa pàṣẹ pe gomina Rotimi Akeredolu ko gbọdọ yan igbakeji gomina tuntun, ko sí gbọdọ fi orúkọ kankan ranṣẹ sile aṣofin titi ti igbẹjọ yoo fi waye tan.
Adajọ Nwite pàṣẹ yii lẹyin ti agbẹjọro Adewusi sọ fun ile ẹjọ pe o ṣe pataki ki awọn aṣofin da igbesẹ wọn duro ki igbẹjọ naa le kẹsẹ jari.
Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin NAN ti kọkọ gbe iroyin kan jade pe Ọgbẹni Aiyedatiwa pe ọga ọlọpaa Naijiria ati Gomina Akeredolu lẹjọ.
Awọn mii ti o tun pe lẹjọ ni abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ondo, adajọ agba ipinlẹ Ondo ati gbogbo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lọjọ kokanlelogun oṣu kẹsan an.
Adajọ Nwite tun paṣẹ pe gomina Akeredolu tabi awọn iṣọmọgbe rẹ kankan ko gbọdọ dunkoko mọ Ọgbeni Aiyedatiwa lẹnu iṣẹ rẹ.
Adajọ naa ti sun igbẹjọ sí ọjọ kẹsan an oṣu kẹwaa.
Ẹ gbà mí o, ẹbọ ni wọ́n fi ń lé mi kiri nítorí ìgbésẹ̀ yíyọ igbákejì Gómìnà Ondo- Olórí ilé aṣòfin ké gbàjarè

Ọrọ awuyewuye lori iyọninipo igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo tun ti gba ọna miran yọ pẹlu bi olori ile aṣofin ṣe ke gbajare pe kawọn agbofinro ṣaanu oun tori idunkoko tawọn kan n ṣe si oun pọju.
Olamide Oladiji to jẹ olori ile sọ pe ati oun ati awọn ọmọ ile ni ọkan awọn o balẹ mọ lati igba ti awọn bẹrẹ igbesẹ lati yọ igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa kuro nipo.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Akure lo ke gbajare yi lọjọ Aje.
Gẹgẹ bi o ṣe wi o ni ''lowurọ yi ni mo tun ba ẹbọ tawọn eeyan kan gbe si iwaju ile igbe ti ijọba la kalẹ fun mi''
O ni ile igbe yi to nilo atunṣe jẹ ibi toun ko saba maa lo si.
O ni ipade ẹẹkankan awọn ọmọ ile aṣsofin ipinlẹ lawọn maa n ṣe nibẹ.
''Lowurọ yi ni mo ri ẹbọ ti eeyan kan gbe si iwaju ile yi. Yatọ si eleyi mo ti n gba ipe lori ago tawọn kan fi n dunkoko mọ ẹmi mi ati awọn ọmọ ile aṣofin mii.Idaamu yi pọ lori ẹmi mi''
Aṣofin mẹrindinlọgbọn lo ti buwọlu aba yiyọ igbakeji Gomina nipo
Olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo tun ṣalaye pe awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn lo ti buwọlu aba yiyọ igbakeji Gomina pinlẹ naa, Ọgbẹni Ayedatiwa inipo ati pe ile aṣofin naa yoo ṣẹṣẹ fi iwe to igbakeji Gomina leti ni wi pe igbesẹ fẹ bẹrẹ lati yọ kuro nipo.
Aṣofin Ọlamide Ọladiji ni ọjọ meje ni igbakeji Gomina ni lati fesi si iwe tawọn ba fi ranṣẹ si.
Bakan naa lo ni oun ti fẹjọ sun lọdọ awọn agbofinro ati pe lati igba tawọn ti bẹrẹ igbesẹ lati yọ igbakeji Gomina kuro ni ipo ni gbogbo idunkoko yi ti bẹrẹ.
Ṣe lootọ lawọn aṣofin Ondo gba miliọnu lọwọ Gomina Akeredolu lati yọ igbakeji rẹ?
Nigba to n dahun si ẹsun tawọn kan fi kan an pe oun ati awọn aṣofin ti gba owo miliọnu mẹẹdogun lọwọ Gomina lati yọ igbakeji rẹ ni ipo, Oladiji sọ pe ile aṣofin ti oun n dari rẹ ko le gbabọde.
''Igbakigba ti igbesẹ iyọninipo bayii ba ti n waye lawọn eeyan maa n ro pe ẹka apaṣẹ lo tiwa lati ṣe bẹẹ.''
O ni ''mo fẹ fi to gbogbo aye leti pe a ko gba abẹtẹlẹ kankan lọdọ ẹnikẹni.Iṣẹ wa laa n ṣe gẹgẹ bi asofin''
Igbakeji Gomina ni oun ko ti i ri iwe ifisun kankan lati ọdọ ile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/AKEREDOLU/AIYEDATIWA
Ninu atẹjade kan ti igbakeji Gomina fi sita lesi ti waye lori ọrọ iyọni nipo ti ile fẹ gbe igbesẹ lori rẹ.
Lucky Orimisan Aiyedatiwa lọjọ Aje yi sọ ninu atẹjade pe ko si ootọ ninu ọrọ ti aṣofin kan Olatunji Oshati sọ lori eto Politics Today ileeṣẹ ẹrọ amohunmaworan Channels TV pe wọn ti fi iwe ranṣẹ si oun.
O ni titi di ọjọ Aje tii ṣe ọjọ Karundinlọgbọn oṣu Kẹsan ọdun 2023, ''mi o ti ri iwe kankan gba lati ọdọ ile to ni ki n wa rojọ lori iwa asemaṣe ti ile fi kan mi''
O ni o jẹ ohun to kan ni lominu pe agbẹnusọ ile yoo lọ sori ileeṣẹ amohunmaworan lati kede ọrọ ti ko si ẹri lati fi jẹri rẹ.












