Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Eeyan to ba ni awọn ara ijọun gọ, o ti bu baba nla rẹ mọ.

Ni igba atijọ, oniruuru ọna ni Yoruba n gba se akoso ilu, lati jẹ ki iwa ọdaran dinku, ti wọn si n se idajọ ara wọn.

Lara ilana fun afọmọ ilu naa ni amulo awọn orisa ilẹ Yoruba fun idajọ ẹlẹsẹ, inu wọn si ni orisa Ayelala wa.

Orisa yii si lo maa n se idajọ oju ẹsẹ fun awọn eeyan to ba huwa ibajẹ lawujọ lai segbe si ẹyin ẹlẹsẹ kankan.

Ọna lati mọ nipa orisa onidajọ oju ẹsẹ yii lo gbe BBC Yoruba lọ silu Okiti Pupa nibi ti ojubọ orisa Ayelala ti rinlẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Onimọlẹ Ayelala, Oloye Araye Holo salaye ọna ti Ayelala maa n gba mu ọdaran ati oniruuru iya to fi n jẹ wọn.

Holo ni Oluwẹri obinrin ni orisa Ayelala, idi si ree to se maa n pọn omi sinu ẹlẹsẹ.

O fikun pe awọn ẹlẹsin maa n tako orisa naa loju aye amọ wọn maa n gba ẹyin wa sọdọ rẹ fun iranlọwọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni awọn eeyan kan tun jẹri si bi agbara orisa Ayelala ti pọ to atawọn sna to maa n gba se idajọ ẹlẹsẹ laisegbe sibikan.