Alaafin: Ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ wa ní èdé àti àṣà Yorùbá

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Ọdun Sango , tii se ọdun isẹnbaye to maa n waye lọdọọdun, eyi ti Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta maa n se agbatẹru rẹ, ti waye lọdun yii, to si ti lọ pẹlu.

Sugbọn awọn ọrọ ti Alaafin sọ lasiko ayẹyẹ ọdun Sango naa si n ja rain-rain nilẹ.

Ọba Adeyẹmi, lasiko to n sọrọ salaye pe awọn alalẹ ati iran to n bọ lọjọ iwaju ko ni forijin oun, ti oun ba kọ lati maa se ajọdun Sango lọdọọdun, gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọba to ti jẹ ri nilu Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaafin wa kesi awọn ọba alaye yoku nilẹ Yoruba lati maa gbe awọn asa ajogunba wa, ede, ati ise Yoruba larugẹ, ni gbogbo ilu ti wọn ba jọba le lori.

Awọn onisango n bọ Sango

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Bakan naa ni Ọba Adeyẹmi tun rọ awọn ọmọ Kaarọ Oojire lati maa fi asa ati ise wa kọ awọn ọmọ wa nitori orisa ti a ko ba fi oju ọmọde mọ, ko ni pẹ parun.

"Iyatọ nla wa laarin ẹsin ati asa, ẹ mase jẹ ki oju ti yin lati maa wọ awọn asọ ajogunba Yoruba, koda asa wa gan gbọdọ fara han ninu awọn ounjẹ ta n jẹ"

Oriade naa wa daba pe kawọn eeyan maa kọ awọn ogo wẹkrẹ wa ni ede abinibi ninu ile ati nile iwe.