Dele Momodu: Gbogbo aáyan àwa Nadeco láti tú Abiola sílẹ̀ ni kò hàn sí Kọla Abiọla

Àkọlé fídíò, Dele Momodu: Gbogbo aáyan àwa Nadeco láti tú Abiola sílẹ̀ ni kò hàn sí Kọla Abiọla

Oloye Dele Momodu, tii se ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Nadeco to sa kuro lorilẹede yii lasiko ti oloogbe Sani Abacha gbe Oloye MKO Abiọla ju sẹwọn, ti ba BBC Yoruba sọrọ.

Dele Momodu. ẹni to tako ọpọ ọrọ ti Kọla Abiọla sọ ninu ifọrọwerọ kan lati tako Oloye Bọla Tinubu pe o dalẹ MKO Abiọla, wa sisọ loju rẹ pe oun ati Tinubu jọ sisẹ pọ bii ọmọ ẹgbẹ Nadeco nigba naa, ti awọn si ja fitafita lati gbe Abiọla jade ni ahamọ to wa.

Momodu fikun pe, asiko kan tiẹ wa ti awọn mejeeji dijọ joko sepade pẹlu awọn ologun ọmọ ilẹ Germany ti wọn fẹ fi owo gba, lati wa gbe Abiọla kuro lẹwọn, ti Tinubu si se gudugudu meje ati ya ya ya mẹfa lati yọ Abiọla kuro nigbekun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe lara awọn eeyan meji si mẹta ti oun mọ, to n nawo fi gbọ bukata ẹgbẹ to n ja fun ifẹsẹmulẹ ijọba alagbada lorilẹede Naijiria (Nadeco) nigba naa, ni Bọla Tinubu wa.

Momodu wa gba gbogbo ọmọ Naijiria nimọran pe, ohun to ja ju bayii ni lati fọwọ sowọpọ fi gbe orilẹede Naijiria de ibi giga nitori ohun atijọ ti kọja lọ.