Adebayo Shittu: Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ń kò jẹ mínísítà lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, @HMAdebayoShittu
Minisita tẹlẹri feto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, Adebayo Shittu ti ṣe'mọ bi aarẹ Buhari ko ṣe yan sipo Minisita.
Ọgbẹni Shittu to fi ọrọ yii lede ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ akoroyinjọ ilẹ wa, NANS, nilu Abuja wa fikun pe, oun ti gba ọrọ naa gẹgẹ bi akọọlẹ Ọlọrun nilana ẹsin musulumi.
Ninu orukọ awọn minisita tuntun ti Buhari yan sipo, eeyan mẹrinla to ti ṣiṣẹ tẹlẹ bii minisitani saa akọkọ, lorukọ wọn wa ninu rẹ, amọ ti orukọ Shittu ko si lara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Makinde, jọ̀ọ́ kéde Aug 20 ọdọọdún bíi ọjọ́ ìsinmi fún ìṣẹ̀ṣe - Àwọn oníṣẹ̀ṣe Ọyọ
- Khafi jẹ̀bùn ọkọ̀ ₦7.6m lórí ètò BBNaija torí pó sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Nàíjíríà
- Bí mo ṣe dúró ti Toyin nílé ìgbẹ̀bí jẹ́ kí ń mọ̀ pé ó yẹ kí ọkùnrin máa bọ aya wọn - ọkọ Toyin Abraham
- Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
Bakanna la ri minisita obinrin meje, ninu awọn mejidinlogun to jẹ minisita tẹlẹri kuna lati ri ipo bi ti Shittu.
''Lootọ ni pe mo fi ọkan si pe wọn yoo yan mi sipo pada ṣugbọn nigba ti ọrọ ko ri bẹẹ, ko gba mi ni iṣẹju marun un lati gba wi pe akọsilẹ ni ati pe bi Ọlọrun ti ṣe fẹ ẹ ni yẹn''
O fi kun ọrọ rẹ pe ''Mo si ti ri ohun to tu mi ninu latara ẹsẹ Kurani, nibi ti Ọlọrun ti ṣe adehun pe oun to n bọ lọna, lati fun ọ ni ohun to dara ju eleyi to wa lọwọ rẹ bayi lọ''

Oríṣun àwòrán, @HMAdebayoShittu
Nigba to n sọrọ lori ohun ti yoo wa maa ṣe bayii lẹyin to kuna lati dipo minisita mu, ọgbẹni Shittu sọ pe oun yoo pada si idi iṣẹ amofin eleyi toun ti n ṣe saaju oṣelu.
Bi a ko ba gbagbe, ọmọ bibi ipinlẹ Oyo naa kuna lati ri tikẹẹti gba, eyi ti yoo fun laanfaani lati ṣoju ẹgbẹ APC ninu idibo Gomina to kọja nipinlẹ Oyo.
- Ẹ̀rù àti oríkunkun ló mú kíjọba máa fi ọlọ́pàá, ológun halẹ̀ mọ́ aráàlú - Ṣoyinka
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
Idi ni pe ẹgbẹ APC ja Shittu kulẹ tori pe ko kopa ninu eto agunbanirọ ọlọdun kan, eleyi ti a mọ si NYSC.












