SERAP: Ọ̀rọ̀ àwọn alájẹbánu ti kúrò lọ́rọ̀ yàrá, ó ti di ọ̀rọ̀ gbangba

Oríṣun àwòrán, @SERAPNigeria
Gbogbo aye lo mọ pe ọrọ iwa ijẹkujẹ jẹ ohun kan to ti ba orukọ Naijiria jẹ nile ati loke okun fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Bẹẹ ni ọkan o jọkan akitiyan lawọn ijọba gbogbo ti gbe lori rẹ, ṣugbọn kaka ko san lara iya ajẹ, n ṣe lo tun n fi gbogbo ọmọ rẹ bi obinrin, ni ọrọ naa n jẹ.
Eyi lo wa mu ki ajọ kan to n lepa igbayegbadun araalu ati igbogun ti iwa ijẹkujẹ lawujọ, SERAP, ti ke sijọba apapọ lati gbe iwe orukọ awọn alajẹbanu sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Makinde, jọ̀ọ́ kéde Aug 20 ọdọọdún bíi ọjọ́ ìsinmi fún ìṣẹ̀ṣe - Àwọn oníṣẹ̀ṣe Ọyọ
- Khafi jẹ̀bùn ọkọ̀ ₦7.6m lórí ètò BBNaija torí pó sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Nàíjíríà
- Bí mo ṣe dúró ti Toyin nílé ìgbẹ̀bí jẹ́ kí ń mọ̀ pé ó yẹ kí ọkùnrin máa bọ aya wọn - ọkọ Toyin Abraham
- Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
SERAP ni iwe naa ni yoo ṣafihan orukọ awọn gomina ipinlẹ atawọn eekan ijọba miran, ti ile ẹjọ ti da lẹbi fun ẹsun ikowojẹ, bẹrẹ lati ọdun 1999.
Ninu lẹta kan ti SERAP kọ si agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami, lo ti pe ipe yii.
Ajọ SERAP tun rọ agbẹjọro agba ni Naijiria lati ri pe gbogbo orukọ to yẹ ko wa ninu iwe iforukọsilẹ naa lo wa nibẹ fun anfani araalu.
O ni eyi yoo jẹ ki wọn mọ ewolewo laarin awọn gomina ati awọn eekan ti ọbẹ ofin ti ba ni idi fun iwa ijẹkujẹ.
- Ẹ̀rù àti oríkunkun ló mú kíjọba máa fi ọlọ́pàá, ológun halẹ̀ mọ́ aráàlú - Ṣoyinka
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
SERAP ni ko yẹ ko si ọrọ a n ṣe ọrọ orukọ awọn akowolujẹ ni awo mọ, nitori o ti de gbangba kii ṣe agbekọrọ yara gbọ mọ.
O ni orilẹede Naijiria lee wo awokọṣe ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, to kede orukọ awọn afunrasi ẹsun ilunijibiti lorilẹede naa, nipa gbigbe igbesẹ bẹẹ ni kiakia.























