Oluwo: Èyí ni ohun tí wọ́n máà ń ṣe sí òkú ọba tó bá wàjà ní ilẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, mperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1/facebook
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ke si awọn onisegun ibilẹ at’awọn oniṣẹṣe ni ilẹ Yoruba lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ iwadii kun iṣẹ isegun ibilẹ leyi ti yoo le ba igba mu.
Oluwo Abdulrasheed Akanbi sọ eyininu fọnran kan to jade to ti n ba awoneeyan kan sọrọ.
O ni asiko ti to fun awọn “babalawo” lati bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ abẹ fun itọju alaisan.
“Ẹ lọ maa fi awọn oogun yin ṣe bi awon ogun oyinbo, bi oogun ori fifọ. Ẹ lọ kọ nipa iṣẹ abẹ.
“A ko tii ri iṣẹ abẹ ninu babalawo ati oniṣegun ti ẹ n ṣe. ẹ gbiyanju lati tubọ tẹsiwaju “

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1/facebook
Bakan naa ni Oluwo ti ilu Iwo tun sọ oko ọrọ si awọn ‘Babalawo ‘ to n ṣe ogun owo pe “owo ti babanla yin o le ri” ni wọn n fẹ ṣe ogun rẹ fun awọn eeyan.
O ni oyinbo lo mu owo ti wọn n ṣe oogun rẹ.
Amọsa awọn itan isedalẹ ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agba iwasẹ ni ilẹ Yoruba ti n na owo ẹyọ fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
O tẹsiwaju lati sọ wi pe ko si ogun owo kankan ju ki eniyan tẹpa mọ iṣẹ rẹ lọ.
O fi kun un pe aifẹ ṣiṣẹ lo n mu ki ọpọ maa lọ si idi iṣẹ awo “lati le pa irọ fun awọn eeyan ki wọn sinsọ pe ki wọn wa ṣe oogun owo”.
Awọn alawo lo maa n ṣi ọpọ awọn ọba lọna -Oluwo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Nigba to n sọrọ nipa awọn ọba ati ajọṣepọ wọn pẹlu iṣẹṣe, Ọba Abdulrasheed ṣalaye pe ọpọ awọn ọba ni ilẹ Yoruba loni lo jẹ wi pe awọn alawo lo n ṣi wọn lọna.
“Awọn babalawo yẹn ni wọn n ṣi awọn ọba yẹn lọna o. Awọn ni wọn n ko wọn sininu ẹgbẹ ti ko dara.”
O fi kun un pe wẹlẹwẹlẹ ni wọn maa nnge ẹran ara awọn ọba bẹẹ lẹyin iku wọn.
“Awọn babalawo ati oniṣegun yẹn naa lo jẹ wi pe wọn maa n ko yin sinu nnkan to jẹ wi pe ti ẹ ba ku tan wọn o ge yin si wẹwẹ ... wọn o fi ọ ranṣẹ kaakiri.”













