Njẹ́ ẹ̀ mọ̀ pé kò sí ojúlé kan ní Ogbomoso tí kò ní ẹbi ní Ghana?
Lati ọdunmọdun ni iroyin ti n lọ kaakiri nipa ajọṣepọ to wa laarin awọn eniyan ilu Ogbomoso nipinlẹ Oyo, ati awọn eniyan orilẹ-ede Ghana.
Ti ẹ ba de Ogbomoso, ẹ ko nii rin jina rara tẹ o fi pade ọni to jẹ ọmọ orilẹ-ede ghana.
Bakan naa ni nnkan ri ni Ghana, niṣe ni awọn eeyan to jẹ ọmọ Ogbomoso, ẹya Yoruba, pọ nibẹ.
O ṣe e ṣe ki eeyan ronu pe eyi ribẹ nitori bi ẹda eniyan ṣe n fi ibi kan silẹ lọ ọ gbe ni ibomiran.
Ajọṣepọ Ghana pẹlu Ogbomoso kọja eyi.
Ti ẹ ba de Ogbomoso lonii, awọn ounjẹ ti wọn n jẹ ni Ghana bii Dokunnu, Banku, Iyan olomi, ati bẹẹbẹẹ lọ, wọpọ bi igba ti ẹ fẹ ẹ ra Amala ati gbẹgiri.
Eyi lo jẹ ki BBC ba awọn eniyan ilu naa sọrọ, to fi mọ awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana paapaa lori ibaṣepọ yii.
Awọn ti a ba sọrọ fi ya wa pe, ko si ojule kan niluu Ogbomoso, ti ko si ẹnikan to pada sile lẹyin to ti gbe ni Ghana.
Wọn jẹ ko ye wa pe ẹlomii n gbe ni Ghana, pẹlu ila ilẹ Yoruba lẹẹkẹ rẹ, amọ to n sọ pe ọmọ Ghana ni oun.





