Kí ló fà á tí wọ́n fi ẹ̀sùn níní èròǹgbà láti ṣekúpa Ààrẹ kan àgbà olóṣèlú?

Aworan olori ẹgbẹ oselu alatako Malawi

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọkan ninu agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Malawi ni wọn ti fẹsun kan pe o n gbero lati ṣekupa Aarẹ orilẹede Malawi, Lazarus Chakwere.

Patricia Kaliati, akọwe agba fun ẹgbẹ oṣelu UTM ni awọn agbofinro mu lọsẹ to kọja lori ẹsun pe wọn fura si pe o n gbimọ pọ pẹlu awọn kan lati ṣekupa Aarẹ.

Nigba to n fara han ni ile ẹjọ lọjọ Aje ni olu ilu orilẹede Malawi, Lilongwe, ẹni ọdun metadinlọgọta ọhun ko fọhun ni ile ẹjọ.

Ṣugbọn agbẹjọro rẹ ni oloṣelu naa ko mọ ohunkóhun nipa ẹsun ti wọn fi kan.

Ọpọ awọn oloṣelu lati inu ẹgbẹ oṣelu alatako gbagbọ pe minu Kaliati ni ọwọ oselu ninu.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu UTM ni wọn duro siwaju ile ẹjọ ti wọn si n kọrin ọtẹ ṣaaju Igbẹjọ naa.

Ile ẹjọ ni ki wọn gba baali Kaliati sugbọn ki iwadi tẹsiwaju.

Ẹgbẹ oselu UTM wa ninu ijọba UTM titi wọ oṣu kẹfa nigba ti wọn juwọlẹ nitori iku olori ẹgbẹ, Saulos Chilima, ẹni to jẹ Igbakeji Aarẹ.

O ku ni ẹni ọdun mọkanlelaadọta nigba ti ọkọ baalu rẹ ja ni apa ariwa Malawi.

Kaliati tí fi ara rẹ kalẹ lati rọpo Chilima gẹgẹ bii olori ẹgbẹ pẹlu erongba lati koju Chakwera ninu eto idibo ti yoo waye ni ọdun to n bọ.

Kaliati lo jẹ olukọ ile ẹkọ akakọbẹrẹ kí o tó darapọ mọ oṣelu.