Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán aṣòfin tó fọ́ awakọ̀ tó gbé ọjà lọ fún-un nílé léti

Alex Ikwechegh

Oríṣun àwòrán, Alex Ikwechegh/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí awakọ̀ Bolt kan, Stephen Abuwatseya fi kan ọmọ ilé aṣojúṣòfin kan, Alex Ikwechegh pé ó fọ́ òun létí, ó sì fa aṣọ ya mọ́ òun lára.

Abuwatseya nínú fídíò kan tó wà lórí ayélujára ní lásìkò tí òun lọ gbé ọjà kan tí aṣòfin náà rà lọ fún-un ló fọ́ òun létí tó sì fa aṣọ ya mọ́ òun lára lásìkò tí òun ń bèèrè fún owó òun lọ́wọ́ rẹ̀.

Nínú fídíò náà ni awakọ̀ náà ti ń bèèrè fún owó íṣẹ́ tó ṣe lọ́wọ́ aṣòfin ọ̀hún àmọ́ ó takú pé òun kò ní fún-un ní owó náà nítorí pé ó wu ìwà àbùkù sí òun.

Pẹ̀lú ìbínú ló fi pe ẹni tó ra ọjà lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ló dé tó fi ọjà òun rán ẹni tí kò bọ̀wọ̀ fún òun àti pé òun le mú kí ó parẹ́ ní Nàìjíríà pátápátá tí wọn kò ní ri mọ́ tí nǹkankan kò sí ní ṣẹlẹ̀.

Aṣòfin náà ti awakọ̀ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí ní dìjọ tàkurọ̀sọ tí aṣòfin Ikwechegh sì sún mọ́ awakọ̀ náà, tó sì fọ ní etí.

Abuwatseya fẹ̀sùn kàn Ikwechegh pé ó fọ́ òun létí ní ẹ̀ẹmẹta àmọ́ aṣòfin náà fún lésì pé ẹ̀ẹmèjì ni òun fọ létí, tí òun yóò sì tún fọ ní ìkẹta tó bá mú inú bí òun jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ikwechegh sọ pé ṣe awakọ̀ náà kò mọ bí òun ṣe jẹ́ ni àbí tá lò rò wí pé òun ń bá sọ̀rọ̀.

Bákan náà ló ní kí awakọ̀ náà lọ fi ẹjọ́ sun ẹni tó bá wù ú kódà kó jẹ́ ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà, kò sí nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun àti pé kò lè wá sí ilé òun láti wá tàbùkù òun.

Awakọ̀ náà fèsì padà pé òun kò tàbùkù rẹ̀ pé owó iṣẹ́ tí òun ṣe fun ní òun ń bèèrè, pé kó fún òun lówó òun kí òun le máa bá iṣẹ́ òun lọ.

Nínú fídíò míì tí awakọ̀ fi sórí ayélujára ló ti fẹ̀sùn kan aṣòfin náà pé ó ya aṣọ tí òun wọ̀ àti pé ẹ̀ẹmẹta ní aṣòfin ọ̀hún fọ́ òun létí.

Aṣòfin náà kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ láti alẹ́ ọjọ́ Àìkú tí ìròyìn náà ti gba orí ayélujára.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tẹ́ka ìlú Abuja ní aṣòfin Alex Ikwechegh ti wà ní àhámọ́ àwọn fẹ́sùn pé ó gbá awakọ̀ ọkọ̀ Bolt, Stephen Abuwatseya létí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja, Josephine Adeh fi léde fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Alex Ikwechegh ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá Maitama tí àwọn sì ti ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.

Adeh, nínú àtẹ̀jáde náà, ṣàlàyé pé awakọ̀ Bolt, Stephen Abuwatseya tí Alex Ikwechegh gbá létí ló wá fi ẹja náà sùn ní àga wọn.

Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti kọ́kọ́ fi àtẹ̀jáde síta pé àwọn bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà àfojúdi ni aṣòfin náà hù sí ọ̀fíìsì ọ̀gá ọlọ́pàá pẹ̀lú bí ó ṣe sọ pé òun kí Stephen Abuwatseya pé ọ̀gá ọlọ́pàá kò sí nǹkankan tó máa ṣẹlẹ̀.

Bákan náà ni àtẹ̀jáde náà fi kun pé Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìlú Abuja, Olatunji Disu ti pàṣẹ pé kí ìwádìí tó gbòòrò wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Wọ́n ní àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé àwọn máa tọ̀ ọ́ ní ìlànà pẹ̀lú ìbámu òfin.

Ta ni Alex Ikechegh?

Alex Ikechegh

Oríṣun àwòrán, Alex Ikechegh/Instagram

Ní ọdún 2019 ló bẹ̀rẹ̀ sí ní dipò òṣèlú mú nígbà tí wọ́n dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bí alága ìjọba ìbílẹ̀ Aba North, ìpínlẹ̀ Abia.

Ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ló wà nígbà náà tí wọ́n yàn-án sípò.

Lẹ́yìn náà ló du ipò sílé aṣojúṣòfin ìlú Abuja láti ṣojú ẹkùn Abia South àti North níbi tó wà báyìí.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Calabar ni ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Business Administration.