A kò ní í padà sí ẹnu iṣẹ́ tí a kò bá gba owó tí ìjọba jẹ wá- SSANU

Aworan awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Awọn oṣiṣẹ fasiti to n ṣe iwọde

Bi iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ kaakiri yunifasiti Naijiria (SSANU) ṣe n tẹsiwaju, awọn eeyan naa ti leri pe awọn ko ni i pada sẹnu iṣẹ bijọba ko ba san ajẹsilẹ gbese ti wọn n jẹ awọn.

Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa ọdun 2024 ni SSANU ati NASU, gunle iyanṣẹlodi.

Igbese naa waye latari owo oṣu mẹrin ti awọn oṣiṣẹ naa sọ pe ijọba apapọ n jẹ awọn.

Aarẹ SSANU sọ pe afi tawọn ba ri alaati gbese tijọba jẹ yii ni awọn yoo too pada sẹnu iṣẹ

Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti bẹrẹ igbesẹ lati pe wọn si ipade fun ajọsọ ọrọ.

“Eyi ki i ṣe ọrọ ipade kankan, ohun ti a fẹ ni ki wọn san owo wa, ki wọn si tẹle gbogbo ilana to yẹ. Mo le fi da yin loju pe bi wọn ba sanwo yii, ki wakati mẹrinlelogun too pe, a maa fagile iyanṣẹlodi yii’’

Aarẹ SSANU, Mohammed Ibrahim, lo sọrọ yii lori eto kan to ṣe lori tẹlifiṣan Channels, lọjọ ti iyanṣẹlodi naa bẹrẹ.

O ni oni kọ ni ijọba ti n ṣeleri fawọn ti wọn ki i mu un ṣe.

Bẹẹ naa lo ni ileri awọn oloṣelu ko jẹ tuntun fawọn mọ, gbogbo ẹ yoo pada ja si ofo ni.

Aburú wo ní ìyanṣẹ́lódì yìí ti mú bá ẹ̀ka ẹ̀kọ́?

Iyanṣẹlodi awọn SSANU ati NASU ki i yee fa ọwọ aago ẹkọ sẹyin nile ẹkọ giga.

Idi ni pe awọn eeyan naa ni wọn n ri si bi aye yoo ṣe dẹrun fun awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn n kọ.

Bi wọn ba ti daṣẹ silẹ, gbogbo ile ẹkọ giga yoo wa ni titipa ni.

Gbigbo ẹka ẹkọ pata titi to fi de ori awọn nnkan amayeṣerun bi ina, omi, opo ayelujara, eto iṣuna ati aabo yoo daṣẹ silẹ, bi awọn eeyan yii ba ti bẹrẹ si iyanṣẹlodi.

Ṣaa, ile igbimọ aṣọfin Naijiria ti sọ pe ko si idi kankan fun iyanṣẹlodi yii lati waye, wọn pe fun ajọsọ pẹlu awọn oṣiṣẹ naa.

Alaga igbimọ to n ri si ọrọ ile ẹkọ giga, Dandutse Mohammed, ṣalaye pe asọyepọ tijọba n beere fun yii wa fun ki inira ma ju bo ti waye yii lọ ni.

O ni ọrọ ajọsọ naa yoo dena idaṣẹsilẹ ọjọ iwaju.

Àwọn òṣìṣẹ́ fásitì bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì jákèjádò Naijiria

UNILAG

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti ti kii ṣe olukọ ati ẹgbẹ awọn olori oṣiṣẹ ni fasiti, SSANU ati NASU, ti bẹrẹ iyanṣẹlodi kaakiri Naijiria, bẹrẹ lati aarọ oni ọjọ Aje.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ SSANU, Mohammed Ibrahim, ati akọwe agba NASU, Ọmọba Peters Adeyemi fi lede, wọn ni oru ọjọ Aiku ni gbedeke ti awọn fun ijọba lori owo oṣu to jẹ wọn, dopin.

Lara awọn nnkan ti awọn oṣiṣẹ naa n bere fun ni owo oṣu mẹrin ti ijọba jẹ wọn, wọn tun bere fun afikun owo oṣu ati pe ijọba gbọdọ mu adehun to ni pẹlu awọn lọdun 2009 ṣẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ijọba apapọ ti kọkọ sọ lọdun 2022 pe oṣiṣẹ ti ko ba ṣiṣẹ ko ni gba owo oṣu, iyẹn lẹyin ti awọn oṣiṣẹ naa gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.

Amọ nigba ti yoo di inu oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ ki wọn san mẹrin ninu owo oṣu mẹjọ awọn oṣiṣẹ fasiti to da iṣẹ silẹ, ninu oṣu Keji ọdun yii wọn to ri owo naa.

Amọ ṣa, ikede Aarẹ ọhun ko mẹnuba owo oṣu awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ, eyi to mu wọn maa ronu nipa ipin wọn lori ọrọ naa.

Lẹyin eyi lawọn ọmọ ẹgbẹ naa kọwe si ijọba apapọ lori owo ọhun, koda, wọn leri, wọn fẹhonuhan, sibẹsibẹ ijọba ko fun wọn ni owo naa.

Ẹgbẹ ọhun ti wa ke si gbogbo awọn eeyan rẹ lawọn fasiti ijọba ni Naijiria bayii lati bẹrẹ iyanṣẹlodi alailọjọ.

Ẹgbẹ SSANU lo wa ni iṣakoso awọn ohun to ṣe pataki ninu ọgba ile ẹkọ, ọpọ nnkan ni ko si ni lọ dede ti wọn ba le da iṣẹ silẹ.

Aarẹ ẹgbẹ naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch pe “Awa ni a wa nibi iṣakoso ina mọnamọna, eto ibaraẹnisọrọ, oju opo ayelujra, eto abo, eto iṣuna, ti wọn ba san owo ti wọn jẹ wa lonii, a o fopin si iyanṣẹlodi wa.”

Iyanṣẹlodi yii lo n waye lasiko ti Aarẹ Tinubu paṣẹ pe ki minisita eto ẹkọ tẹlẹ, Mamman Tahir fa iṣẹ rẹ le minisita tuntun, Ọmọwe Tunji Alausa lọwọ.