Ǹjẹ́ o mọ irú iṣẹ́ tí egbògi ‘bitters’ ń ṣe lágọ̀ ara rẹ?

Aworan awọn 'bitters' ibilẹ kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi gbogbo aye ṣe da owo mọ ni awọn egbogi olomi kikoro ti wọn n pe ni bitters naa ṣe gbajumọ lorilẹede Naijiria yii.

Ọlọkan-o-jọkan awọn egbogi tewe-tegbo naa lo kun ọja, ti awọn onibaara wọn ko si jọra wọn.

Eroja meji ni wọn fi n ṣe egbogi dudu ta a mọ si bitters yii:

Akọkọ ni akọjọpọ ewe ati egbo loriṣiiriṣii, ikeji si ni eroja líle to maa n wa ninu ọti, to si le ṣe akoba fun ara.

Iwadii fi han pe awọn eeyan to n ra egbogi mimu yii n pọ si i ni Naijiria, lai tiẹ ro iru itu to le pa fun ara wọn.

Ìdí tí àwọn èèyàn fi ń mu bitters

Awijare awọn onibaara kan lori rẹ ni pe nitori ọti to wa ninu rẹ lawọn ṣe fẹran rẹ.

Awọn miran sọ pe awọn egbogi ti wọn n to pọ sinu rẹ yẹn gan-an lawọn fẹran, nitori oogun ibilẹ ni.

Dokita onimọ nipa awọn ẹya ara to n gbe inu ikun eeyan, Kodichimma Onwuka, ṣalaye pe ọpọ eeyan n ra awọn egbogi kikoro yii nitori pe owo rẹ ko wọn.

Onwuka sọ pe awọn egbogi naa dẹrun lati ra, wọn ko si ṣoro lati ri pẹlu, yatọ si awọn oogun ibilẹ mii ti owo wọn gara.

Dokita Onwuka sọ pe awọn miran n ra a nitori igbagbọ ti wọn ni ninu iṣẹ egbogi naa.

“Wọn lo dara fun inu rirun, iba, ara sisan asanju, aile ba obinrin ṣe, aisan ibalopọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ṣe n lo o.’’ Onwuka lo sọ bẹẹ.

Dokita Onwuka sọ pe ai si itọju lọna igbalode nigba miran maa n mu ki awọn eeyan pada si egbogi bitters.

O ni ileewosan ati awọn oṣiṣẹ ilera ko pọ lawọn apa ibi kan nilẹ Africa, eyi to maa n mu ki awọn eeyan pada si idi bitters to da bii gbogboniṣe loju wọn.

Dokita Tobechi Ozuzu ni ti eẹ ṣalaye pe awọn ọdọ n lo egbogi bitters ki wọn baa le ni agbara ibalopọ gidi ni.

Ǹjẹ́ egbògi yìí ní àǹfààní kan tó ń ṣe f’ára?

Aworan 'bitters' kan tun ree
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti a dele aye ba nipa egbò ati itakun igi ni pe omi to wa lara wọn dara fun agbo iwosan.

Awọn agbo iba ti ẹfọn fa si eeyan lara, iba jẹdọjẹdọ atawọn iba miran.

Koda, awọn agbo to ṣiṣẹ fun ara asanju wa pẹlu, eyi to n ṣiṣẹ fun ai pe ọmọkunrin ati awọn eyi to n gbọ arun ibalopọ naa wa pẹlu.

Ṣugbọn Dokita Onwuka sọ pe a ko le sọ eyi nipa awọn bitters to gbode kan.

O ṣalaye pe awọn egbogi bitters yii ko gba ilana ayẹwo oogun kọja nigba ti wọn n ṣe wọn.

"Eyi naa lo fa a ti oriṣiiriṣii bitters fi gbode kan lọja bayii, ti awọn eeyan si n ra wọn mu." Dr Onwuka lo sọ bẹẹ.

Gẹgẹ bi iwadii Showande, ti ọdun 2014, ninu ẹgbẹrun kan eeyan to n mu egbogi bitters, ida ogoji n mu un lati fọ ara wọn.

Nigba ti awọn ọkunrin ati obinrin miran n mu un lati fi dena arun .

Iwadii naa fi han pe awọn eeyan kan jẹrii si i pe awọn maa n rù lẹyin tawọn ba mu bitters.

Awọn kan sọ pe ẹnu awọn ki i dun lẹyin tawọn ba mu un, awọn kan si sọ pe awọn maa n bì.

Bẹẹ lawọn kan sọ pe igbọnsẹ gbuuru lawọn maa n ṣe ti awọn ba lo o, awọn mii si sọ pe ara awọn maa n wú lẹyin lilo bitters.

Kí ni ìwádìí ìṣègùn òyìnbó sọ nípa lílo bitters?

Iwadii fi han pe mimu egbogi ibilẹ bitters le ko ba kindinrin eeyan, ti ara yoo maa wú.

Gẹgẹ bi Dokita Onwuka ṣe wi, o ni lati igba ti oun ti n ṣiṣẹ nileewosan l'oun ti ri i pe ọpọ eeyan lo ni iṣoro aisan kindinrin lati ipasẹ awọn egbogi ibilẹ ti wọn n lo.

O ni awọn eeyan naa ko mọ akojọpọ oogun ọhun, tabi ohun ti wọn fi ṣe e ki wọn too maa gbe e lura.

O ṣee ṣe nigba mi-in ki ohun to le fa ijamba fun ara ma pọ ninu awọn bitters naa, gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Omiran si le pọ pẹlu.

Ṣùgbọ́n kí ló dé tí àwọn egbògi náà fi pọ̀ lọ́jà?

Aworan ọwọ to gbe igo egbogi bitters dani

Dr Tobechi Ozuzu, ṣalaye fun BBC pe ajọ NAFDAC to n ri si ounjẹ ati oogun ni eyi ku si lọwọ.

O ni NAFDAC ko ti i fi gbedeke si iye bitters to le jade si ọja ati awujọ .

" Bi NAFDAC ba gbe ilana kan kalẹ to n tọpinpin bi wọn ṣe n ṣe bitters, yoo ran wa lọwọ lati ṣe adinku wọn lawọn ọja to wa ni Naijiria’’

DokitaTobechi Ozuzu, lo ṣalaye bẹẹ.