Èyí ni bí Lookman ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bọ́ọ̀lù títí tó fi di ẹni tí wọ́n fa orúkọ rẹ̀ kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or
- Author, Emmanuel Akindubuwa
- Role, BBC Sport Africa
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ọdun ayọ ni ọdun ni jẹ yii fun Ademola Lookman latari awọn aṣeyọri rẹ nilẹ Afrika ati Yuroopu.
Bẹrẹ lati ipa to n ko ninu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lasiko idije 2023 Africa Cup of Nations (Afcon) titi de aṣeyọri rẹ ninu ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta.
Lookman sọ fun BBC pe “ọdun ayọ ni ọdun yii.
“Mo ti la oniruru nnkan kọja ninu ọdun yii, awọn igbesẹ mi si ti n so eso rere.
“Amọ ṣa, eyii ni ibẹrẹ awọn ohun rere fun mi.”
Lara awọn aṣeyọri Lookman ni bi orukọ rẹ ṣe wa lara awọn ti yoo gba ami ẹyẹ Ballo d’Ord ti yoo waye niluu Paris.
Lara awọn nnkan to mu ki eyii ṣe pataki ni pe oun nikan ni ọmọ ilẹ adulawọ ti orukọrẹ wa lara awọn ọkunrin to mọ gbọọlu gba julọ lagbaye.
O ni “o jẹ ohun iwuri fun mi pe orukọ mi wa lara wọn, paapaa pe emi nikan ni ọmọ ilẹ Afrika to wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu ọdun yii, lara awọn akoko ti irawọ Lookman tan julọ ni goolu to ju sawọn ninu aṣekaba Idije Europa League, eyii to mu ki ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta ṣaṣeyọri.
Lookman fi han ni papa iṣere Aviva niluu Dublin pe oun mọ inu igbin ati ikarahun bọọlu gbigba lọjọ naa.
O ni “Alẹ ọjọ naa yatọ gedegbe... ayo ti a gba jẹ ohun agbayanu nitori Leverkusen naa ko kere ni saa bọọlu ọhun.
Bo ṣe lo akoo rẹ ni Bergamo

Oríṣun àwòrán, EPA
Lookman darapọ mọ Everton ni owo ti iye rẹ jẹ $14.26m nigba to wa ni ọmọ ọdun mọkandinlogun, lẹyin naa lo darapọ mọ RB Leipzig ni Germany.
O gba bọọlu fun Fulham ati Leicester City ko to lọ si Atalanta.
Ko rọrun lati lọ maa gbe ni orilẹede tuntun ati lati kọ ede mii amọ Lookman ko jẹ ki eyii di i lọwọ.
O ni “Kọ rọrun fun mi rara lati kuro nibi ti mo n gbe fun ọjọ pipẹ amọ mo yan lati ni iriri tuntun, kii ṣe gẹgẹ bii agbabọọlu nikan amọ gẹgẹ bii ẹlẹran ara.
“O ran mi lọwọ lati dagba si gẹgẹ bii agbabọọlu, inu mi si dun pe mo gbe igbesẹ akin ọhun.”
Iyatọ tuntun lo ti de ba aye Lookman lẹyin ọdun meji to de Bergamo labẹ iṣakoso akọnimọọgba Gian Piero Gasperini.
Lookman ṣalaye pe “Wọn fun mi laaye lati gba bọọlu bi mo ṣe fẹ.
“Akọnimọọgba wa fẹran ki a koju awọn alatako, ki a sọ goolu sinu awọn ki a si maa ṣe awọn ohun tuntun miran, mo si ti jẹ ki wọn mọ pe emi naa ko kere.”
Agbọọlu to ni ifẹ Naijiria lọkan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe o gba bọọlu pẹlu awọn ọdọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi, Lookman ko sọ afujusun rẹ lati gba bọọlu fun Naijiria nu.
O ni “Lootọ ni wọn bi mi ni UK, ṣugbọn ọmọ Naijiri ni mi.
“Gbogbo igba ni mo maa n kan si awọn eeyan mi, lati mọ nipa aṣa ati iṣe wọn, lati kekere ni mo ti maa n rinrinajo lọ si Naijiria.
Nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria o ni “ẹgbẹ naa gba mi tọwọ-tẹsẹ fun igba akọkọ, wọn si ri mi gẹgẹ bii ọkan lara wọn.
“Ohun iyi ni fun mi pe mo gba bọọlu fun Naijiria, mo si wọ aṣọ agbabọọlu Naijiria pẹlu iwuri.
Lookaan wa lara awọn to gba bọọlu fun Naijiria ninu idije Afcon 2023 bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ naa ko gba ife ẹyẹ lẹyin ti Ivory Coast na Naijiria ni ami ayo meji si ọkan ninu aṣekagba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images













