Chris Ndukwe and Olamide Alli: Ọkùnrin kan gún àfẹ́sọ́nà rẹ pa, òun náà gbé ògùn jẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe, arakunrin kan ti wọn ni orukọ rẹ n jẹ Chris Ndukwe, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ni wọn fura si pe o gun obinrin kan, to n jẹ Olamide Alli pa.
Atẹjade ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fisita fun awọn akọroyin salaye pe, lẹyin ti Chris gun Olamide to jẹ afẹsọna rẹ pa tan, ẹti tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, lo ba gbe ogun oloro jẹ.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa àwọn tí yóò láǹfàní àti lọ sí Hajj lọ́dún yìí
- Àìmọ̀kan ló ń ṣe ìjọba Oyo tó fẹ́ ṣí iléèwé, gbogbo ìpínlẹ̀ ló ní àrùn COVID 19- Ijọba àpapọ̀
- Lórí bóyá igbákejì gómìnà Ondo yóò fipò sílẹ̀ tàbí rárá, ohun tó lu sí wa lọ́wọ́ nìyí
- Ènìyàn 675 ni èsì àyẹ̀wò sọ pé ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Covid-19 ní Nàìjíríà
Iroyin naa ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ni abule Victory Park, agbegbe Ilasan ni Lekki ni ipinlẹ Eko, ti Olamide to jẹ́ alaisi naa, si wa se abẹwo si Chris, to bi ọmọ meji fun lati agbegbe Ọgba.
Iroyin naa ni Chris lo ransẹ pe Olamide pe ko wa sile oun, ti onitọun naa si wa pẹlu aburo rẹ obinrin, ẹni ọdun mejilelogun ati ọmọ rẹ mejeeji to bi fun Chris, ti wọn jẹ ọmọ ọdun meje ati mẹta.
Olamide, aburo rẹ ati awọn ọmọ rẹ mejeeji sun mọju nile Chris, nigba ti ilẹ si mọ ni aburo Olamide gbọ orin kan to lagbara lati inu yara ti Chris ati ẹgbọn rẹ sun si, igba to de ibẹ lo ri pe awọn mejeeji ti ku.
Ileesẹ ọlọpa Eko ni ni kete ti wọn fi isẹlẹ naa to oun leti, ni oun ran awọn ọlọpa oluwadii lọ sibẹ, ti wọn si ba obinrin naa ninu ẹjẹ ara rẹ pẹlu ọgbẹ to jin lori rẹ, nigba ti ọkunrin naa n pọ nnkan funfun lẹnu, eyi to seese ko jẹ oogun apakokoro Sniper.
Awọn ọlọpaa tun se akiyesi pe ẹjẹ wa lara ọbẹ to wa ninu yara naa, ti wọn si tun ri korofo igo majele meji , agolo igo ohun mimu Red Bull mẹta ati ẹmu ti wọn fi n yọ eso kan.









