Oyo Corornavirus: Gbogbo ìgbìmọ́ aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ló ṣe àyẹwò àrùn Covid-19 Sùgbọ́n...

Gbogbo ọmọ ìgbìmọ́ aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ló ṣe àyẹwò ààrùn Covid-19 Sùgbọ́n

Oríṣun àwòrán, Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde tí fi léde lórí ojú òpó ìkànsíraẹni Facebook rẹ̀ pé, mẹ́ta nínú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣe ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ló ti ni ààrùn Coronavirus bayìí.

Gómìnà ní sáájú àsìkò yìí ní gbogbo ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ti ṣe àyẹ̀wò ààrùn coronavirus súgbọ̀n mẹta nínú wọ́n ni ayẹwò fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti ni ààrùn náà nígbà tí àyẹ̀wò àwọn méjì kò sì dájú bóyá wọ́n ni tàbi wọ́n kò ni ààrùn.

Seyi Makinde ni ìjọba ti ránṣẹ́ si àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kan, títọpasẹ ibi ti wọ́n ti rìn sí náà ti bẹ̀rẹ̀, bákan náà ni ọfíìsì wọ́n tí wà ni títìpa fún àtúṣe tó yẹ.

Gómìnà Makinde ní " Ààrùn náà sì wà pẹ̀lú wa dájúdájú, pé à n gbìyajú láti dá ọrọ̀ ajé padà bọ̀ sípò kò túnmọ̀ si pé ààrùn náà ti di oun ìgbàgbé"

" Ó ṣe pàtàkì kí a máa mójú tó ara wa nípa wfífọ ọwọ́ wa déédé pẹ̀lú omi aàti ọṣẹ , kí a sì maa wọ ìbòmú ti a bá ti wà pẹ̀lú àwọn eníyà, ìjìnà síra ẹni náà si ṣe pàtàkì pẹ̀lú."

gomina Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, twitter/Seyi makinde

Update on Coronavirus ní Nigeria: Bí a ṣe fi N2.7 bilìọ̀nù kojúu àrùn Coro réé- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Ipinlẹ Oyo ni awọn ti na owo to to N2,779,000,000 lati koju arun COVID-19 nipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Oyo fi sita loju opo Twitter wọn pẹlu alaye ni sisẹ n tẹle lori bi wọn ṣe na owo naa.

Nigba to n ṣalaye alakalẹ gbogbo ibi ti wọn na owo yii si kaakiri iṣọri iṣọri, kọmiṣọnna eto isuna ipinlẹ Oyo, Akinola Ojo sọ ipinnu ijọba ni pato.

O sọ eyi nibi ipade igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Oyo pe N900.5 miliọnu ni awọn fi ra awọn nkan iranwọ, ounjẹ ati irugbin fun araalu.

Wọn ni awọn na N370.6 miliọnu lati ṣatunṣe ibudo itọju ajakalẹ arun to wa ni Olodo.

Bakan naa, wọn na N453.7 miliọnu lori amojuto ibode ipinlẹ, ọkọ iṣẹ awọn oṣiṣẹ alaabo ati itọju awọn oṣiṣẹ gangan.

N118 miliọnu ni wọn na lori iranwọ ileewosan ijọba to wa ni kọlẹẹji fasiti Ibadan fun ṣiṣe awọn ayẹwo arun COVID-19.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lafikun, wọn ni fun ayẹwo gangan, N614.7 miliọnu ni wọn na lori ayẹwo, ohun eelo fun ayẹwo atawọn nkan jijẹ fun ilera

Nigba ti wọn na N321.2 miliọnu lati ra ọkọ awọn eleto ilera Ambulansi.

Ojo jẹ ko di mimọ siwaju sii pe N156 miliọnu ni wọn ya sọtọ fun awọn to n ṣiṣẹ iyọnda

Pẹlu N15,000 ajẹmonu owo pe wọn n fẹmi ara wọn wewu ti wọn ti n jẹ wọn latinu oṣu kẹta.

O wa pe gbogbo ẹbun owo to wọle latọdọ awọn Aladani, ileeṣẹ ati ajọ pọ soju kan pe o jẹ N1.2 biliọnu.

Àkọlé fídíò, Genotype: Kí làwọn àǹfàni àti ewu tí ẹ̀yà jínótáìpù rẹ le mú bá ìgbé ayé rẹ̀

Coronavirus ní Nigeria: Makinde kéde àyípadà lórí ọjọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé padà l'Oyo

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede ayipada lori ọjọ ti ile iwe yoo di ṣiṣi pada kaakiri ipinlẹ naa.

Ọjọ Aje tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa ni ijọba Seyi Makinde n gbero tẹlẹ lati ṣi ileewe pada, amọ ijọba ti so o rọ bayii nitori bi awọn eeyan to n karun coronavirus ṣe pọ si nipinlẹ naa.

Akọwe iroyin fun Gomina ipinlẹ, Taiwo Adisa lo fi idi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun.

Ni bayii, awọn olukọ nikan yoo wọle pada lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa nigba tawọn akẹẹkọ kan yoo wọlẹ pada lẹyin ọṣẹ kan tawọn olukọ wọn ba ti wọle tan.

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti kọkọ tako ṣiṣi ileewe pada lasiko yii ti aarun coronavirus si n pọ si ni Naijiria, ijọba aika ilera awọn eeyan si ni.

Amọ ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe ohun ti gbaradi fun ṣiṣi ileewe pada nipa riran awọn akọṣẹmọṣẹ ninu eto ilera ati ọrọ ayika lọ si awọn ileewe lati sọ bi eto ṣe le kẹsẹjari.

Ijọba ipinlẹ Oyo ni gbogbo eto lo ti to lati rii pe awọn olukọ atawọn akẹkọọ n tele ilana ti ijọba la kalẹ lati dena itankalẹ aarun covid-1

Àìmọ̀kan ló ń ṣe ìjọba Oyo tó fẹ́ ṣí iléèwé, gbogbo ìpínlẹ̀ ló ní àrùn COVID 19- Ijọba àpapọ̀

Ajọ NCDC ti ni ko si ipinlẹ kankan ni Naijiria to dantọ lọwọ arun Coronavirus.

Ọga agba ajọ naa, Chikwe Ihekweazu lo fi eyi lede lọjọ aje lasiko ti wọn n ṣepade pẹlu igbimọ amuṣẹya ti aarẹ gbekalẹ lori arun yii ni ilu Abuja.

Ohun to mu ọrọ yii jade gan ni bi ajọ NCDC ko ṣe tii jabọ boya eeyan lugbadi COVID -19 ni ipinlẹ Cross River lọsan ọjọ aje yẹn.

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Ọgbẹni Ihekweazu n sọrọ nigba ti ibeere kan jade lori pe awọn ipinlẹ kan naa to ti da awọn alaisan yii silẹ nileewosan n kede ara wọn pe awọn bọ lọwọ COVID-19.

"Ko si ipinlẹ kankan to ti bọ yanyan lọwọ arun COVID-19, ko si nkankan. Ko da ilu Zealand gan to da wa nibi to wa pada ni lẹyin igba diẹ ti wọn o ni tẹlẹ.

O ni "a o le ya ara wa kuro lara orilẹede wa. Tori naa lọwọlọwọ, ko sẹni to bọ, tori eyi lao fi tẹsiwaju ni ṣiṣe ayẹwo lati mọ awọn to ni.

Ẹwẹ, igbimọ amuṣẹya COVID-19 gba awọn ọmọ Naijiria niyanju lati ma bẹru ṣiṣe ayẹwo paapaa julọ tori arun naa kii kuku ṣe idajọ iku.

Gomina MAkinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

"A lee dena pipadanu ọmọ Naijiria bi a ba pe fun iranwọ". Alaga igbimọ naa, Boss Mustapha sọ eyi o si tun pe akiyesi si ọrọ awọn ara orilẹede meji kan ti wọn gbamu to yọ wọ Naijiria o si gboriyin fun ileeṣẹ to n ri si iwọle wode ni Naijiria fun iṣẹ takun takun. O ni awọn ṣi tun gbọ pe awọn kan n ko ounjẹ wọle lọna aitọ ṣugbọn o ni ileeṣẹ to n ri si iwọle-wọde n ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ.

Ipade yii tun mẹnu ba bi awọn eeyan ko ṣe tẹle awọn ofin ti ijọba la kalẹ lati dena arun yii. O ni ọsẹ meji akọkọ lawọn eeyanfi ṣe boju boju amọ lẹyin rẹ, wọn ti rẹwẹsi.

Mustapha tọka si wipe awọn ṣe iwadii kan to fihan awọn ibi kan wa ni Naijiria ti wọn o ṣi gbagbọ pe COVID 19 wa lootọ ti wọn si n fọwọ yẹpẹrẹ mu u.

Àkọlé fídíò, Kid boxer: Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà

Dokita Aliyu ni "o lee ko Coronavirus bi o ba jade lai tẹle awọn ofin ti a ṣe". Ẹwẹ, o gboriyin fawọnipinlẹ to n jabọ deedee nipa iye awọn to ti lugbadi arun naa. O jẹ ko di mimọ pe " ko si itiju ninu sisọ iye awọn to ni i nipinlẹ yin. Bi a o ba mọ otitọ nipa ipo ti ipinlẹ yin wa ni ti arun yoo, ẹ n fi ẹmi awọn araalu yin wewu ni".

Update on school resumption in Nigeria: Iléèwé tó bá tẹ̀lẹ́ ìlànà ìjọba lórí àbò COVID-19 nìkan ni yóò ṣí- ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe ipinnu oun lati ṣi awọn ile iwe pada lọjọ kọkandilọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020 ṣi wa ni digbi.

Agbẹnusọ Gomina ipinlẹ naa, Taiwo Adisa sọ fun BBC pe kii ṣe gbogbo ile iwe ni yoo di ṣiṣi

O ni ayafi awọn ile iwe to ba tẹlẹ ilana ti ajọ eleto ilera gbe kalẹ lati dabo bo awọn akẹkọ.

Adisa ni awọn aṣoju ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ni ipinlẹ Oyo yoo ma kaakiri awọn ile iwe lati ri pe wọn ni gbogbo oun to yẹ

O ni eyi ko ṣẹyin ki wọn baa le ni lọna ati dena itankalẹ arun Covid-19 laarin awọn ọmọ ile iwe.

Adisa tun ni "Ile iwe to ba ṣe awọn nnkan to yẹ nikan lo maa koju osuwọn lati wa ni ṣiṣi."

"Ṣugbọn awọn ile iwe ti ko ba ṣe awọn ohun to tọ bii ibi ti awọn ọmọ ile iwe yoo ti maa fọ ọwọ wọn pẹlu aridaju pe awọn akẹkọọ naa yoo ma lo ibomu, ko tii ṣetan lati di ṣiṣi."

Adisa ṣalaye pe awọn to wa ni ipele kẹfa ile iwe alakọbẹrẹ, awọn to wa ni ipele kẹta akọkọ ati ipele kẹta keji ni ile iwe girama nikan ni ijọba lero pe yoo pada sẹnu ẹkọ wọn.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Twitter

Ni ti pe awọn to ni arun Coronavirus n pọ si ipinlẹ Oyo, Adisa ni ko ṣẹyin ayẹwo ojule si ojule ti ijọba ipinlẹ ọhun gunle.

O ni ojuko ti ijọba Oyo ti n gba nnkan ayẹwo coronavirus le ni mẹwaa kaakiri ipinlẹ naa, ati pe ida mẹwaa ninu ọgọrun awọn to ṣayẹwo arun naa lo ni ni ipinlẹ ọhun.

Adisa pari ọrọ rẹ pe ijọba ti kọwe ranṣẹ si awọn olori ile iwe lori igbesẹ to yẹ ki wọn gbe, ṣugbọn ti wọn ba kọ lati tẹle awọn igbesẹ yii, ko ni si aye lati ṣi irufẹ ile iwe bẹẹ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Twitter

Lórí ṣíṣí iléèwé pàda, Makinde ní ó yá ní ìpínlẹ̀ Oyo, Cross River ní kò sóhun tó jọọ́

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti paṣẹ ki awọn ileewe gbogbo ni ipinlẹ naa o di ṣiṣi pada ni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii, amọ ijọba ipinlẹ Cross River ti fi ọsẹ meji kun iwọle awọn akẹẹkọ.

Igbimọ amuṣẹya ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ lori kikoju ajakalẹ arun coronavirus lo kede igbesẹ ijọba ipinlẹ naa lọjọ Aje.

Ninu ọrọ ti wọn fi lede, ijọba ipinlẹ Cross River ni awọn fẹ fi ọsẹ meji naa se ayẹwo gbogbo awn ileewe naa lati le gbaradi fun iwọlẹ awọn akẹkọ naa.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Ti ijọba ipinlẹ Cross River ko ba yi ẹnu pada, awọn ni ko ba jẹ ipinlẹ akọkọ ti yoo ṣi ileewe pada lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ ti wọn, Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni awọn akẹkọọ iwe kẹfa nileewe alakọbẹrẹ (Primary Six), iwe kẹta ileewe girama (JSS 3) ati kilasi aṣekagba nileewe girama (SSS 3) nikan ni yoo wọle ikẹkọọ ni ọjọ naa.

Ati pe wọn si gbọdọ maa tẹle awọn ilana ti igbims amuṣẹya naa ba fi silẹ.

gomina Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, twitter/Seyi makinde

Bakan naa lo tun fi kun un pe awọn ileejọsin pẹlu lee pada si nii ṣi ilẹkun wọn silẹ fun ijọsin lati ọjọ Aje kan naa

Sugbọn ida kan ninu mẹrin awọn eeyan to n wa si ileejọsin naa tẹlẹ ni aye gba lati maa jọsin fun asiko yii na ti wọn ko si gbọdọ maa tẹle ofin ati ilana igbimọ amuṣẹya naa.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ọyọ tun paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa lati ọjọ Aje to n bọ.

Amọ, ipinlẹ Cross river nikan ni ko i tii kede pe awọn ni arun Coronavirus ninu gbogbo awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede Naijiria.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Twitter