Ibidun Ighodalo: Ǹkan ti amọ̀ nípa ilúmọ̀ọ́ká arẹwà obìnrin nígbà kan rí tó d'olóògbé

Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ebi oloogbe Ighodalo ti gbe oku rẹ lọ si ileewosan kan ni agbegbe Lagos Island ni ilu Eko.

Alamojuto ileeṣẹ rẹ, lo fi ọrọ naa sita faraye gbọ.

O ni ọjọ Aiku ni ọkọ oloogbe naa atawọn mọlẹbi gbe oku rẹ

Nigba ti ikọ BBC News de ile oloogbe naa lagbagbe Bourdilourn ni ilu Eko lowurọ Ọjọ Aje nibi ti awọn eeyan leni ejeeji ti n wọle ba wọn daro.

Paroparo ni agbegbe naa da ti iwọnba awọn eeyan melookan to n wọle si n kọ ọrọ idaro wọn si iwe ibanikẹkun ti wọn ṣi pẹlu aworan oloogbe naa.

Ibidun Ighodalo: Ǹkan ti amọ̀ nípa ilúmọ̀ọ́ká arẹwà obìnrin nígbà kan rí tó d'olóògbé

Ọpọlọpọ awuye lo n lọ lori iku to pa Ibidun Ighodalo to jẹ́ ọbinrin tó rẹ̀wà jùlọ nígbàkan rí, tó sì tún jẹ́ ìyàwó adarí àti olùdásílẹ̀ ìjọ Trinity House.

Bi o tilẹ jẹ pẹ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló tí n fi èrò wọ̀n hàn lórí ikú tó pa Ibídun.Ìròyìn sọ pé, arẹwa náà kú ní ìdájí òní Ọjọ́ àìkú ní ìlú Port Harcourt, nípìnlẹ̀ Rivers.

Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ tó máa ń báni ṣètò ayẹyẹ Elizabeth R ní, àti pé ó ti wà ní ìpínlẹ̀ Bayelsa àti Rivers láti ṣèrànwọ́ kíkọ́ ibudó ti wan yóò ti maa tójú àwọn aláàrùn Covid-19 sí.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Nurudeen Lawal adarí Elizabeth R tó jẹ́ ilé iṣẹ́ olóògbé sàlàyé fún BBC pé àwọn kò mọ ǹkan to ṣe ku paa nítori lẹ́yìn ti àwọn pari iṣẹ́ ní alẹ́ àná, olúkúlùkù wọ yàrá rẹ̀ lọ láti sù, sùgbọ́n nígbà ti ilẹ̀ mọ́ ni owúrọ̀ yìí ni kò jí mọ.

"Ó lọ sùn lánàá sùgbọ́n nígbà ti olúkúlùkù jí láàrọ̀ òní ni kò jí mọ́

Ọkùnrin náà kò dárúkọ ilé ìtura tàbi àdúgbò ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sùgbọ́n ìlú Port Harcourt lo ti ṣẹlẹ̀.

Bákan náà ni ẹni tó sún mọ́ ọkọ olóògbé náà fìdi ìṣẹ̀lẹ̀ aburu náà múlẹ̀ fún ìwé ìròyìn "The Nation", sùgbọ́n kò sọ bóyá o ti ṣe àìsàn tẹ́lẹ̀.

Ibídùn fí ọkọ àti ìbejì rẹ̀ silẹ̀ sáyé lọ

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ọjọ́ kọkàdínlógún Oṣù tó ń bọ̀ ló pinu láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ojójì ọdún rẹ̀.

Taní Ibidunni Ighodalo tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà ń selédè lẹ́yìn rẹ̀

Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ǹkan tí a mọ̀ nípa Ibidunni Ighodalo tó kú

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ń bèrè pé taa ni Ibídunni Ighodalo, nítori náà ni aṣe ṣe àkójọpọ̀ àwọn ǹkan ti a ti mọ nígbà ayé rẹ̀

  • Àrẹwa tí ojú rẹ̀ wà lára èpo oṣẹ Lux ní Ibidunni ti ó sì ti jẹ́ ilúmọ̀ọ̀ká láti ẹni ọdún méjìdílógún.
  • O fẹ́ olùṣọ́àgùntàn Ituah Ighodalo olórí ìjọ Tirinity House ní ọjọ́ kẹ̀rìndinlógun oṣù kejì ọdún 2007.
  • Òun ni olùdásílẹ̀ àjọ kan tó ń poun réré ọ̀rọ̀ àìrọ́mọbii tí a mọ̀ sí Ibidunni Ighodalu Foundation tó sì tún n ń ran àwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún láwùjọ lọ́wọ́ láti ṣe IVF
  • Ìgbà mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ ló gbìyànjú àti di ọlọ́mọ láyé nípa ṣíṣẹ ọ̀nà àti rọ́mọbí ìgbàlódé IVF
  • Ibidunni àti Ituah ní ọmọ méjì papọ̀
  • Ilé iṣẹ́ rẹ̀ Elizabeth R ló maa ń ṣe ilú Eko lóge lásìkò ọdún kérésì

Ẹ̀wẹ̀, ọkọ rẹ̀ Ituah Ighodalo lẹ́yìn tó gba ipè pé ọkọ rẹ̀ kú lótún ṣe ètò ìsìnkú fún ẹnikan lówòrọ̀ òní ojọ́ àìkú.

Ìsìnkú Deji Okoya ọmọ-ọmọ ilúmọ̀ọ́ka onísòwò Rasak Okoya ni olùsáàgùntàn náà ṣe, tgí ó sì sọ níbẹ̀ pé gbogbo àyé fẹ́ẹ̀ dojúdé pẹ̀lú ìròyìn ikú ìyàwó òun, sùgbọ́n ènìyàn gbọdọ tẹ̀síwájú ìgbé ayé rẹ̀.

Ituah ní láti ǹkan bí wákàtí díẹ̀ sẹyìn, gbogbo ǹkan lo daru papọ.

"Tí wọ́n bá sọ fún wá ni ọjọ́ àìkú tó kọjá wipe àó wá sòkú Ayodeji ènìyàn yóò jiya"

Ọdún kẹtalá rẹ̀ẹ́ tí Ituah àti Ibidunni ti wà bíi tọkọtaya kí ó to dédé dolóògbé ní ilú Port harcourt láàrọ̀ kùtù ọjọ́ àìkí

Ibidun Ighodalo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ibidun Ituah Ighodalo fayé silẹ̀ ìlúmọ̀ọ́ká arẹwà tí fáyésilẹ̀
Ibidun ati ẹbi rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @prettypearl

Kogi Robbery: Àwọn adigunjalè tó ja báńkì lólè ní Kogi, ya bo àgọ́ ọlọ́pàá,pa ọlọ́pàá mẹ́jọ

Awọn adigunjale ti pa ọlọpaa mẹjọ, ti ọga ọlọpaa DPO si wa lara wọn ati obinrin kan ni agbeegbe Isanlu, ni ijọba ibilẹ Yagba ni ijọba ipinlẹ Kogi.

Iṣẹlẹ naa to wayẹ ni aago mejila ọsan ni o da ipaya silẹ ni gbogbo agbeegbe naa ti awọn eniyan si sa asala fun ẹmi wọn.

Iwadii fihan wi pe ni ṣe ni awọn adigunjale naa digun lu ile ifowopamọsi First Bank to wa ni agbegbe naa, ti wọn si kọkọ lọ sigun bọ agọ ọlọpaa to wa ni ibẹ.

Iroyin ni ado oloro ni awọn adigunjalẹ naa lo lati sigun bo agọ ọlọpaa naa, ti ado oloro naa si pa awọn ọlọpaa to wa ni bẹ.

Lẹyin naa ni wọn lọ si ile ifowopamọsi naa, ti wọn si yin ibọn pa obinrin to n gba owo ninu banki naa.

Fidio to wa lori ẹrọ ayelujara ṣe afihan bi awọn adigunjale naa ṣe yin ado oloro to pa awọn ọlọpaa naa, ti o si ba agọ ọlọpaa naa jẹ.

Ọjọ́ karùn ún, oṣù Kẹrin ọdún 2019 ló pé ọdún kan ti ìdigunjalè iru eleyii waye ni nílùú Ọffa, ni ipinlẹ Kwara, ti wọn si ja ileefowopamọ maarun ọtọọtọ lole.

Awọn kan lara wọn wọ agọ ọlọpaa to wa nitosi, ti wọn si pa ọlọpaa mẹsan, to fi mọ ọlọpaa obinrin kan to loyun sinu.