Fake News: Wọ́n padà ká a nílẹ̀ ṣùgbọ́n àbàwọ́n rẹ̀ ṣì wà lára mi

Awọn oniroyin Senegal ni iroyin ofege ti gbilẹ lẹnu perete ki idibo waye.

Oríṣun àwòrán, AFP

    • Author, Michelle Madsen
    • Role, Investigative journalist

Gẹlẹ bi mo ṣe n jade ninu kilasi ẹkọ nipa ijo ninu orun lọsan gangan ọjọ kan ni apa ariwa ilu London ni mo dede ba ọpọ ipe lorii foonu mi pẹlu awọn nọmba orilẹede Afirika.

Mi o loye ohun to ṣẹlẹ - mo ba wo oju opo ikansiraẹni Facebook ati Twitter mi, ọpọ lẹta ni mo ti gba ti gbogbo wọn n bere ọrọ kan naa lọwọ mi pe ṣe emi ni "Michelle Damien", akọroyin iroyin aburu kan to n da wahala silẹ ni gbogbo Senegal?

Lọkan ninu awọn to fọrọ raṣẹ ba ni " ẹsun iwa ibajẹ kan n mi orilẹede mi titi, wọn si ti darukọ rẹ".

" Akọroyin ọmọ orilẹede Senegal ni mi mo si ni lati ba ọ sọrọ"

Awọn oniroyin Senegal ni iroyin ofege ti gbilẹ lẹnu perete ki idibo waye.

Oríṣun àwòrán, George Wafula/BBC

Eyi ṣẹlẹ ni o ku ọsẹ diẹ ṣaaju idibo aarẹ ni Senegal bẹẹ si ni ẹni ti iroyin naa n ba wi Ọgbẹni Sonko jẹ ọkan lara awọn to n gbena ibo yii woju aarẹ Macky Sall.

Bi o tilẹ jẹ pe gẹgẹ bi oniroyin aṣewadii, mo ti kọ ọpọlọpọ iroyin nipa Senegal atawọn ileeṣẹ epo.

Aworan obinrin kan to de igo

Oríṣun àwòrán, George Wafula/BBC

Gbogbo wọn fẹ mọ boya emi ni mo kọ iroyin kan ti akọle rẹ jẹ "Ipenija lilo awọn nkan alumọni ilẹ Afirika lọna aitọ" eyi ti wọn gbe jade loju opo ayelujara ileeṣẹ iroyin kan ni Ghana lọjọ kẹsan oṣu kinni ọdun 2019.

Iroyin naa n fẹsun ka oludije fun ipo Aarẹ ẹgbẹ alatako lorilẹede Senegal, Ousmane Sonko pe o gba abẹtẹlẹ gọbọi lọwọ ileeṣẹ epo ilẹ Yuropu wọn si gbe e jade pe "Michelle Damsen" lo kọ ọ", lẹta meji pere lorukọ yii fi yatọ si temi - Michelle Madsen.

Presentational grey line
Àkọlé fídíò, Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ
Presentational grey line

Ẹwẹ, akọroyin abẹlẹ bii ọtẹlẹmuyẹ lai gbowo oṣu ni mi, aimọye iroyin ti mi o kọ ni wọn ti forukọ mi si - mo mọ pe emi kọ ni mo kọ eleyi ti wọn n sọ yii ṣugbọn awọn koko iroyin to jade ninu rẹ gan mi mi titi bo ṣe wa di pe wọn lọ ọ mọ mi lẹsẹ ko ye mi.

Kia ni awọn to n fi koko ọrọ ṣe ọfintoto ṣafihan pe iroyin ofege ni. Ileeṣẹ kan ti wọn darukọ ninu rẹ Oxfam sọ fun mi pe awọn ko gba owo kankan lọwọ ileeṣẹ epo ṣugbọn awọn ti ṣagbatẹru sisanwo ri fun idanilẹkọ kan fun Ọgbẹni Sonko. Ootọ eleyi lasan lee jẹ ki awọn eeyan gba iroyin naa gbọ.

"Gbogbo ọṣẹ ti mo ngbiyanju lati fi wẹ mọ, pabo lo n ja si".

Aworan Obinrin to n to gbe ẹrọ ipe sọwọ to tun n wo kọmputa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, George Wafula/BBC

Onimọ kan sọ fun mi pe awọn to lee ri anfani lara iru iroyin bayii ni ijọba Senegal tabi awọn ileepo.

Ọdun kan kọja, sibẹ mi o ri ẹnikankan to n jẹ "Michelle Damsen" boya mi o si ni mọ ọ lailai.

Mo ṣaa fẹ mọ ẹni to n jẹ Michelle Damsen yii, mo tun wadii kiri . Nigba ti aṣiri maa fẹ tu, mo tọpasẹ iroyin naa titi de ileeṣẹ iroyin akọkọ to gba a, a pe nọmba ẹni to mu u wa lo ba di ti akọroyin Senegal kan ṣugbọn to n gbe ni Amẹrika, Baba Aidara - ọrẹ mi ree e.

Ẹwẹ, Aidara ni o ti, oun kọ lo kọ ọ. O ni oun gbero pe wọn lo ọna ipa lo nọmba oun ni oun si fura si ijọba orilẹede Senegal.

Okunrin kan ati obinrin n wo nkan lowo won
Àkọlé àwòrán, Michelle n sabewo sawon oju opo kan lori erọ kọmputa

Awọn oniroyin Senegal ni iroyin ofege ti gbilẹ lẹnu perete ki idibo waye.

Awọn ikọ akọroyin fun aarẹ kọ lati ba mi sọrọ.

Gbogbo eyi da bii iji lile fun awọn oniṣẹ iroyin to si waye laarin ọjọ diẹ.

Michelle ati okunrin kan bi wọn se n wo bi ijoko ile ṣe lọ
Àkọlé àwòrán, Bí wọ́n ṣe kó mi mọ́ rògà ìròyìn òfégè kan tó leè kóbá olùdíje Ààrẹ ẹgbẹ́ alátako

Nigbẹyin gbẹyin, gbogbo iroyin ofege ni wọn ti yọ kuro nita ti wọn si ti tun un kọ. Ṣugbọn abawọn naa ṣi wa nibẹ - eyi si lo le ju to si buru jai nipa titan iroyin ayederu kalẹ paapaa to tun wa bọ si asiko idibo.

Bakan naa pẹlu gbogbo ohun ti mo la kọja, o to ki eeyan fi sọkan pe igba mii ti "Michelle Damsen" ba tun jẹ jade ninu iroyin, iroyin naa ati ipa rẹ yoo rin jina gan.

Awọn oniroyin Senegal ni iroyin ofege ti gbilẹ lẹnu perete ki idibo waye.

Oríṣun àwòrán, George Wafula/BBC