Osun state lockdown update: Ìpínlẹ̀ Osun ṣòfin ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹnikẹ́ni tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, BBC/others
Ẹwọn gbere ni fun ẹnikẹni to ba ti jẹbi ẹsun ifipabanilopọ bayii ni ipinlẹ Ọṣun.
Eyi ni atunbọtan abadofin ti awọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun fi ẹnu rẹ jona eyi tiolori ile naa, aṣofin Timothy Owoẹyẹ ṣalaye pe yoo mu adinku ba ọwọja iwa ifipabanilopọ to n fojojumọ gogo sii ni lorilẹede Naijiria bayii.
Ofin yii n waye lẹyin ọkan-o-jọkan iṣẹlẹ awọn omidan ti awọn eeyan kan n ṣekupa lẹyin ti wọn ba ti fipa ba wọn lo pọ tan.
Bakan naa lawọn aṣofin naa tun fi sinu ofin naa pe ẹnikẹni to ba gbimsran rẹ ṣugbọn ti ko ṣaṣeyọri lori rẹ yoo lọ lo ọdun mẹrinla roko ọba.
Asofin Owoẹyẹ rọ awọn ọdọ lati jinna si iwa ọdaran naa tabi iwa ipa yoowu si awọn obinrin.
JusticeforUwa:Ọwọ́ ọlọpàá tí tẹ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tó ṣekú pa Uwaila

Ọwọ́ sìnkún ọlọ́pàá ti tẹ ọ̀kan nínú àwọn tó pa Uwaila Vera Omozuwa akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Uniben tí wọ́n fipá bálòpọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sì tún paá síbẹ̀.
Alága àjọ tó n rísí àwọn ọmọ Nàìjíríà lókè òkun Abike Dabiri-Erewa ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀ @abikedabiri
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ẹ̀wẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti ń fèrò wọ́n hàn lórí ìgbẹ́sẹ̀ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàáb ní àsìkò yìí
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Mo sunkún nígbà tí mo rí ẹ̀jẹ̀ nílẹ̀ ní sọ́ọ̀ṣì tí wọ́n pa ọ̀mọ mi sí- Bàbá Uwa, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tí wọ́n fipábálòpọ̀
Justice for Uwa: Bàbá Uwa, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tí wọ́n fipábálòpọ̀ ní Benin bá BBC sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe pa mọ rẹ̀
Baba arabinrin akẹkọọ ti awọn eeyan kan fipabalop ti wn si tun ṣekupa ni ilu Benin ti ṣalaye fun BBC News pe ibanuj ti ko lẹlgbẹ ni o ba oun pẹlu iku mbinrin naa.
o ṣalaye pe lootọ mọ marun ni oun bi, ṣugbọn Uwa da yatọ laarin gbogbo wọn.
Justice for Uwa: Ọ̀gá Ọlọ́pàá Naijiria sèlérí láti wá àwọn tó ṣekúpa Omozuwa láwàrí
Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Niajiria, Mohammaed Adamu ti seleri wi pe awọn yoo se awari awọn to sekupa arabinrin Vera Omosuwa ni ipinlẹ Edo.
Adamu ni oun ti fikun awọn ọlọpaa to n sewadii iṣẹlẹ naa lati ri wi pe wọn tete mu awọn to wu iwa ika naa ni kiakia.
Oga ọlọpaa na to bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, wa ba awọn ẹbi ati ara obinrin naa kẹdun pẹlu ileri pe awọn aṣeka naa ko ni lọ lai jẹya.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Edo ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi lori iṣẹlẹ naa.
Ni opin ọsẹ ni iroyin gbe e gbe awọn okunrin mẹrin kan fi ipa ba ọmọbinrin lọpọ ni ibi to ti n kawe ni ile ijọsin, ti wọn si ṣekupa a.
Ọpọlọpọ eniyan lo ti pe fun iwadii finfini lori iṣẹlẹ naa, lẹyin to da awuyewuye silẹ lori ẹrọ ayelujara.
Awọn àkẹkọ̀ọ́ Uniben wọ́de ìfẹ̀hónú hàn nítórí akẹgbẹ́ wọ́n tí wọ́n fipa bálòpọ̀
Àwọn ọdọ́ tó wọ́de ìfẹ̀hónúhàn nítori ìwà ìfipá báni lòpọ̀ tí hù sí Uwa, tí wọ́n sì tún gba
ẹmi ọdọ́mọbinrin náà kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé ní ìpínlẹ̀ Edo.
Wọ́n ní ìwà yìí pẹ̀lú kò mọ́ àsọ tí ènìyàn wọ tàbí ọjọ orí oní tọ̀hún.
- Gómínà Kogi pàṣẹ kóníléógbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Kogi
- Ó ṣeéṣe kí ilé ìjọsìn, mọ́sálásí àti ọkọ òfurufú ṣí, Ẹ wo àwọn ìlànà tuntun tí ìjọba là sílẹ̀
- Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ṣòfò lásìkò ìfẹ̀họ́nú hàn nítorí ìṣèkúpani George Floyd
- Inú káàdì ìránti tí mo rí he ní mó tí rí fọ́tò ìhòhò Salawa, mó kàn fẹ́ gbà owó díẹ̀ ni- Afurasí
Ọ kan nínú àwọn olùfẹ̀hónú hàn náà ati ẹgbọ́n ọmọ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sẹlẹ̀ sí sàlàyé pé oríṣiríṣi irú ìṣẹ̀lẹ̀ yii ló ti n wáyé látẹyinwá to fi mọ ìyá àgbàlagbà tọ n lọ si ilé rẹ̀ jẹjẹ ti wọ́n sì fi ipá bálòpọ̀ láàrín ọ̀nà
Justice for Uwa: Pásítọ̀ Adeboye, Amnesty International fárígá lórí àwọn aṣebi tó pa omidan Omozuwa

Oríṣun àwòrán, PAstor adeboye/ facebook
Pasitọ agba fun ijọ Redeemed lagbaye, Enoch Adeboye ti ṣeleri ati rii daju pe awọn leṣebi-leṣeka ẹda to ṣekupa akẹkọọ ipele kinni ni fasiti Benin, Uwaila Omozuwa lẹyin ti wọn fipa baalopọ ko sa mọ ofin lọwọ.
Ninu ijọ RCCG miracle Mega Parish ni ilu Benin city lawọn eeyan kan ti lọ fi ipa ba omidan naa lo pọ ni Ọjọru to kọja ki wọn to la agolo panapana, fire extinguisher mọọ lori to si ku; lati igbayi wa si lawọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n ke ibosi lori rẹ.
- Coronavirus dé ọ̀dọ̀ ará ọ̀run, ọdún Egúngún kò ní wáyé nílùú Ibadan nítorí coronavirus
- Ẹ̀yin Pásítọ̀, ẹ múra fún ìkómọ yanturu lọ́dún tó ń bọ̀ - Adeboye
- Inú káàdì ìránti tí mo rí he ní mó tí rí fọ́tò ìhòhò Salawa, mó kàn fẹ́ gbà owó díẹ̀ ni- Afurasí
- Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹ gbọ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
Ninu atẹjade kan eyi to fi sita lọju opo Facebook rẹ, Pasitọ Adeboye ṣalaye pe oun yoo forikori pẹlawọn ajọ agbofinro gbogbo lati rii pe panpẹ ofin tete mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa ati pe o digba ti idajọ ododo ba waye lori ọrọ naa ki oun to si lẹyin rẹ.
Kí ni àjọ ajàfẹ́tọ́, Amnesty International, sọ?
Bakan naa ni iranṣẹ Ọlọrun naa tun ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi pẹlu adura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.
Bakan naa ni ajs ajafẹts lagbaye, Amnesty Internation pẹlu ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo twitter rẹ,Amnesty International ni ibanujẹ nla lo jẹ pe irufẹ iṣẹlẹ tun lee maa waye ni kopẹkopẹ si asiko ti ọwọ awọn ọlọpaa ṣẹ tẹ awọn ọkunrin mọkanla kan fun fifi ipa ba ọmọ ọdun mejila kan lajọṣepọ ni Limawa ni ilu Dutse ni ipinlẹ Jigawa.

Oríṣun àwòrán, Pastor e.a. adeboye/facebook
Ajọ naa ni bi iwa ifipabanilops ṣe n fojojumọ pọ si lorilẹede Naijiria ko ṣẹyin ijakulẹ awọn agbofinro atipe ọpọ awọn ti wọn hu iwa ifipanilopọ ni wọn maa n bọ ms ofin lọwọ lẹyin o rẹyin.
'Lootọ iwa ọdaran to gogo ni ifipabanilopọ lorilẹede Naijiria, ṣugbọn ọwọ ti ijọba fi n mu u ko wuni lori rara'
Justice for Uwa: "Fájìn ni àbúrò mi ti wọn fipá bálopọ̀ nínú sọ́ọ́sì, tí wọ́n sì tún fọ́ lórí"

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ni owurọ ọjọ Satide ni awuyewuye bẹrẹ lori ayelujara nitori iku to pa ọmọbìnrin, ẹni ọdun mejilelogun kan nipinlẹ Edo.
Iroyin sọ pe ọmọbìnrin náà, Uwaila Omozuwa, ni awọn kan fi ipa balopọ, ti wọn si tun fi agolo afẹ́fẹ́ ti wọn fi n pa ina, 'fire extinguisher' fọ ọ lori, ninu ile ijọsin Redeemed Christian Church of God kan to wa ni adugbo Ikpoba Hill nilu Benin.
Ọmọbinrin naa la gbọ pe ọdun yii ni wọn gba a wọle si Fasiti ilu Benin, lati kẹ́kọ̀ọ́ nipa imọ nípa kokoro aifojuri, Micro Biology.
Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karùn-ún, ọdun 2020 ni iṣẹlẹ naa waye, sugbọn ọmọbìnrin Uwa pada ku si ile iwosan to ti n gba itọju lẹyin ọjọ mẹta.
Ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin to ba BBC sọrọ, sọ pe lati bi ọdun meji lo ti maa n lọ ka iwe ninu sọọsi náà. Koda, ko to o di pe wọn gba a wọle si Fasiti ilu Benin.

Oríṣun àwòrán, Twitter
"Bi aago mọkanla si mejila lo maa n lọ, o si maa n pada sile bi aago marun irọlẹ.
Lọjọ ti wọn pa a, oun ati iya wa lo jọ jade nile, ki o to o ya si sọọsi.
Awọn ara sọọsi wa kan ni kọ́kọ́rọ́ maa n wa lọwọ wọn. Ọwọ wọn lo si ti maa n gba kọkọrọ lati si ilẹkun sọọsi, ti yoo si tun da pada to ba kàwé tán.
A n ti n reti rẹ ko pada sile lọjọ naa nitori pe o ti n to bi aago mẹfa irọlẹ. Ibi ti a ti gbiyanju lati pe fóònù rẹ ni awọn ara sọọsi ti pe wa lati wa a wo, nitori awọn o mọ nkan ti wọn ṣe fun.
Ẹ̀gbọ́n ọmọbinrin naa sọ pe, wọn ti gbe e lọ sileewosan ki awọn to de sọọsi.’'
"Wọn sọ fun wa pe ninu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni wọn ti ba aburo mi, ti wọn ti ya pátá rẹ, sikẹẹti rẹ naa wa ni kika soke, ẹwu rẹ si ti kun fun ẹ̀jẹ̀.
Ọkùnrin to máa ń sọ sọọsi wa ni alẹ si owurọ lo de si ibi'ṣẹ ni irọlẹ, to si lọ si ọdọ awọn to maa n tọju kọ́kọ́rọ́.
Wọn sọ fun pé Uwa ko ti i da pada, pe ko lọ wo boya o si n kawe lọwọ tabi o ti mu kọkọrọ lọ sile.
Igba ti ọkunrin naa wọle sinu sọọsi lo ba aburo mi ninu agbara ẹjẹ, ki wọn o to sare gbe lọ sileewosan aladani, sugbọn ileewosan ikọsẹ isegun Fasiti ilu Benin lo pada ku si.

Oríṣun àwòrán, Twitter
" Wúńdíá ni aburo mi lẹni ọdun mejilelogun, ko ni ibalopọ rí.
" Ibanujẹ ni nkan to ṣẹlẹ jẹ fun ẹbi wa, nkan ti a si fẹ ni pe ki awọn to ṣe nkan yii ko má lọ lai jiya."
Sugbọn, o fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe 'wọn ko bẹrẹ iwadii ni kiakia nitori pe wọn ni baba oun ko fun wọn ni owo lati wu wọn lori'.
Nigba ti BBC kan si alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo, o sọ pe ori ayelujara ni oun naa ti ka nipa iṣẹlẹ naa ni owurọ òní. Eyi lo si mu ki oun pe alamojuto ileesẹ ọlọpaa ni adugbo Ikpoba Hill ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Twitter
"Alaye to ṣe fun mi ni pe ija lo waye laarin ọmọbìnrin naa ati awọn kan ninu sọọsi. Ọmọbinrin naa farapa, ki wọn o to gbe lọ sileewosan, to ku si."
Alukoro ọlọpaa sọ pe oun ti pàṣẹ fún lati ṣe iwadii oun to ṣẹlẹ ni pato, ko si fun oun ni abọ.















