Coronavirus lockdown updates in Nigeria: Adeboye ni ọpọ nǹkan ńlá ńlá ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbélé Coronavirus

Oríṣun àwòrán, PAstor adeboye
Olusọ agutan agba fun ijọ Redeemed, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti sọ aṣọtẹlẹ pe ọpọlọpọ nnkan nla nla ni yoo maa ṣẹlẹ tori igbele Coronavirus.
Pasitọ Adeboye woye ọrọ yii lasiko iwaasu isin ọjọ isinmi, eyi to ṣe lori ayelujara.
Adeboye ni ọkan lara awọn nnkan nla nla ti yoo sẹlẹ tori igbele Covid-19 ni afikun yanturu ti yoo ba ọmọ bibi jakejado agbaye.
"Mo wa fẹ sin awọn pasitọ ni gbẹrẹ ipakọ pe, ẹ n sinmi bayii, amọ ẹ gbaradi fun eto isọmọ lorukọ lọpọlọpọ ni ibẹrẹ ọdun to n bọ, ẹ si maa ti ojule kan lọ si omiran ni nitori igbele Coronavirus."

Oríṣun àwòrán, Pastor Adeboye/twitter
Gbajugbaja pasitọ naa tun woye pe, iye awọn alarun Coronavirus ti ara wọn n da n ya ni lẹni pupọ, ti iye awọn eeyan ti arun naa n pa si kere si iye awọn ti ara wọn n ya.
Bakan naa lo tun woye pe iye awọn eeyan ti arun Coronavirus pa kere jọjọ si iye awọn eeyan ti ijamba ọkọ ati nkan miran n pa lọ.
Coronavirus Pandemic: Babàbá Adeboye ní coronavirus kò lè tán lórí ilẹ̀ ayé pátápátá

Oríṣun àwòrán, Facebook/Pastor E.A. Adeboye
Ṣẹ ẹ fẹ gbọ? Aarun coronavirus ko le tan lori ilẹ aye patapata.
Alakoṣo ijọ Redeem, alufa Enoch Adeboye lo sọ bẹẹ ninu iwaasu rẹ ninu isin ọjọ Aiku to pe akori rẹ ni ''ọna meje lati doju kọ oke.''
Pasitọ Adeboye ni gẹgẹ bi aarun Ebola, covid-19 naa ti di aarun ti yoo ba gbogbo aye gbe laelae.
- Àwọn tó wà nínú ìjàmbá ọkọ̀ órí afára Otedola ń lọ ìpínlẹ̀ míì láti Eko ni - LASTMA
- 'Ìbọn dún láàfin Ọ̀ọ̀ni ilé ifẹ̀ lóòtọ́, ṣùgbọ́n kò séwù'
- Àwọn ìbejì Akeugbagold kò le rìn dáadáa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáwọn padà
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó jogún eré ṣíṣe lọ́dọ̀ òbí wọn
- Wo báwọn mùsùlùmí ti ṣe ọdun ìtúnu ààwẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Afirika lásìkò covid-19 yìí
- Èsì àyẹ̀wò tí àjọ NCDC gbé síta fihàn pé ènìyàn 265 ló tún ti ní ààrùn Covid-19 ní Nàìjíríà
O ni iyanu nla ni yoo jẹ ti aarun naa ba kuro lori ilẹ aye patapata.
Ṣugbọn alufaa Adeboye awọn ti wọn ba ni ibẹru Ọlọrun ko ni ipin ninu aarun naa mọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Pastor Enoch Adeboye
Alufaa Adeboye ni o da oun loju pe ọpọ eeyan ni yoo kọ orin iyin si Ọlọrun lẹyin ti coronavirus ba di afisẹyin ti eegun fi aṣọ tan.
Amọ, o rọ awọn eeyan lati ni igbagbọ ninu Ọlọrun to da ọrun ati aye nitori Oun lo ti wa ṣaaju awọn oke gbogbo.

Kí ló pa bàbá Adeboye, bàbá Davido àti Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀ pọ̀ lásìkò ìgbélé l'Ọ́ṣun?
Gbajugbaja pasitọ to jẹ Alamojuto agba fun ijọ RCCG lagbaye, Pasitọ Enoch Adeboye, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi pẹlu gbajugbaja oniṣowo to tun jẹ baba akọrin takasufe ni, Davido, Ọmọwe Deji Adeleke, obinrin to lowo ju nilẹ Afirika Iyaafin Fọlọrunhọ Alakija wa ninu awọn eekan ilu ti ijọba ipinlẹ Ọṣun ṣẹṣẹ ko jọ lati wa ọna ti wọn yoo fi ṣetọ arẹmọlẹkun fawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lasiko igbele coronavirus yii.

Oríṣun àwòrán, PAstorEAAdeboye
Baba Adeboye ni Alaga igbimọ naa eleyi ti awọn gomina tẹlẹ ni ipinlẹ naa atawọn to di di ipo Oṣelu mu pẹlu awọn oludaleeṣẹsilẹ pẹlu wa.
Awọn yoku to jẹ ọmọ igbimọ naa niyi.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lori agbekalẹ igbimọ naa, gomina Gboyega Oyetọla ni ara igbesẹ lati rii pe ebi ko pa awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun lasiko ti ofin koniogbele yoo fi wa nikalẹ nipinlẹ ọhun ni wọn
Coronavirus in Osun: Ọọ̀ni ile Ifẹ̀ yóò gbé orò bí ìgbà ìwáṣẹ̀ láti lé 'ẹbọra Coronavirus,' 'kúró nílùú

Oríṣun àwòrán, Ooni Enitan Ogunwusi
Gbogbo agbaye ti n damu lori arun yii fun ọpọlọpọlọ oṣu bayii laisi ọna abayọ kan to dan mọran.
Arun Coronavirus ti sọ ara rẹ di ẹrujẹjẹ ni gbogbo ilẹkilẹ, ẹbọra ti n se gbogbo aye mọle porogodo.
Ṣe awọn agba si bọ wọn ni to ba runi loju, aa bi ilẹ leere.
Eyi lo difa fun Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti ke sawọn alalẹ ilẹ yii lati le arun Coronavirus to gbode kan bayii wọgbo.
Idi niyi ti kabiyesi Ọọni fi kede pe ki gbogbo awọn olugbe ilu ifẹ o wa ninu ile wọn nitori oro fẹ jade lati fọ ilu mọ lọwọ arun Corona.
Atẹjade kan ti Ọọni fi sita latọwọ Oloye Ọyalami Awoyọde ni ẹnikẹni ko gbọdọ yọju sita nitori bi ẹnikẹni foju ba oro yii, oro naa yoo gbe ni o.
Ọọni Ile Ifẹ ṣalaye ninu atẹjade naa pe, lara awọn ibi ti oro naa yoo gba kọja ni iwara ilode, oke atan, iloro, aganhun, arubidi, moremi, ondo road, olurin, omi okun, iyekere, oroto, itaagbon, oke ayetoro, oke soda, otutu,
ajamopo, ita sun, lokore, odoiwara, olumogbe, ijio, ojafe, edena, igbo agbo, obaloogun, onpetu, oduduwa college road, akiile, ilare, saabo, iremo, okerewe, obalejugbe, garage isale, mokuro road, ojaja, ogbingbin, okejan,
iredumi, lagere, fajuyi, gbodo, ita olopo, isale agbara, ogbon agbara, ogbon oya, akui, obalufon, itakogun, oriyangi, ehindi, omisore,olurin, pediro, okemorisa, atawon ibo mii

Coronavirus updates: Èyí ni bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe lo ìgbélé wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ ènìyàn ló ti ń sọ iriri wọn bí wọn ṣe ló ojo kini wọn nínú ilé leyin ti ijoba apapo kéde konileogbele ni ipinle Eko, Ògún àti Ábuja.
Èyí ni àkójọ ìrírí tí àwọn ènìyàn fi sowo sì ilé ose BBC News Yorùbá àwọn ọ̀nà tí wọn gba láti lọ ojo kini igbele wọn.
Leyin ojo kini nìkan àwọn kan ti bere si ni ké gbajare pé kí a bá àwọn bẹ aare Muhammadu Buhari kí ó tú àwọn sílè nítorí pé ilé tí sú àwọn, wọn ní gbogbo ojo ni àwọn fi sún àti pé ojú ni òun kò rán àwọn ìṣe mo.
Enikan nínú ìdáhùn re ó ní 'A tẹ fóònù titi fóònù kú, Data Paapaa tán sugbon awon PHCN gbìyànjú díè.
"Àwọn ọmọ rí iná wo Cartoon àti pé iṣọwọ jẹun mi, ó lágbára mo sún titi ojú fẹẹ fọ".
Nínú oro tìrẹ Alowonle Olajide ni, oro igbele yìí kò bá òun lára mú rárá, àti pé ó jọ bí ẹni pé ènìyàn wá nínú ewọn ni, ó wá rọ ijọba pé kí wọn dín ọjọ igbele yóò kú tí ó bá ṣeeṣe ọsẹ kan péré tí to kí olúkúlùkù sì padà sí ẹnu isẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ti Kabiru Tunde, igbele fun òun àti àwọn ọmọ oun ni ìṣòro nítorí pé òun dojú kọ wàhálà púpọ bii ariwo pipa lórí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó wà nílè.
Ní ìhà míràn igbe kò sì iná mọnamọna ni àwọn miran nke, tí wọn sì ni èyí mú kó nira púpọ fún àwọn láti gbé inú ilé fún ọjo mẹ́rìnlá.
Àwọn miran tilẹ ṣalaye pe ni àdúgbò wọn làwọn agbegbe kan n'ilu Èkó, òfin isèdè yìí kò múlẹ nitori pe olokada àti awọn onimaruwa lọ ń ṣiṣẹ oojọ wọn,
Ó ní n ṣe ní ìta dabi ọjọ lásán tí àwọn ènìyàn ń lọ tí wọn ń bọ̀.
Ọpọ lọ n ke si ijọba kí wọn ba awọn tó ń tà ọjà ṣọrọ kí wọn sì ni aṣẹ lori bí wọn ṣe ń gbowó lórí ọjà nitori pe nkan ti àwọn n ra ni eedegbeta Naijiria ti di egbeunnkannabo ládùúgbò báyìí.
Ẹwẹ, àwọn miran ni àwọn sí ń retí oúnjẹ tí ìjọba ń pín nítorí kò tií de àdúgbò wọn rárá.














