Coronavirus in Nigeria: Ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ fínfín àyíká nítorí Coronavirus
Lati asiko ti arun Coronavirus ti di gbajugbaja lorilẹede Naijiria ni ijọba ti n wa oniruuru ọna lati koju rẹ ati lati daabo bo awọn araalu kuro lọwọ rẹ.
Ni ipinlẹ Eko, ijsba ipinlẹ naa pẹlu n gbe igbesẹ lati rii pe àwọn eeyan ipinlẹ naa wa ninu alaafia laisi ewu.
Awọn oṣiṣẹ̀ eto ilera ni ijọba ibilẹ Ojodu bọ sigboro lati fin gbogbo ibi ti kokoro arun Coronavirus lee farasinko si.