Salawa Abeni:Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ ẹni tó fẹ́ ba Queen Waka lórúkọjẹ́ lọ́jọ́sí

Emmanuel

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Àkọlé àwòrán, Mó rí káàdì ìránti kan hé ní, mó kàn fẹ́ gbà owó díẹ̀ ni- Afurasí
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọlọpàá RRS sọ pé ọwọ́ tẹ ọmọkurin ẹni ọdun mọ́kàndinlógún náà tó tún jẹ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè National Diploma ní Yaba College of Technology tí ìpinlẹ̀ Eko ní Magboro ni Ipinlẹ Ogun

Afurasí náà Olufowoke Oladunjoye Emmanuel ni wọ́n lọ gbé nílé àwọn òbí rẹ lọ́jọ́bọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta ti wọ́n ti n ṣọ́ọ kiri.

Kọmisona ìpínlẹ̀ Eko, Hakeem Odumosu sàlàyé pé ni kété ti ọ̀rọ̀ náà ti jẹyọ nínú oṣù kẹrin tí wọ́n mú ẹ̀sùn wá pé ẹnìkan fẹ́ bá Salawa Abeni lórúkọ jẹ́ ní òun ti pàṣẹ fún ẹka RRS láti ṣe ìwádìí irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Afunrasí ọ̀un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọlọ́pàá sàlàyé pé lóòtọ́ òun lòun wà nídìí ìbanilórúkọ jẹ́ náà láti gba owó díẹ̀ ní.

Àkẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ẹ̀rọ ni YabaTech ọun ni òun ri fótò ìhònhò náà nínú káàdì ìránti kan ní ìlẹ̀ẹ́lẹ̀ nílé iwé òun ní ínu ọsù kọkanlá ọdun 2019 ní.

Ó fí kún pé lẹ́yìn ti òun fi fótò náà si orí fóònù òun tàn, òun wá wá nọ́nbà Waka Quenn lójú òpó instagram rẹ.

Lẹ́yìn náà lòun fí àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí gbajúgbajà olórin náà lẹ́yìn ti òun fi àwọn fótò díẹ̀ sọwọ́ síi. Èrò ọkàn mi ni láti gba owó díẹ̀ ki sì ba àwọn fótò náà jẹ́.

"Mo rò pé gbogbo ǹkan sì ńlọ bí mo ṣe rò ni àfi ti mó gbọ nínú ìròyìn lọ́ja keji pé ẹnikàn ń gbìyànjú láti bá òun lórúkọ jẹ́, ẹgbọ́ ìyá mi ni mo wà nígbà ti ìròyìn náà n lọ lorí Rẹdíò ti ìyá mi náà sì n ṣépè lé ẹni tó fẹ́ ba Salawa lórúkọ jẹ́ láì mọ̀ pé, ẹmi gàn ni mo wà nídìí ọ̀rọ̀ náà"

" Mo rọra yọ jáde, mo sì lọ ba káàdì ìpè mi àti káàdì ìràntí náà jẹ́ tí mò sì júù sọnu ti fóònù si inú omi kan ni Magboro, kò sì si ẹni to sọ ǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà tabi pé Alhaja Salawa lori ọ̀rọ̀ náà mọ"

Salawa Abeni

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ ẹni tó fẹ́ ba Queen Waka lórúkọjẹ́ lọ́jọ́sí

Ẹ̀wẹ̀ gbájúgbàja olórin náà Salawa Abeni ti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ní Nàìjíríà àti lókè òkun fún àdúrótì, bákan náà lo dúpe lọ́wọ́ àjọ ọlọ́pàá pàápàá jùlọ ẹka RRS fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe láti wá ọmọkunbrin náà jáde.

Salawa ní òun kọ ni ẹni àkkọ́kọ́ ti ọmọkùnrin yìí ṣe irú rẹ̀ fún, sùgbọ́n òun dúpẹ́ fún ìfẹ́ àti àdúrótì gbogbo ènìyàn

Àwòrán ìhòhò: Salawa Abeni ti sọ̀rọ̀, ẹgbọ́ ohun tó wí

Salawa Abeni: Mi ò leè gbà kẹ́nikẹ́ni bàmí lórúkọ jẹ́

Àkọlé fídíò, Salawa abeni

Gbajugbaja olorin waka, Salawa Abẹni ti sọ pe, oun ti fi ẹjọ abanilorukọjẹ to fẹ fi aworan ihoho oun lede lori itakun agbaye sun ijọba.

Salawa lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.

O ni oun ko mọ ẹni to ṣe iṣẹ ibi ọhun, ṣugbọn bi iku ile o pani, tode ko le pani.

Salawa sọ pe ọkunrin naa ba oun sọrọ lori ikanni WhatsApp, to si sọ pe ki oun fun un lowo, bi bẹ kọ, oun yoo fi aworan ihoho rẹ lede fun gbogbo aye lati ri.

Gbajugbaja olorin waka naa ṣalaye pe iṣelẹ naa ko tu irun kankan lara oun.

Lẹyin naa lo sọ pe oun ko lee gba ki ẹnikẹni ba orukọ oun jẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti n to orukọ ọhun jọ, idi re ti oun ṣe fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ṣaaju ni Salawa ti fi ọrọ kan lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti ṣafihan atẹranṣẹ ti ọkunrin naa, to pe orukọp ara rẹ ni Jason tẹ si.

Ọkunrin ọhun ṣo pe ki Salawa fun oun lowo, bi bẹ kọ, oun yoo fi aworan ihoho Salawa lede fun gbogbo agbaye lati ri.

Lẹyin eyi ni Salawa fun ra rẹ wa fi aworan ọhun lede.