Seyi Makinde: Ọdún 2023 ni màá jíyìn iṣẹ́ ìríjú mi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́

Àkọlé fídíò, May 29: Akala, Aleshinloye sọ̀rọ̀ lórí ọdún kan Seyi Makinde gẹ́gẹ́bíi gómìnà

Arise ni arika, arika si ni baba iregun, eyi lo mu ki gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi ṣe alaye aseyọri rẹ ni aarin ọdun kan.

Makinde, nigba to n kopa lori akanse eto to n sami ọdun kan ijọba rẹ lori aleefa, ni ijọba oun ti pari apapọ iṣẹ akanṣe ojilenigba o din ẹyọ kan tijọba ana fi silẹ ni ẹka eto ẹkọ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Bakan naa lo fikun pe, ijọba oun tun ti da ọwọ le akanṣe iṣẹ miran ni ẹka naa to to mejidinlaadọrin pẹlu afikun pe oun lo ajakalẹ arun Coronavirus lati ṣe agbega ẹka eto ilera nipinlẹ Oyo ni.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

"O ti pe ọdun kan ti mo gba akoso ipinlẹ Oyo, asiko ka sere yatọ, asiko ijiyin iṣẹ iriju ẹni si yatọ pẹlu, ọdun 2023 si ni maa jiyin iṣẹ iriju mi ni ẹkunrẹrẹ, sugbọn ko to di igba naa, o yẹ ka mọ ibi ti a ti n bọ, ka lee mọ baa ṣe ṣe aseyọri si."

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter

"Mo ti mu ileri mi ṣẹ lati pari gbogbo iṣẹ asepati ti ijọba to kọja lọ ti ṣe lati ọdun 2011, ti n ko si fi imọ tara ẹni nikan bẹrẹ iṣẹ tuntun miran, ninu ọdun yii nìkan, iṣẹ ojilenigba o din mẹrin la dawọ le."

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Makinde tun salaye pe, ayipada rere ti n ba owo ti ijọba Oyo n pa wọle labẹle, o si ti di irọrun lati gba iwe aṣẹ emi ni mo nilẹ bayii, toun si tun ṣe atunṣe awọn oju popo to ti bajẹ."

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina Makinde ni oun mọ riri atilẹyin ati igbẹkẹle awọn eeyan ipinlẹ Oyo ninu oun, oun si seleri lati ma ṣe ja wọn kulẹ.