Ẹ pèsè 'pad' ọ̀fẹ́ fáwọn obìnrin láti ṣe nǹkan oṣù dípò 'condom' ọ̀fẹ́ - Dókítà

Paadi nkan oṣu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ kan nipa isegun oyinbo, Dokita Olufisayo Ogunbayo ti sísọ loju rẹ pe, kii ṣe oju ara nikan ni awọn obinrin ti maa n ṣe nnkan oṣu, amọ awọn obìnrin miran n ṣe e lati imu abi idodo eyi ti ko wọpọ.

Dokita Ogunbayo kede bẹẹ lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba eyi to n sami ayajọ imọtoto nnkan oṣu lagbaaye.

Ogunbayo, ẹni to salaye pe lasiko ti obinrin ba n ṣe nnkan oṣu, o ṣee ṣe ko maa kanra, ki ẹjẹ maa ya ni ara rẹ, ki inu si maa run, wa rọ awọn ọkunrin to wa lẹgbẹ wọn lati ni ifarada pẹlu wọn.

Onisegun oyinbo naa tun rọ awọn obinrin lati ni imọtoto lasiko nnkan oṣu, ki wọn si yago fun titi ọwọ bọ oju ara wọn loore koore, ki arun ma baa wọ ibẹ.

Ogunbayo tun gba awọn obinrin nimọran lati maa paarọ iledi wọn ni igba meji ni ọjọ kan, to si tun rọ ijọba lati pese paadi ni ọfẹ fawọn obinrin.

"Ọranyan ni nnkan oṣu ṣíṣe fawọn obìnrin, o si yẹ ki ijọba ṣe ipese paadi ọfẹ fun wọn gẹgẹ bi wọn ṣe n pin rọba idaabobo ta mọ si condom fawọn ọkunrin.

"Gbogbo awọn obinrin to kopa lori eto naa si lo kin dokita Ogunbayo lẹyin pẹlu afikun pe ọpọ mẹkunnu ni ko ri owo ra paadi fun nnkan oṣu wọn, ti wọn si n lo awọn eroja ti ko ni imọtoto.