Coronavirus cure: Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣetán láti dán abẹ́rẹ́ covid-19 tí fásítì Oxford ṣe wò ní Kenya

Ileeṣẹ kan to n ṣe iwadii nipa eto ilera lorilẹede Kenya ti kede pe ohun yoo dan abẹrẹ aarun coronavirus ti fasiti Oxford nilẹ Gẹẹsi ṣe agbekalẹ rẹ wo niluu Kilifi.
Kemri-Wellcome trust sọ pe ohun yoo nilo irinwo oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn yoo fi ara jin fun ẹkọ kikọ, eyi wa lara ohun to pe ''Abẹrẹ kan fun gbogbo eeyan.''
Kaakiri gbogbo aye lawọn onimọ ijinlẹ ti n wa abẹrẹ to le wo aarun coronavirus.
- Ìdí rèé tí ilẹ̀ Afirika fi gbọdọ̀ kópa nínú dídán abẹ́rẹ́ coronavirus wò
- Mọ síi nípa ohun tó ṣẹlẹ ní àwọn ibi tí wọn ti ṣilẹkùn ilé ìwé padà lẹyìn Covid 19
- Àsìkò wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé padà? Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nìyìí.
- Coronavirus ti di ara wa, kò le è kúrò mọ láéláé - WHO
- Coronavirus kò lè tán lórí ilẹ̀ ayé pátápátá- Bàbá Adeboye
- Àwọn alárùn coronavirus ṣe ìwọ́de ní Gombe, wọ́n ní ìjọba n febi pa wọ́n
Ẹ gbẹ onimọ ijinlẹ oogun oyinbo kan wa ni fasiti Oxford nibi ti wọn ti n ṣagbeyẹwo abẹrẹ kan ti wọn n pe ni ''ChAdOx1 nCoV-19.''
Wọn ti dan abẹrẹ naa wo lara ẹgbẹrun un kan awọn olugbe ilẹ Gẹẹṣi ti wọn yọnda ara wọn fun idanwo abẹrẹ naa.
Nibayii, ileeṣẹ to n ṣewadi nipa eto ilera ni Kenya ti sọ pe awọn eeyan ti wọn fẹ dan abẹrẹ naa wo lara wọn gbọdọ ju ọmọ ọdun mejidinlogun lọ, wọn si gbọdọ jẹ oṣiṣẹ eleto ilera niluu Kilifi.
Ọpọ lo ti tako didan abẹrẹ coronavirus wo nilẹ Adulawọ, ṣugbọn awọn oniṣẹ iwadii naa ti sọ pe awọn yoo gba iyọnda ko to di pe awọn bẹrẹ iṣẹ.
Wọn o ṣe pataki ki orilẹede Kenya kopa ninu idanwo abẹrẹ naa ki wọn le mọ bo ya abẹrẹ naa yoo ṣiṣẹ nilẹ Afirika.












