Coronavirus cases: Àjọ WHO ní ọ̀rọ̀ àrùn coronavirus ti di èyí tí yóò máa bá ọmọnìyàn gbé láéláé

Aworan eeyan kan to n ṣe ayẹwo ẹjẹ

Oríṣun àwòrán, Who

Onikaluku orilẹ ede lo n sa kijo-kijo kiri lati wa iwosan fun ajakalẹ arun Coronavirus, eyi to n mu ẹmi ọpọ eeyan lọ.

Amọ ajọ eleto ilera ni agbaye, WHO ti wa sin gbogbo agbaye ni gbẹrẹ ipakọ pe, o see ṣe ki arun Covid-19 naa di baraku fun wa, ko ma si kuro laarin wa titi laelae.

Dokita Mike Ryan, tii se oludari iṣẹlẹ pajawiri labẹ ajọ WHO lo ṣe ikilọ naa pẹlu afikun pe, ki awọn eeyan dẹkun sisọ asọtẹlẹ nipa akoko ti ajakalẹ arun Coronavirus yoo kasẹ nilẹ.

O fikun pe, koda gan bi wọn ba ṣe awari abẹrẹ ajẹsara fun Covid-19, iṣẹ nla ni akoso arun naa yoo si tun jẹ.

O le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ti aisan Coronavirus yii si ti mu lọ jakejado agbaye.

Ajọ isọkan orilẹede agbaye, United Nations UN, tun ti sisọ loju rẹ pe, arun Coronavirus ọhun lo ti n mu irẹwẹsi ọkan ati arun ọpọlọ ba awọn eeyan lagbaye, paapaa ni awọn orilẹ ede ti wọn kii ti ja itọju arun ọpọlọ kunra, to si rọ awọn adari ijọba lati ri itọju arun ọpọlọ bii ojuṣe koowa wọn.

Ki ni ajọ WHO tun wi?

aworan gbongan ipade ajọ WHO

Oríṣun àwòrán, Who

"O ṣe pataki ka ṣe agbeyẹwo eleyi: Coronavirus yii tun le e di ara awọn ajakalẹ arun miran to wa nilẹ ni awujọ wa, ti ko si ni lọ mọ laelae." Dokita Ryan sọ bẹẹ nibi ipade awọn akọroyin to waye ni Geneva.

"Kokoro arun HIV ko tii kuro nilẹ - a tun ti n ba ajakalẹ arun Coronavirus yi."

Dokita Ryan ni oun ko gbagbọ pe "ẹnikẹni le e sọ asọtẹlẹ nipa akoko ti arun yii yoo poora."

Lọwọ-lọwọ bayii, o le ni ọgọrun-un abẹrẹ ajẹsara ti wọn n dabaa pe yoo wo arun naa san, eyi ti wọn n ṣe lọwọ - sugbọn Dokita Ryan tọka si pe, awọn arun miran bii Ẹyi, ni ko kuro ni ayika wa patapata lai naani pe, aimọye abẹrẹ ajẹsara lo wa fun iwosan rẹ.

Amọ Oludari agba fun ajọ eleto ilera ni agbaye WHO, Tedro Adhanom Ghebreyesus tẹnu mọ pe, o si ṣee ṣe lati mu adinku nla ba ọwọja arun naa, ti a ba ṣe aayan to yẹ.

"Ọwọ wa ni ọna abayọ wa, iṣẹ gbogbo wa si ni, gbogbo wa si la gbọdọ ko ipa tiwa si ọna lati dẹkun ajakalẹ arun naa." o ṣalaye.

Onimọ isegun nipa ajakalẹ arun labẹ ajọ WHO, Maria Van Kerkhove, naa sọ nibi ipade awọn akọroyin naa pe, "a nilo lati fi sọkan pe, yoo gba akoko diẹ ka to bọ lọwọ ajakalẹ arun Covid-19 ọhun."

Àkọlé fídíò, Bá wo ni coronavirus ṣe ń tàn kálẹ̀ ní àyíká wa?

Bi wọn ṣe sọ oju abẹ nikoo naa lo waye lasiko yii, ti ọpọ awọn orilẹ ede agbaye n dẹ okun lọrun ofin konile o gbele, tawọn asaaju orilẹ ede si n gbero lori akoko ati ọna ti wọn yoo gba ṣe agbende ọrọ aje orilẹ ede koowa wọn pada.

Dokita Tedros wa ṣe ikilọ pe, ko si idaniloju kankan to fi idi rẹ mulẹ pe, ọwọja arun Coronavirus yii ko tun ni gbalẹ ni ẹẹkan si bi awọn orilẹ ede ba dẹ okun ofin konile o gbele.

"Ọpọ orilẹede lo fẹ kuro ninu oniruuru ilana to gbe kalẹ lati mu adinku ba ọwọja itankalẹ arun naa," ọga agba fun ajọ WHO salaye "sugbọn aba ti wa ni pe, ifojusọna ati igbaradi irufẹ awọn orilẹ ede bẹẹ gbọdọ gbepọn pupọ."

Dokita Ryan fikun pe "Ero ajẹbiidan kan tilẹ n lọ pe, ofin konile o gbele n ṣiṣẹ daadaa, ati pe mimu ofin konile o gbele kuro yoo ṣiṣẹ pupọ gan ni. Amọ awọn ero mejeeji naa lo ni ewu ninu."