Coronavirus guidelines: Kí ló ń mú àwọn adarí obìnrin lágbáyé rọwọmú nípa kíkojú covid 19?

Ajakalẹ arun coronavirus lo ti gba ọpọlọpọ ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye lati oṣu kejila, ọdun 2019 to ti bẹrẹ ni Wuhan lorilẹ-ede China.
Lati New Zealand to fi de Germany,Taiwan titi de Norway lati ri awọn orile-ede tobinrin n dari wọn ti wọn si n ṣe aseyọri nipa kikoju arun Covid 19.
Koda, awọn oniroyin ko sinmi lati maa kan sara si wọn fawọn igbesẹ ti wọn gbe lati koju arun yi.
Laipẹ yi ni Forbes sapejuwe wọn gẹgẹ bi ''awokọse daadaa laarin awọn asiwaju''
Awọn onwoye ni lara awọn to kẹsẹ jari ninu kikoju arun yi, awọn olori obinrin lo pọ ninu wọn.
Ki wa ni nkan ti wọn se ti wọn fi pegede?
Gbigbe igbesẹ lasiko
Olootu ijọba Iceland, Katrin Jakobsdottir ti se ayẹwo to pọ jantirẹrẹ fawọn eeyan ilẹ rẹ.
Tohun ti pe iye eeyan orile-ede rẹ ko ju 360,000 lọ; Iceland ko jafara rara.
Wọn gbe awọn igbesẹ ni kiakia.

Apẹẹrẹ igbesẹ akin ti Iceland gbe
Wọn ko jẹ ki awọn eeyan wa ni ipejọpọ to pọ ju eeyan ogun lọ eleyi ti wọn se titi di ipari osu kini ki wọn to wa ri ẹni akọkọ to ko arun naa nilẹ wọn.
Titi di osu Kẹrin, ko ju eeyan mẹsan an to gba ti ọwọ arun yi ku nibẹ.
Kini Taiwan ti ṣe?
Ni Taiwan to se pe orile-ede China ka kun ara ilẹ wọn,
Aarẹ Tsai Ing-wen tara sasa se agbekalẹ ibudo kokoro aifojuri ti o si tun se awọn nkan miran lati dena itankalẹ arun yi.

Bẹẹ tun ni Taiwan mu alekun ba iye asọ idaabobo ara ẹni tawọn osisẹ ilera n wọ to fi mọ ibomu .
Ninu eeyan miliọnu mẹrinlelogun, eeyan mẹfa pere lo ti padanu ẹmi wọn lọwọ arun yi.
Kini o ṣẹlẹ ni New Zealand?
Ẹwẹ ni New Zealand, olootu ijọba Jacinda Ardern, gbe ọkan lara awọn igbesẹ to lagbara ju lọ lagbaye nipa arun Coronavirus to n damu aye yi.
Oun ko duro ki arun coronavirus tankalẹ rara, ọna to gba ni pe o kuku pa arun naa rẹ ni orile-ede rẹ.
Nigba ti eeyan mẹfa ku ni o fofin de lilọ bibọ gbogbo ni ilẹ naa-nigba ti yoo fi di ogunjọ osu Kẹrin, eeyan mejila nikan lo ku nibẹ.

Yatọ si pe awọn orile-ede wọnyi ni obinrin gẹgẹ bi adari wọn, awọn orile-ede wọnyi ni nkan miran to pa wọn pọ eleyi to mu ki wọn le koju isẹlẹ yi.
Awọn orile-ede ta n wi yi ni owo, wọn ni eto imayegbadun farailu to munadoko bẹẹ ni wọn tun gbe igba-oroke ti ọrọ ba kan ki a mu idagbasoke ba awujọ.
Ati pe wọn tun ni ẹka eto ilera to duro deedee lati koju isẹlẹ pajawiri.
'Njẹ ka ni pe awọn olori wọnyi lo mu aseyọri yi wa funra wọn ni tabi ka sọ pe awọn nkan to wa nilẹ yi lo sokunfa aseyọri yi?
Lilo orisi ọna lati koju arun yi naa ni ipa to ko
Bawọn olori ta n sọ yi ti se n se eto oselu wọn naa ni ipa to kọ gẹgẹ bi awọn onwoye ti se sọ.
Dokita Geeta Rao Gupta to jẹ oludari ajọ 3D Programme for Girl and Women sọ pe ''mi o ro pe o ni ọna tawọn obinrin fi n dari ilu to yatọ si tawọn ọkunrin. Sugbọn tawọn obinrin ba wa ni ipo olori, wọn maa n mu iyatọ ba isakoso''.
O sọ fun BBC pe o yatọ si iru ọna ti awọn olori bi Aarẹ Trump ti ilẹ Amẹerika tabi Jair Bolsonaro ti Brazil ti se n se ijọba to n jiyan pe ko si ohun to jọ Coronavirus nita.

Aarẹ Bolsonaro lọpọ igba ti sọ pe ọfinkin kekere ni arun Covid-19 ti ko si bikita fun ilana itakete si ara ẹni lawujọ ti a mọ si social distancing.
Rosie Campbell, oludari Global Institute for Women's Leadership to wa ni fasiti Kings College ni London sọ pe ''ko si ọkunrin tabi obinrin ti wọn bi isejọba mọ''
''Sugbọn bi awujọ ti se re wa, ohun to seese ni ki awọn obinrin to jẹ olori ni oju anu ju awọn ọkunrin lọ'; Ipenija to wa ninu ka maa se oselu ọkunrin lo lagbara"
Awọn ọkunrin adari oriẹ-ede n kọ?
Ninu awọn olori ọkunrin orile-ede bii Brazil, Israel ati Hungary, a ti ri pe wọn di ẹbi asise wọn ru ara ita ti wọn si ni awọn eeyan ilẹ miran lo ko arun naa wọ ilẹ wọn.
Ọjọgbọn Campbell sọ pe ''imotomoto pọ fun awọn olori bi Trump ati Bolsonaro.
Wọn ko bi iwa bẹẹ mọ wọn; amọ, awọn ni wọn yan lati maa hu iwa bẹẹ''
O ni awọn obinrin kii saba hu iwa bẹẹ. Sugbọn o ni awọn miran to jọ bẹẹ bi apẹrẹ Marine Le Pen ilẹ Faranse.
Ta ni Angela Merkel?
Angela Merkel ti ilẹ Germany ni ọpọ se apejuwe gẹgẹ bi akinikanju ilẹ Yuroopu ninu didoju ija kọ ajakalẹ arun yi.
Orile-ede ọtọọtọ gbe igbesẹ ọtọọtọ lati koju arun Covid-19 latara pe ọtọọtọ ni alumọni ti wọn ni ati pe nkan ko ri bakan naa lọdọ wọn.
Eleyi ko ni nkankan se pẹlu boya eeyan jẹ obinrin tabi ọkunrin.
Nitori naa, Ọjọgbọn Campbell sọ pe awọn olori to jẹ ọkunrin ti ko hu iwa bayii naa wa tawọn naa ko si ni eeyan pupọ to ti ku nipasẹ arun coronavirus yii lawọn orilẹ-ede wọn.
Bi aarẹ Moon Jae-in South Korea ti se seto ipenija yi mu ki ẹgbẹ rẹ gbegba oroke ninu idibo ile asofin to waye lọjọ kẹẹdogun, osu Kẹrin.
Bẹẹ naa ni olootu ijọba Greece Kyriakos Mitsotakis tawọn eeyan gbosuba kare fun bi o ti se seto ti awọn to ku ko fi ju mẹrinlelaadọfa lọ ninu awọn eeyan miliọnu mọkanla.
E jẹ ki a fi eleyi we Italy ti o ni eeyan miliọnu ọgọta ti eeyan ẹgbẹrun mejilelogun si ti ku nibẹ.
Greece gba imọran awọn onimọ ni ti o si fi ilana itakete-siara-ẹni lelẹ saaju ki wọn to ni ẹni akọkọ to dero ọrun nipasẹ arun naa.
Wo awọn orile-ede mi tobinrin n dari wọn kan naa ti wọn ko si jajabọ ninu ajakalẹ coronavirus yi.
Ni Bangladesh, olootu ijọba Sheikh Hasina n tiraka ni lati mu adinku ba iye eeyan to gba tọwọ arun yi ku nilẹ to ni ọkan lara awọn eeyan to pọju lọ lagbaye.
Ohun to jẹ ipenija ni pe ilẹ naa ko ni eronja ta fi n se ayẹwo arun naa tawọn osisẹ ilera Bangladesh si sọ pe awọn wa ninu ewu aini aso idaabo to peye.
Gbigbe igbesẹ to nira lati gbe
Lati le koju arun Covid 19, awọn olori yoo ni lati gbe igbesẹ to le bii ki wọn wọgile eto ọrọ aje ni ibẹrẹpẹpẹ ajakalẹ arun yi ki o to pẹka bi igi iroko.
Sugbọn sa iru igbesẹ bayi ni wahala ti o maa n mu wa paapa julọ lagbami oselu gẹgẹ bi ọjọgbọn Campbell ti se salaye.
Sibẹ, awọn olori obinrin mi gba oriyin lọdọ awọn eeyan nitori pe wọn ko pẹ ọrọ sọ nipa ipenija to de bawọn fara ilu
Angela Merkel ti Germany ko pẹ ọrọ sọ fara ilu pe ''ipenija nla ni arun naa jẹ''
Orile-ede rẹ se agbekalẹ aye ayẹwo ati iyasọ́tọ to tobi julọ ni gbogbo Yuroopu.
O le ni ẹgbẹrun mẹrin le ni eeyan to ti tọwọ arun naa ku ni Germany to ni eeyan miliọnu mẹtalelọgọrin.
Fun Norway Ati Denmark:
Awọn Olootu ijọba obinrin mejeeji ṣiṣẹ to ya wọn sọtọ kuro pelu awọn akẹgbẹ ọn ọkunrin
Wọn n pe ipade pajawiri pẹlu awọn akọroyin loorekoore
Wọn n dahun ohun to yẹ to dabo ẹru obi lori awọn ọmọde lasiko
Erna Solberg ati Mette Frederiksen tun n ṣepade pẹlu awọn ọmọde nigabgbogbo.
Adari New Zealand naa n fi awọn omode lọkan balẹ bo ti yẹ.













