School re-opening: Àwọn orílẹ-èdè tó ti ṣilẹkùn ilé ìwé padà

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Heiko Jung

Awọn ileewe jakejado agbaye ti bẹrẹ si ni ṣi ilẹkun wọn pada lẹyin ti awọn ijọba ti n dẹwọ isede to tẹle ajakalẹ arun Covid 19.

O ti kọja osu meji bayi tawọn akẹkọọ ni orile-edeto le ni aadọwa kio ti lọ sile iwe mọ.

Ajọ UNESCO ni awọn ọmọde ati ọdọ to le ni biliọnu kan ni wọn ko ti ribi lọ si ile ẹkọ lati igba ti ajakalẹ arun coronavirus ti di ẹru jẹjẹ ni gbogbo agbaye.

Awuyewuye loriṣiriṣi lo n waye lori ewu to wa nibi ki awọn akẹkọọ pada si ileewe lai se pe wọn ri abẹrẹ ajẹsara atabi oogun to le koju arun Covid-19.

Sugbọn sa, awọn ijọba kan ni igbagbọ pe bi wọn ba tẹle ilana itakete-sira-ẹni eyi le daabo bo awọn akẹkọọ lọwọ arun yi.

Laarin osu Karun un, nkan bi orile-ede ọgọrun un ni ko tii kede igba tawọn akẹkọọ yoo wọle pada.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede marundinlaadọrin ti kede pe awọn yoo si ileewe tabi si wọn laabọ, nigba ti awọn mejilelọgbọn si ni loju opo ayelujara lawọn akẹkọọ yoo ti pari saa eto ẹkọ to ku.

Amọ sa, fawọn akẹkọọ to to miliọnu mẹwaa din ni ọgọrun mẹsan an, eto ẹkọ ko ti i lojutu ba ti se n sọrọ yi.

Wo ninu awọn to ti si ileewe pada ati bi wọn se n daabo bo awọn akẹkọ:

China

China nibi ti arun yi ti jẹyọ ti da awọn akẹkọọ pada sile iwe lẹyin ti wọn jajabọ lọwọ arun naa.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ilana bi itakete-sira-ẹni, lilo ibomu, ọkọ ti wọn seto lọtọ ati oju ọna ti wọn la kalẹ si kilaasi kọọkan wa lara nkan ti China n se bayi tawọn akẹkọọ ti pada sile iwe.

Koda , awọn ile ẹkọ kan gbe ẹrọ ti yoo maa sọ bi ara awọn akẹkọọ ba ti se n gbona si kalẹ si ẹnu ọna abawọle ileewe wọn.

Taiwan

Gbogbo awọn ilana ti China fi lelẹ naa ni Taiwan mulo ti wọn si ti si ile ẹkọ wọn pada lati osu Keji nitori bi wọn ti se jajabọ lọwọ ajakalẹ Covid-19.

Eeyan irinwo le ni mọkandinlogoji lo farako arun naa ti eeyan mẹfa si baa lọ.

Akẹkọọ perete ni wọn n jẹ ki ọkọ ile iwe maa ko lẹẹkan naa.

Wọn ko jẹ ki awọn akẹkọọ to pọ jeun papaọ mọ

Denmark

Awọn naa dẹwọ ilana isede wọn ni aarin osu Kẹrin bi awọn ile ẹkọ ti se bẹrẹ isẹ pada tohun ti bi awọn obi kan se n bẹru pe ajakalẹ naa le tun jẹyọ lẹẹkeeji.

Idi ree tawọn miran ko fi ti i mu ọmọ wọn lọ si ile iwe.

Awọn akẹkọọ ni Denmark

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olukọ gbọdọ tẹle ilana itakete-sira-ẹni lasiko ti wọn ba n kọ awọn ọmọ.

Awọn olukọ kan n kọ awọn ọmọ ni ita kilaasi ti awọn miran si n kọ ọrọ si ilẹẹlẹ dipo oju patako.

Wakati meji meji ni wọn n jẹ ki awọn akẹkọọ lọ fọ ọwọ wọn nigba gbogbo.

Australia

Ni ipinlẹ to tobi ju ni Australia iyẹn South Wales, awọn akẹkọọ pada si ileewe bo tile jẹ pe ọjọ kan laarin ọsẹ ni wọn yoo fi kọ ẹkọ.

Lọjọ Kẹtadinlọgbọn osu yi ni Victoria ipinlẹ to tobi sikeji yoo bẹrẹ kilaasi tawọn akẹkọọ ati olukọ yoo jọ foju kan ara wọn.

Ileewe ni Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipinlẹ yi pẹlu Melbourne yoo kọkọ gba awọn ọsóọrọmọde lati wọle lẹyin naa lawọn to kere si wọn yoo bẹrẹ ẹkọ pada ni ọjọ kẹsan an, osu Kẹfa.

Akẹkọọ kọọkan mọ iye mita to maa wọn ti ko fi le sunmọ akẹkọọ miran

Germany

Ni ipelenipele ni Germany si awọn ile ẹkọ pada lẹyin ti wọn jajabọ lọwọ arun Covid-19.

Gẹgẹ bi China, Germany fi awọn ilana itakete-sira-ẹni lelẹ lawọn ile ẹkọ to bẹrẹ isẹ pada.

Awọn akẹkọọ n fọ ọwọ wọn loorekoore, wọn ko jẹ ki wọn sunmọ ara wọn rara.

Sweden

Ohun to jọ bi ọwọ yẹpẹrẹ ti Sweden fi mu ọrọ Covid-19 yi ya ọpọ eeyan lẹnu.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn kọ lati tẹle imọran ajọ isọkan agbaye pe ki wọn ti orile-ede wọn pa.

Awọn akẹkọọ wọn keekeeke si wa ni ile ẹkọ.

Ohun ti wọn sọ ni pe ẹri wa wi pe awọn ọmọde kii ko tabi tan arun naa kaakiri.

Norway

Lọjọ Kẹtadinlọgbọn, osu Kẹrin ni awọn ileewe alakọbẹrẹ si pada ni Norway ti awọn ileewe jẹle o sinmi si pada ni ogunjọ, osu Kẹrin.

Akẹkọọ mẹẹdogun pere lo le wa ni kilaasi.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn gba awọn eeyan niyanju lati maa fọwọ ati tabili ikọwe wọn loorekoore.

Ilé Gẹẹsi nkọ?

Eto wa nilẹ lori bi awọn ile ẹkọ ni ilẹ Gẹẹsi yoo se bẹrẹ si ni si pada losu to n bọ.

Sugbọn aroye pupọ wa lori boya wọn o yara da awọn ọmọ yi pada si ile ẹkọ ni tabi bẹẹkọ ati iru aabo ti yoo wa fun wọn nibẹ

Naijiria ati Ghana nkọ ?

Ni Naijiria titi pa ni gbogbo ile ẹkọ yoo wa titi di igba ti wọn yoo fi se agbeyẹwo ẹkunrẹrẹ.

Ohun ti igbimọ to n mojuto ọrọ ajakalẹ arun Covid-19 ni Naijiria sọ ni yi ni Ọjọbọ tii se ọjọ kọkanlelogun, osu Karun un.

Ni Ghana, Minisita feto iroyin, Kojo Oppong Nkrumah sọrọ lori koko yii lasiko tawọn alasẹ n salaye ọrọ nipa ọrọ yi wi pe ijọba ko ni erongba lati si ile ẹkọ pada lasiko yi.