Yollywood: Àwọn ayé ló tú èmi àti Iyabo Ojo ká, wọ́n rò pé à ń fẹ́ ara wa ni- Muka Ray

Muka Ray pẹlu awọn oṣere mii

Oríṣun àwòrán, Instagram/Muka Ray

Yoruba ni oju kii ri arẹwa ko ma kii, oju to ba sì rẹwa, o di dandan ko pawo wale.

Idi ree ti ọpọ awọn oṣere tiata lobinrin fi n lo ipara ibora ki wọn lee pupa ni awọ, ti oju wọn yoo si dun wo ninu ere.

Gbajumọ oṣere tiata kan Muka Ray Eyiwunmi lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto kan loju opo ikanni BBC Yoruba.

Muka, ti ọpọ eeyan tun n pe ni Apasẹ tiata, tun salaye siwaju pe, ọpọ awọn oṣere tiata to dudu bíi koro isin tẹlẹ ni wọn ti bora, ti wọn si pọn roboto, ki awọn oṣere lee maa pe wọn lati kopa ninu ere.

"Ọrọ naa wa lọwọ awọn alagbata sinima, awọn Olootu ere atawọn ololufẹ wa, nitori ọmọ pupa ni wọn n wá ninu fiimu ki wọn to wo o, a si maa n fi wọn ta ọja ni amọ awọn ọmọ dudu naa si wa ninu fiimu wa.

Ọpọ onitiata to dudu si lo di pupa, ki wọn le maa lo wọn ninu ere."

Nigba to n sọrọ lori ajọsepọ rẹ pẹlu gbajugbaja oṣere tiata lobinrin kan, Iyabo Ojo, ti ẹnu n kun awọn mejeeji pe ọrọ ifẹ ikọkọ wa laarin wọn; Muka Ray ni awọn mejeeji dijọ n ṣíṣẹ papọ ni amọ araye ro pe awọn n fẹ ara awọn ni.

Muka Ray ati Doris

Oríṣun àwòrán, Instagram/Muka Ray

" Iyabo Ojo ni iwa irẹlẹ pẹlu oju aanu, yatọ si pe mo jẹ ọga rẹ, ọrẹ mi ni ninu iṣẹ ta dijọ n ṣe. Awọn eeyan ro pe a n fẹ ara wa ni, idi ree taa fi sun sẹyin funra wa, awọn aye lo tu wa ka."

Lori ipo ti iṣẹ tiata wa:

Apasẹ ni gbogbo nkan ti bajẹ patapata nítorí ayelujara ti awọn eeyan ti n wo sinima bayii. Ko si owo ninu iṣẹ tiata mọ,

Koda, o tun nira lati ni orukọ pẹlu. Akoba ti n wọ iṣẹ tiata bayii, iṣẹ sinima n ku lọ, sinima ti wọn n wo lori ayelujara ko ni jẹ ki ọpọ jade lọ wo sinima."

Àkọlé fídíò, Njẹ ọ mọ̀ pé mímí afẹ́fẹ́ tí kò dára lè fa àìsàn?

Gbajugbaja oṣere tiata naa, tii ṣe ọmọ agba ọjẹ oṣere to ti di oloogbe, Ray Eyiwunmi, tun kede fun araye pe, inu ẹjẹ oun ati awọn ẹgbọn oun ni iṣẹ tiata wa, ogun nla tí baba awọn si fi silẹ fun awọn nìyẹn.

O ni oun ati awọn ẹgbọn oun ni awọn dijọ jogun iwe akọsilẹ ere ti baba awọn fi silẹ, owo nla ti awọn ere naa si nilo ni ko tii jẹ ki awọn gbe sinima rẹ jade.

Muka Ray wa rọ ijọba Naijiria lati maa seto iranwọ, nipa amulo awọn dukia ijọba pẹlu owoya, fun awọn oṣere tiata, eyi ti yoo mu ko rọrun fun wọn lati ṣe eré to ni èrè, ti yoo si pawo gidi wọle fun ijọba.

Bakan naa lo tun rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ tiata, lati maa pe awọn agba ọjẹ oṣere to ti darugbo si iṣẹ, eyi ti yoo mu ki ẹmi wọn gun, ti gbogbo aye yoo si tun mọ pe wọn wa laaye, ti wọn ko si ni jẹ ohun elo alopati.

Mo kábàámọ̀ pé n kò kàwé, kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà - Sanyeri

Ilumọọka osere tiata, Alhaji Mukaila Olaniyi Afonja, tí gbogbo eeyan mọ sì Sanyeri abi Ambali ti ṣalaye bo ṣe rin irin ajo aye rẹ, ko to di onitiata. Sanyeri, lasiko to n kopa lori eto BBC Yoruba ṣalaye pe, ọjọ pẹ ti oun ti n jẹ Sanyeri, lati igba ti oun ti bẹrẹ ere tiata laarin ọdun 1992 di 1993.

"Mo kere diẹ nigba ti mo bẹrẹ ere tiata, bii ẹni ọdun mejidinlogun si mọkandinlogun nigba ti mo wa nile iwe girama, awada ti mo n ṣe lo si mu ki awọn eeyan fi gba mi nimọran pe, ki n lọ ṣe iṣẹ tiata."

Sanyeri

Oríṣun àwòrán, Instagram/sanyeri2

"Asiko ijade ounjẹ nile iwe ni ọrẹ mi kan mu mi lọ sibi isẹ tiata lọdọ oga mi tó di oloogbe, mo bẹrẹ tiata ni pẹrẹu nigba ti mo jade ile ẹkọ girama lọdun 1992." Sanyeri tun salaye pe awọn obi òun ko nifẹ si ere ori itage, amọ oun ko sọ fun wọn pe oun ti n ṣe tiata. Ó ni wọn ri aṣọ oogun tawọn fi n ṣe ere lọwọ oun, wọn na oun pupọ, amọ oun ko jawọ lẹyin isẹ tiata.Nigba to n sọrọ lori ajọṣepọ rẹ pẹlu Kamilu Compo, o ni " Adekola Tijani, wa ba mi lati ṣe tiata, mo si mú lọ sọdọ ọga mi, taa si di ibeji ti ki i ya ara wọn lati igba naa, taa si pinnu láti wá sílu Eko papọ. Sanyeri ni ọdun mẹta ṣe, ki oun to kuro lọdọ ọga oun, tí oju oun si ri mabo nigba ti oun ati Kamilu de Eko, ọdọ ẹgbọn Kamilu Compo si ni awọn n gbe.

Olaniyi Afonja

Oríṣun àwòrán, Instagram/sanyeri12

"Ere apanilẹrin ni ode inawo ni emi ati Kamilu Compo maa n lọ ṣe nigba ta kọkọ de Eko, ta si n ri owo diẹ-diẹ, kii ṣe agbe taarata amọ a a fi awada tọrọ owo." O ni awon lọ si ode inawo lọjọ kan ni awọn ṣe alapade oloogbe Lekan Lekinson ati Remi Shittabe, ti wọn si gba awọn nimọran lati dara pọ mọ ẹgbẹ tiata kan, ti awọn si dara pọ mọ ẹgbẹ tiata Fadeyi Caucus, ibẹ si ni awọn ti rí oloogbe Alaran, tii ṣe ẹgbọn Kamilu Compo lati ilu Oyo, amọ o ni o kọ lati gba awọn sinu ẹgbẹ naa."" Nibẹ la ti rí Ajala Jalingo to wa ninu ẹgbẹ osere miran ni Mushin, to si ni oun setan lati gba wa sinu ẹgbẹ amọ o gba wa to oṣu meji ka to ri ẹgbẹrun kan Naira owó iforukọsilẹ ti wọn beere san, tawọn sì lo ọdún mẹta nibẹ, ki awọn to kuro kuro ni ọdun 1998.

Sanyeri tun sọ pe ọjọ ti inu oun julọ lagbaaye lọjọ ti oun gba fisa ilẹ Amẹrika.

O ni ṣaaju asiko naa, oun ko ti ni anfaani lati rinrin ajo kuro ni Naijiria lọ si orilẹede miiran lati Naijiria.

Sanyeri ni oun maa n kabamọ pe oun ko kawe nitori ti oun ba kawe, oun ko ba ti ju bayii lọ."Emi gan ko pe mọ pe Ọlọrun ma gbe mi de ipo ti mo wa lonii, o si ma n dun mi pe n ko le kopa ninu ere tiata oloyinbo nitori aikawe mi, ti ero aitẹgbẹ si maa n mu mi." "Idi ree ti n ko fi lọ gba ami ẹyẹ nitori oyinbo mi ko dan mọran lati sọrọ imọyi tabi ba awọn akọroyin sọrọ.Mo wa rọ awọn ololufẹ wa pe aikawe kii ṣe arun, ki wọn ye ma yẹyẹ wa tabi fa ila si asise wa ninu oyinbo." Nigba to n sọrọ lori afojusun rẹ lọjọ iwaju, Sanyeri ni o ti wu oun lati kawe si ki ede oyinbo oun lee dan mọran lati maa ṣe ere tiata ni ede miran yatọ si Yoruba.Lori ajọṣepọ rẹ pẹlu osere tiata miran Tayọ Amokade, taa mọ si Ijẹbu, Sanyeri ni "Amugbalẹgbẹẹ mi ni Ijẹbu, koda o gbe inu ile ọdọ mi ri. Oun ati Ẹgbọn rẹ lo ja, to fi wa gbe lọdọ mi." Sanyeri ni oju Ijẹbu ri diẹ ko to da duro amọ ọpẹ ni fun Ọlọrun pe oun naa ti jana bayii. O wa gba awọn onitiata akẹẹgbẹ rẹ nimọran lati tẹra mọ ohun tí wọn n ṣe, ti aye fi n nifẹ wọn.Sanyeri ẹni to kọ ila, eyi ti ko wọpọ lode oni sọ pe "N ko kabamọ pe mo kọla nitori ka ni n ko kọ ila ni, o seese ki n ma de ibi tí mo de loni." Sanyeri, ẹni to tun sọrọ nipa ajọṣepọ rẹ pẹlu baba ati iya rẹ ni, "Mo fẹran iya mi, awọn eeyan si iya oun ju iyawo ile oun lọ, oun ko si le ma darukọ rẹ ninu ere nitori o ṣe atilẹyin fun oun nidii isẹ tiata, kí oun to ní orukọ." Baba mi ko tiẹ gba rara ki n di onitiata. Koda, o mu mi lọ si idi isẹ Telọ nitori o gba pe n ko lee di eeyan gidi nidi isẹ tiata." Nigba to n sọrọ lori ipenija to koju lẹnu isẹ tiata, Sanyeri ni oun bu sẹkun nigba ti aburo oun sọrọ buruku si oun nigba ti oun ko ri ọwọ mọlẹbi da, ìyá awọn si lo pari ija naa lẹyin ọdun kan.Sanyeri ni ọjọ ti oun ko leè gbagbe laelae ni ọjọ ti oun gba iwe irinna lọ si ilẹ Amẹrika lẹyin osu mẹta ti oun se fiimu 'Ọ̀pá kan' to sọ oun di olokiki.

Olaniyi Afonja

Oríṣun àwòrán, Instagram/sanyeri12