Ondo judgment: Pásítọ̀ Kolawole ṣá Olaniyi pa lóko kọ̀ǹkọ̀, adájọ́ bá ní kí wọ́n yẹgi fún un

okun igbẹmi ẹni

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Akurẹ ti dajọ iku fun pasitọ kan ti orukẹ rẹ n jẹ Kọlawọle Samson fun jijẹ ẹsun ipaniyan.

Onidajọ Ademọla Bọla gbe idajọ rẹ kalẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun iranṣẹ Ọlọrun naa fun ṣiṣeku pa arakunrin kan ti oruks rẹ n jẹ Ayọ Ọlaniyi ni ileto kan to wa nitosi Okeigbo ni ipinlẹ Ondo.

Onidajọ Ademọla Bọla ni arakunrin naa ku ni ileewosan lẹyin ti o ṣa a lada ni ileto Gberinlegi.

ṣaaju ni amofin agba ipinlẹ Ondo ti agbẹjọro ijọba meji, Oluṣẹgun Akeredolu ati Arabinrin Ọmọtọla Ologun ṣoju fun ṣalaye fun ile ẹjọ pe ni sjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2016 ni pasits Kọlawọle ṣa oloogbe Ayọ Ọlaniyi lọgbẹ lori nigba to lọ ṣọdẹ kọnkọ pẹlu awsn ọrẹ rẹ mẹta miran ni odo ẹja kan ti wọn ni o jẹ ti ọdaran pasitọ naa.

Pasitọ Ẹọlawọle ṣalaye fun ile ẹjs pe oun ko jẹbi ẹsun naa ki ile ẹjs naa to ni gbogbo ẹri to wa niwaju ile ẹjọ naa lati bii ọdun mẹrin ti igbẹjs naa ti bẹrẹ lo fihan pe pasitọ Kọlawọle jẹbi ẹsun pipa Ọlaniyi.

Ile ẹjọ naa ti wa ni ki wsn ls yẹgi fun un.

Coronavirus in Ondo state: Gómìnà Akeredolu ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó de ìpéjọpọ̀ ìjọ́sìn ní ìpínlẹ̀ Ondo

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Rotimi Akeredolu

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti gbẹsẹ kuro lori ofin to de ipejọpọ ileejọsin gbogbo ni ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọru, ijọba ipinlẹ Ondo ni pẹlu aṣẹ tuntun yii, ọjọ Isinmi Aiku nikan laye ijọsin yọ fawọn kristẹni, ti aye ọjọ Jimọ si ṣi fun awọn Musulumi.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.