Kayode Fayemi: Kìí ṣe torí àti di ààrẹ ni mo ṣe sapá mi fún Àmọ̀tẹ́kùn ṣùgbọ́n tó bá yá, máa sọ̀rọ̀ lórí bóyá a ó jẹ ààrẹ tàbí rárá

Aarẹ Buhari pẹlu Gomina Kayọde Fayẹmi

Oríṣun àwòrán, Presidency nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayode ti sisọ loju rẹ pe ifilọlẹ ikọ alaabo Amotekun lo wa fun ipese eto aabo to jiire fun ilẹ Yoruba, tilẹ jẹ p o fẹ fa ikunsinu laarin awọn gomina ẹkun kaarọ o jiire.

Gomina Fayemi, ẹni to kede bẹẹ lasiko to n kopa lori eto BBC Yoruba kan, wa ṣẹ lori ahesọ ọrọ to n ja rainrain nilẹ pe oun fẹ du ipo aarẹ lodun 2023, ni oun ṣe n ṣe kokari eto Amotekun.

Nigba to n sọrọ lori arun Coronavirus to gbode, ati ipa ti ijọba rẹ n ko lati ṣẹgun arun naa, Fayemi ni ko si ẹni to le sọ pe oun ja ajasẹgun lori arun Coronavirus.

O ni ohun kan ṣoṣo to si le bori arun ọhun ni igbele ati pe, ko si bi arun naa ṣe le kasẹ nilẹ patapata, yoo si maa wa bii HIV ati ọfikin ni.

Nigba to n sọrọ lori atilẹyin ti wọn n ṣe fun awọn oloogun ibilẹ lori iwosan arun Covid-19, Fayemi ni o se ni laanu pe oogun oloyinbo la gbajumọ, ko si si ohun to buru nibẹ ti itọju arun naa ba ti ọdọ oogun ibilẹ wa.

O ni aimọkan lo n jẹ ki awọn eeyan kan maa ro pe arumọjẹ ni arun Coronavirus, ijafara si lewu fun agbalagba to ba ni arun miran lara tẹlẹ, to ba tun ni arun Coronavirus.

Fayemi, tii ṣe alaga ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Naijiria wa sisọ loju rẹ pe, ni ọpọ ipade ti awọn ti ṣe ni awọn ti fẹnu ko lori awọn igbesẹ kan, to fi mọ ofin pe irinke-rindo ko gbọdọ waye lati ipinlẹ kan si omiran.

"O ṣee ṣe ko jẹ pe ọna lati gbadura fun alaafia lori arun Coronavirus lo mu ki awọn gomina kan kede pe ki awọn musulumi lọ kirun ọdun itunu aawẹ, ti wọn si tun fun awọn Kristẹni laaye lati ṣe isin."

Lori ọjọ ọla Naijiria lẹyin arun Covid-19, Fayemi ni ọjọ ọla orilẹede yii yoo dara nitori ọgbọn tuntun ni arun naa fi n ko wa, to si yẹ ka gbajumọ amulo ayelujara bayii ju ti tẹlẹ lọ.

"Igba ipọnju la maa n ronu jinlẹ ju, ara ohun ti yoo si jẹyọ lara arun Covid-19 yoo mu idagbasoke ba wa, bi ilẹkun kan ko ba si ti, omiran kii si."

Àkọlé fídíò, Coronavirus: BBC News Yorùbá ní kí ẹ dúró nílé bí ẹ kò bá ní ìdí láti jáde

Nigba to n sọrọ lori eto iranwọ ti ijọba rẹ n ṣe, Fayemi ni oun maa n fun awọn arugbo ni ẹgbẹrun marun naira losoosu, ọdọ bii ẹgbẹrun marun si lawọn fun ni ẹgbẹrun lọna ogun ẹni kọọkan, ti oun si tun fun awon akẹkọọ nile ẹkọ giga ni ẹgbẹrun mẹwa owo iranwo eto ẹkọ.

Fayemi, lasiko to n sọrọ lori ajọṣepọ rẹ pẹlu gomina tẹlẹ ni Ekiti, Segun Oni, o ni ko si aawọ laarin oun ati Oni, ti ọpọ awọn to n tẹle gomina ana naa si wa ninu ijọba oun.