NECO: Ààrẹ Buhari ti fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún Ọ̀gá Àjọ NECO àti àwọn mẹ́rin míràn lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó báṣubàṣu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi ọwọ osi juwe ile fun adari ajọ eleto idanwo aṣekagba ti girama, NECO ati awọn mẹrin miran lori ẹsun pe wọn ṣe magomago.
Ninu atẹjade ti Aarẹ Buhari fi lede lo ti ni Ọjọgbọn Charles Uwakwe, Bamidele Olure, Shina Adetona, Tayo Odukoya ati Babatunde Aina ni wọn ti kọkọ fun ni iwe lo gbele rẹ fun igba diẹ ki wọn fi ṣe iwadii finifini ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan wọn.
Wọn ni Uwakwe jẹbi ẹsun lilo owo ajọ naa basubasu gẹgẹ bi ofin ajọ naa ti ọdun 2007 sẹ tako iwa ajẹbanu bẹẹ.
Aarẹ wa kesi i lati da gbogbo ẹru ijọba to wa ni ọwọ rẹ pada fun adele dari ajọ naa to wa nibẹ lọwọlọwọ.
Bakan naa ninu atẹjade ohun ni wọn ti sọ wi pe Arakunrin Bamidele Olure to jẹ adari ẹka isuna ni ajọ NECO lo jẹbi ẹsun ṣiṣẹ owo ajọ naa to wa ni ikawọ rẹ basubasu, ti ko si yẹ ni adari ẹka naa mọ.
Ọmọwe Dokita, Shina Adetona ni wọn fẹsun kan ni tirẹ pe o ṣẹ jibiti, to si ṣe magomago pẹlu akọsilẹ awọn oṣiṣẹ.
Tayo Odukoya ni wọn le nitori oun naa ṣẹ magomago to tako ofin ajọ naa, nigba ti wọn si le agbẹjọrọ Babatunde Aina nitori o yi akọsilẹ pade, ti o si ṣe magomago nipa tita ile igbe ajọ naa.
Bakan naa ni Minisita fun eto ẹkọ, Mallam Adamu Adamu wa paṣẹ fun awọn adari ajọ naa lati bẹrẹ igbesẹ lati gba gbogbo owo ti wọn fi ọna ẹru gba pada lọwọ wọn.
Ti a ko gbagbe, Ọjọ Kẹwa, Osu Karun un ọdun 2018 ni ijọba kọ iwe lo gbe ile rẹ fun igba diẹ si ọjọgbọn Uwakwe fun iwadii ẹsun jẹgudujẹra ti wọn fi kan an ati awọn meji miran.












