Foluke Daramola: Ayálégbé wa tó fi tipá já àbálé mi ṣe àkóbá fún ìgbé ayé mi

Oríṣun àwòrán, foluke daramola salako/instagram
Gbajugbaja oṣere tiata lobinrin, Foluke Daramola tun ti sọrọ lori bi ayalegbe baba rẹ ṣe fi tipa ja abale rẹ, nigba to wa ni ọdọ.
Foluke, lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba tun sisọ loju rẹ pe, iṣẹlẹ naa ṣe akoba fun igbe aye oun pupọ, ati igbeyawo akọkọ ti oun ṣe.
"Ọrẹ mi kan wa gba mi ni imọran lati lọ ri awọn onimọ nipa arun ọpọlọ.
Mo yari pe ori mi ko daru, n ko si lọ. Amọ nigba ti mo ri onimọ nipa arun ọpọlọ naa, o gba mi nimọran lati maa sọ iṣẹlẹ bi wọn ṣe fi tipa ba mi lo pọ sita, ki ọkan mi le fuyẹ."
O fikun pe onimọ nipa arun ọpọlọ naa tun salaye pe ọpọ eeyan yoo ri ẹkọ kọ ninu iṣẹlẹ naa, ti oun ba n sọrọ sita, eyi to ti to ọdun mẹwa bayii.
" Lati igba naa si ni mo ti n sọ ọrọ naa sita amọ mo ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin lọjọ kan, ti ọpọ eeyan si n pariwo le mi lori, ibẹ naa ni mo ri pe ọpọ eeyan lo ni iru isoro yii."
Foluke, ẹni to padanu baba rẹ nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹta tẹsiwaju pe, ifọrọwerọ naa lo mu ki awọn oyinbo pe oun fun ipade, ti wọn si gba oun nimọran lati da ajọ alaanu kan silẹ ti oun pe ni PARA, eyi to n ṣe iranwọ fun awọn eeyan ti wọn ba fi tipa ba lọpọ ati awọn ti ebi n pa.
Foluke to ni ọrọ akọmọna ti iya oun fi kọ oun ni ifẹ, otitọ inu ati itẹlọrun wa fikun pe, asiko ti oun ni ajọ alaanu naa ni ọpọ eeyan n tọrọ owo lọwọ oun, to fi mọ awọn oṣere tiata, idi si ree ti oun fi n ṣe aanu fun wọn.
"Gbogbo owo ti mo ni nipamọ ni mo fi ṣe PARA tan, amọ ọpọ eeyan lo mọ riri nkan ti mo n ṣe, ti ori mi si n wu nipa rẹ, asiko Covid-19 yii, mo si ri bii ojuṣe mi lati tọju awọn agbaagba ninu iṣẹ tiata."Nigba to n salaye lori idi to fi n gbe oju awọn agbalagba to n ṣe oore fun sita fun araye, Foluke ni ọpọlọpọ eeyan lo n fun oun lowo ti oun n pin, wọn si gbọdọ ri ohun ti oun fi owo wọn ṣe.
Foluke wa tun rawọ ẹbẹ fun eto iranwọ owo fun agba ọjẹ oṣere tiata kan, Oluwasesan Adio, ti gbogbo eeyan n pe ni baba Ojogẹ, to nilo owo lati sanwo ile to n gbe. Foluke, ẹni to salaye pe iya oun koro oju si iṣẹ tiata ni ibẹrẹ pẹpẹ, wa koro oju si awọn eeyan to n kọ iroyin kiri pe oun ku, to si n gbarata lori awọn eeyan to n gbe ẹjọ ẹlẹjọ kiri.
Gbogbo ẹni tó ba huwa ibajẹ nípa ẹnikan, ibajẹ lo maa ba nitori emi ko mọ ohun ti wọn fẹ gba ti mo ba ku.
Nigba to n sọrọ lori ibasepọ laarin ọkunrin si obinrin, Foluke ni awọn to ba n wa okiki kiakia, ti wọn si n wa oju rere ti ko tọ lo n mu ki wọn maa fi ilọkulọ lọ awọn obinrin lagbo tiata.
"Iwọ ti iṣẹ ọwọ rẹ ba da ọ loju, o ko ni maa yọju si ibi ti wọn ti n ya ere lai jẹ pe wọn pe ọ, eyi si lee mu ki wọn fi ilọkulọ lọ eeyan."
O ni isẹ to tii jọ oun loju ni sinima kan, A barber wisdom, ti oun ti gba miliọnu kan ati abọ naira, to si fun oun ni okiki, bẹẹ si ni oun ti ṣe ọpọ sinima miran to gbe oun saye.
O wa sisọ loju rẹ pe, o dara ki eeyan ni igboya funra rẹ, ko si nifẹ ara rẹ, bẹẹ ni ko si bi Ọlọrun ṣe lee ṣe iṣẹda eeyan, yoo ni ipa to lee ko ninu isẹ tiata.
O ni ọjọ iwaju to dara wa fun iṣẹ tiata, ti sinima Naijiria naa si ti n ba ti awujọ agbaye mu, nitori iyipada rere ti n ba awọn sinima ti wọn n gbe jade.
Foluke wa dupẹ lọwọ awọn ololufe rẹ fun atileyin wọn nigba gbogbo, bẹẹ lo tun ro wọn lati fi ọwọ wọnu lori ohunkohun ti oun ba ṣe, ti ko dun mọ wọn ninu.
Eruku ẹjọ́ tún sọ lórí ìgbéyàwó Toyin Abraham àti Adeniyi Johnson tó forí ṣánpọ́n
Ṣe ni oju opo Instagram n yọ eruku lala lori bi agba oṣere nni, Adeniyi Johnson tun ṣe bo aṣọ loju eegun nipa ohun to da igbeyawo rẹ ati gbajumọ oṣere miran, Toyin Abraham ru.
Bẹẹ ba gbagbe, Adeniyi Johnson ati Toyin Abraham dijọ ṣe igbeyawo amọ to fori sanpọn, ti Toyin si ti di aya Kolawole Ajewole, osere tiata miran, nigba ti Adeniyi fẹ Seyi Edun, ti oun naa jẹ osere tiata.
Nigba to n kopa lori eto kan loju opo Instagram pẹlu agba oṣere tiata miran Muka Ray Ejiwunmi, Adeniyi lo anfaani eto naa lati sẹ ahesọ ọrọ kan, ti wọn lo ṣe okunfa bi igbeyawo rẹ pẹlu Toyin Abraham ṣe daru.
Adeniyi ni "ọpọ eeyan lo ro pe igbeyawo mi pẹlu Toyin Abraham daru nitori pe mo n ṣe oju meji, ti wọn si ni mo n yan ale pẹlu Seyi Edun nigba naa, ẹni tii ṣe iyawo mi bayii."
"Amọ otitọ ibẹ ni pe lẹyin igba ti igbeyawo emi ati Toyin daru, Seyi Edun lo maa n sin mi lọ sile obinrin mii ti mo n fẹ lẹyin Toyin, ti Seyi gan ko si mọ pe oun ni yoo di iyawo mi lẹyin o rẹyin."

Oríṣun àwòrán, Adeniyi johnson
Ṣugbọn ọpọ awọn ololufẹ Toyin lori ayelujara ti ta gba Adeniyi lori ọrọ to sọ yii, ti wọn si n koro oju si bi Adeniyi ṣe tun bo oju egbo to n jina lọ.
Ọpọ wọn ni o san ki Adeniyi dẹkun sisọ ọrọ nipa igbeyawo rẹ ati Toyin mọ nitori baalu to ti fo, lo n juwọ si.
Wọn ni ọrọ igbeyawo laarin osere tiata mejeeji ọhun ti kuregbe-kuregbe, ti ọkọọkan wọn si ti ni ọkọ ati aya lọọdẹ.
Awọn ololufẹ Toyin Abraham wa n rọ Adeniyi Johnson pe ko fi Toyin lọrun silẹ nitori ohun to kọja, ti kọja lọ.












