Funke Adesiyan: Gbajúgbajà òṣèré Yollywood di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Adesiyan
Oṣere Yollywood, Funke Adesiyan ti di oluranlọwọ aya Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Aisha Buhari lori ọrọ abẹle ati awujọ.
Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu iyansipo rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn oluran lọwọ tuntun lofiisi aya aarẹ.
Lọsẹ to lọ ni Aisha pada silu Abuja lẹyin to ti wa nilẹ okere fun bi oṣu mẹta.
Ọjọ meji lẹyin tawọn kan n gbe iroyin ofege pe aarẹ Buhari fẹ ṣegbeyawo pẹlu obinrin mii ni Aisha pada si orilẹ-ede Naijiria.
- Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà
- Àgbo ló ṣiṣẹ́ fún mi l''asìkò tí mò ń wojú Olúwa fún ọmọ - Toyin Abraham
- Ẹ gbà mi o! Wọ́n tún ń lépaà mi o! - Kemi Afolabi
- Akẹ́kọ̀ọ́ Ilaro Poly tó pegedé jù jẹ ẹ̀bùn iṣẹ́ ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Abiodun
- Mama Rainbow pe 77 lónìí, àwọn òṣèré tíátà kọrin re kìí
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
Ta ni Funke Adesiyan?
Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta ni ọjọ ibi oṣere Funke Adesiyan, ọmọ ilu Ibadan nipinlẹ Oyo nii ṣe.
Funkẹ kọ ẹkọ nipa ere itage ni Fasiti Olabisi Onabanjo, bakan naa lo gboye Diploma ninu imọ ofin nile iwe yii kan naa.
Gbajugbaja oṣere Yoruba ni Funkẹ Adesiyan, o si wa lara awọn oṣere ti Eleduwa fun lẹbun ere ṣiṣe lagbo awọn oṣere.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Adesiyan
Ni kekere lọwọ rẹ ti ji sowo, koda ọmọ ọdun mọkandinlogun lo wa nigba to kọ ile akọkọ rẹ.
Iroyin kan tiẹ sọ pe ọmọ ọdun mẹtadinlogun lo wa nigba ti o ṣiṣẹ ni miliọnu kan naira lọwọ.
- Àgungùnlá! Bí Buhari wọ́gilé wíwọ bàálù olówó gọbọi fún òṣìṣẹ́ ìjọba kó ṣe aráàlú láǹfàní - SERAP
- Ọmọ Nàìjíríà, ẹ forijì mí! Aisha Buhari tọrọ ìdáríjì lórí fídìo tó jáde
- Seyi Makinde, bàtà tí Ajimobi bọ́ sílẹ̀ ni ko tẹsẹ̀ bọ̀ fún àṣeyọrí Ọyọ - APC
- Irú ọjà wo ni wọ́n kò ti lè yan Ìyálọ́jà?
- Aarẹ Buhari kẹ́dùn ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá tó jóná ni ọjà Onitsha
Ibẹrẹ aye Funke Adesiyan
Funke Adesiyan bẹrẹ pẹlu iṣẹ arinrin oge ni ọmọ ọdun mẹtala, o bẹrẹ si ni ṣe okowo fun ra rẹ, nigba to pe ọmọ ọdun mẹrinla.
O bẹrẹ si ni ṣe oṣelu lọmọdun mẹẹdọgbọn, nigba naa lo ṣe ipolongo fun oludije fun ipo aarẹ, Mallam Ibrahim Shekarau.
Idibo gboogbo ọdun 2011 lorilẹ-ede Naijiria ni Shekarau ti dije fun ipo aarẹ, bakan naa lo si ti jẹ gomina ipinlẹ Kano ri.
Bi Funke Adesiyan ti wọ agbo oṣelu ree
Lẹyin ti Funkẹ bẹrẹ oloṣelu, lo sọ erongba rẹ lati ṣoju Ẹkun Ila Oorun Guusu Ibadan nile igbimọ aṣofin Ipinlẹ Oyo ninu eto idibo ọdun 2015.
O jawe olubori ninu idibo abẹle ṣugbọn o fidi rẹmi ninu ibo gangan an ninu eyi to ti padanu ọpọ owo ati ohun ini rẹ.
Amọ, Funkẹ ya ọpọ eeyan lẹnu nigba ti o pe apejẹ lati dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ.
- Ààrẹ Buhari wọ́gilé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa wọ ọkọ̀ bàálù olówó gọbọi
- World Food Day: Wo àwọn oúnjẹ ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá tó ti ń di àpatì
- Akẹ́kọ̀ọ́ Ilaro Poly tó pegedé jù jẹ ẹ̀bùn iṣẹ́ ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Abiodun
- Njẹ́ o mọ pé N3000 ló o sàn láti gbà kaadi ìdánimọ̀ míì bí tí tẹ́lẹ̀ bá sọnù?
- 'Gomina Makinde, àgbọ́gbọn'tí ni kẹ́ẹ gbọ́ àwọn ará Oyo o lórí sáà kejì 'torí...'
Lori ohun to wa laarin rẹ ati Saheed Balogun
Funkẹ ni lootọ ni oṣere Saheed Balogun ti jẹ ololufẹ oun ri, o ni oun nifẹ Saheed nitori oun rii gẹgẹ bi oninukan eeyan nigba naa.
O fikun ọrọ rẹ pe akitiyan Saheed lati ran awọn to ba ni iṣoro kan tabi omiiran lọwọ wa lara awọn ohun to jẹ ki oun nifẹ rẹ.
Amọ, onikaluku lọ lọna tirẹ lẹyin ti oun ri ihuwasi to yatọ ninu ihuwasi Saheed.
- Aarẹ Buhari kẹ́dùn ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá tó jóná ni ọjà Onitsha
- Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Patrick Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí!
- Ìná ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ati ìjọba kò wọ̀ níbi ìpadé
- Ọmọ Nàìjíríà, ẹ forijìn mí! Aisha Buhari tọrọ ìdáríjì lórí fídìo tó jáde
- Ọkọ̀ agbépo tó gba iná ṣe àkóbá ní ọjà Onitsha
- Rọ́bà ìdáàbòbò gbówó lórí! ìjọba Tanzania ko 30 Mílíọ̀nù rẹ̀ wọ̀lú












