NLC Strike update: Ìná ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ati ìjọba kò wọ̀ níbi ìpadé

Oríṣun àwòrán, @others
Lẹyin ipade fun ọpọlọpọ wakati ni ọjọru, ni awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣì fariga pe ìná ko nii wọ lasiko yii.
Lati aago mẹrin irọle titi di oru ọjọbọ yii ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ati awọn minista fun ọrọ oṣiṣẹ fi jọ ṣe ipade papọ ni eyi to tun fori ṣọnpọn.
Ijiroro naa da le owo oṣu awọn oṣiṣẹ oni ipele mejila ni eyi ti wọn ko fẹnuko le lori.
Awọn oṣiṣẹ n beere fun ida mọkandinlọgbọn ninu ọgọrun un alekun owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ti owo oṣu wọn ti ji ẹgbérun lọna ọgbọn lọ tẹlẹ, iyẹn awọn to wa ni ipele kọkanla si ikẹtadinlogun lẹnu iṣẹ ọba.
Lẹyin opọlọpọ ijiroro nibi ipade naa ni minista fun ọrọ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Chris Ngige sọrọ ni aarọ yii pe awọn ti sun akoko ipade mii si aago meje alẹ oni, ọjọbọ.

Oríṣun àwòrán, @others
Ngige ni ipade naa yoo tẹsiwaju ki wọn le jọ fẹnuko lori iye owo naa laisi aṣiṣe kankan.
O ni wọn so ipade naa rọ ki awọn akọṣẹmọṣẹ lè wo awọn akọsile bi owo oṣu naa a ṣe ri daadaa.
Lati igba ti NLC ati TUC ti ni wọn maa gunle iyanṣẹlodi lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa ọdun yii ni ijọba ti n ṣe ipade pẹlu wọn.
Ayuba Wabba to jẹ aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni wọn sun ijiroro naa siwaju ki ọrọ awọn ikọ mejeeji le ye ara wọn sii.
O ni wọn n duro de awọn akọṣẹmọṣẹ to n ṣe akọsilẹ bo ṣe maa ri ki a to jọ woo kunakuna.
Wabba ṣalaye siwaju pe igbesẹ yii di dandan nitori pe oriṣiiriṣi ipele ọna sisan owo oṣu oṣiṣẹ ni Naijiria n lo ti afikun owo oṣu yii si gbọdọ kari.
Lati oṣu kẹrin ọdun 2019 ni Naijiria ti sọ ẹgbẹrun ọgbọn naira di owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ni Naijiria.
- Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Toyin Abraham tọ̀ lẹ́ẹ̀mẹwàá
- Ajọ Amnesty International ní kò dín ní 119 ọmọ Nàìjíríà ti wọ́n ti gba ìdájọ́ ikú ní Malaysia
- Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?
- A ti gbé kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ibodè Nàìjíríà kí ọrọ̀ ajé wa leè gbé pẹ́lí- ìjọba àpapọ̀













