NLC: Ìjọba àpapọ̀ ń tán wa ní sùúrù pẹ̀lú bó se dákẹ́ lórí owó osù tuntun

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA
Agbarijọpọ ẹgbẹ osisẹ NLC ti fi igbe ta pe ara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ko balẹ mọ, ti ijọba si n tan awọn ni suuru lori ọrọ sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bii owo osu to kere julọ lorilẹ ede Naijiria.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, akọwe apapọ fẹgbẹ NLC, Peter Ozon Eson ni, ọwọ yẹpẹrẹ tijọba apapọ fi mu ọrọ sisan owo osu to kere ju naa ko bawọn osisẹ lara mu.
O ni ayafi tijọba ba gbe igbesẹ to lowura ni kia-kia, nikan lẹgbẹ naa ko fi ni sepade lẹẹkan si, ti yoo si gbe igbesẹ to yẹ lati beere fun ẹtọ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ osisẹ NLC ni o yẹ ki aarẹ Muhammadu Buhari ti fi aba sisan owo osu to kere julọ naa ransẹ si ile asofin apapọ fun agbeyẹwo ati ibuwọlu to yẹ lati igba ti wọn ti gbe abọ igbimọ to n dunadura ka iwaju rẹ.
"Ti idaduro yii ba si tẹsiwaju, a o kede igbesẹ to kan tẹgbẹ NLC yoo gbe lẹyin ta ba sepade lati se agbeyẹwo ibi ti ọrọ naa de duro.









