New Era OPC: Ọshinbọtẹ kìí se ọmọ ẹgbẹ́ OPC, alárinà lásán ni

Oríṣun àwòrán, @OPC
Igun ẹgbẹ ajijagbara fun iran Yoruba, Oodua people‘s Congress (OPC) kan, New Era OPC, ti kede pe oun ko fara mọ Ọshinbọtẹ OOdua, tawọn eeyan kan kede gẹgẹ bii aarẹ apapọ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ yii, Alukoro fun igun New Era OPC, Sina Akinpẹlu salaye pe awọn kan hu gbọ pe wọn yan olori tuntun ni, awọn ko mọ rara nipa igbesẹ naa.
Gẹgẹ bi Akinpẹlu ti wi, Ọshinbọtẹ ti wọn yan naa kii se ọmọ ẹgbẹ ajijagbara OPC nitori ko ni kaadi idamọ ọmọ ẹgbẹ, bẹẹ naa ni kii se ojuse rẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ OPC.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
New Era OPC ni alarina lasan ni Ọshinbọtẹ ninu ẹgbẹ OPC, to si maa n sanna alaafia laarin ijọba ati ẹgbẹ OPC>
O fikun pe bonkẹlẹ tabi inu okunkun ti wọn yan Ọshinbọtẹ lai jẹ pe wọn ti sin oludasilẹ ẹgbẹ OPC to jẹ ipe Ọlọrun lọjọ Satide, Frederick Faseun, jẹ eyi to mu ifura lọwọ.
Akinpẹlu ni Adele asaaju ẹgbẹ lo si yẹ ki wọn yan to ba jẹ pe omi alaafiaigun OPC Faseun ko toro.
Ẹgbẹ OPC pin si mẹrin
O ni ẹgbẹ ajijagbara OPC ti pin si mẹrin, eyiun ni igun Faseun, igun Gani Adams, igun Reformed OPC ati igun New Era OPC.
Alukoro ẹgbẹ New Era OPC tẹ siwaju pe Ọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji, ti n gbe igbesẹ lasti ri daju pe ẹgbẹ OPC pada si ọkan soso lai pin si yẹlẹ-yẹlẹ mọ, eyi si ni awọn n se lọwọ.
O fikun pe igba ti allafia ba jọba pada ninu OPC lawọn yoo yan aarẹ apapọfun ẹgbẹ ajijagbara naa.

Oríṣun àwòrán, @Faseun
Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ ajijagbara fun iran Yoruba, Oodua people‘s Congress (OPC), ti kede lọjọ abamẹta pe, oun ti yan aarẹ apapọ miran lati rọpo oludasilẹ ẹgbẹ OPC to di oloogbe, Frederick Faseun.
Ọjọ ti Faseun papoda naa ni wọn si kede olori tuntun, eyi tii se Osinbọtẹ Oodua.













