Jonathan: Mó ń sàtilẹyìn fún Atiku kí ìsoro Nàíjíríà má baà fọ́n wa ká

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, @GEJonathan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ orilẹ ede Naijiria ana, Goodluck Jonathan ti salaye pe irọ nla ni pe ẹgbẹ oselu PDP ko se daadaa to fun ọdun mẹrindinlogun to fi tukọ orilẹede yii.

Ninu fidio kan ti BBC Pidgin gbe sita ni Jonathan ti kede ọrọ yii pẹlu afikun pe, to ba jẹ pe ẹgbẹ oselu PDP ko pegede lori aleefa ni, ebi ati iyan ni ko ba ti lu gbogbo ọmọ Naijiria pa tan.

Jonathan wa n beere pe, eelo ni wọn ta apo irẹsi kan nigba ti PDP gba akoso orilẹede yii ati iye ti wọn n ta bayii?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún: N kò bá tí ba ẹnu jẹ́ lọ́jọ́ ìgbeyàwó, àwàdà ni mo se

O tun fikun pe ẹgbẹ oselu PDP ti se iwọn to lee se fun ọdun mẹrindinlogun, ẹgbẹ oselu to wa lori aleefa lọwọlọwọ ni ko mura lati sa ipa tiẹ naa.

Jonathan, ẹni to sọ idi ti oun fi n se atilẹyin fun Atiku Abubakar lati di aarẹ orilẹede yii ni, isoro to n ba Naijiria finra, taa ba tete mojuto, o lee tu orilẹede yii ka, ti ọpọ eeyan yoo si fọn ka lọ sawọn orilẹede miran.

O ni oun nigbagbọ ninu Atiku pe, oun nikan lo lee mu ki irẹpọ ati isọkan pada si orilẹede Naijiria, ti yoo si mu ki gbogbo ẹya ati ede pada wa nisọkan.

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, @GEJonathan

Jonathan ni orilẹede yii ti yapa to bẹẹ gẹ, debi pe taa ba tete pana rẹ, ọpọ ẹmi ni yoo ba rin, to si seese ki ọpọ eeyan sa kuro nilẹ yii.

Nigba to n salaye lori ohun to faa, ti oun fi tẹ iwe kan sita, Jonathan ni ọpọ eeyan ni ko mọ ohun to n sẹlẹ́= nijọba, paapa awọn ọmọ, ti oun si fẹ ki ọpọ wọn mọ nipa isejọba ti oun se kọja,

O fi kun pe awọn ọdọ nilo iwe itan lati ka, ki wọn lee mọ awọn aseyọri ti oun se lori oye, ti wọn yoo si maa fi tọ awọn adari sọna lọjọ iwaju, paapa bo se kan eto idibo ọdun 2015.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post