Buhari: 'Ọ̀pọ̀ fẹ́ kí n kú nígbà tí mo ṣàìsàn

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ko si iku loju oun, koda oun maa to ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọdun mẹrindinlọgọrin oun laipẹ.
Aarẹ sọrọ yii ni ilu Krakow lorilẹede Poland nibi to ti fesi si ahẹsọ ọrọ kan pe ẹda oun lawọn eeyan n ri wi pe kii ṣe oun gan an.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Nibi to ti n ṣepade pẹlu awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn fi Poland ṣe ibugbe ni aarẹ ti sọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ Buhari ọpọ eeyan lero pe oun yoo papoda nigba ti oun ṣaisan, ṣugbọn ko si ohun to jọ beẹ rara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Aarẹ ni ara oun ti le koko bayii, ati pe ọrọ ailera oun ti di afi sẹyin ti eegun fi aṣọ.
Aarẹ Buhari tun fi da awọn ọmọ Naijiria nibi ipade naa loju pe ijọba oun si wa lori ipinnu rẹ lati pese eto aabo to mọnyan lori, ọrọ aje to dara ati lati gbogun tiwa ibajẹ ni Naijiria.